Fact Check Bandits forest Video: Fídíò ajínigbé nínú igbó,ohun táa mọ nípa rẹ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kii ṣe gbogbo ohun taa ba foju ri nii jẹ ootọ. Ni paapa lọrọ yi jẹ ootọ lode oni to ṣe pe awọn ayederu fidio tabi iroyin ẹlẹjẹ a maa gbalẹ kaakiri.
Eyi lo mu ki BBC maa fi aaye silẹ lati toju bọ awọn iṣẹlẹ eleyi to lamilaka lawujọ lati mọ boya lootọ ni wọn ṣẹlẹ tabi awọn kan da wọn bi ọgbọn ni.
Eleyi taa mu tọ yin wa lọtẹ yi ni ti fidio kan to gbode eyi to ṣafihan awọn janduku agbebọn kan ti baalu diroonu ya fidio wọn ninu igbo kijikiji kan
Kaakiri oju opo ayelujara lawọn eeyan ti n ṣalabapin fidio yi ti wọn si kọ akọle si lara pe awọn ajinigbe ni Naijiria ni wọn ya aworan wọn laimọ ni ibuba wọn.

Kini nkan ti aworan yi ṣafihan?
Ninu fọnran yi, a ri awọn eeyan bi marun un kan tawnkan da aṣọ pupa nbori ninu wọn ti wọn si gbe ibọn to jọ A-K47 lọwọ.
Bẹẹ la ri tawọn kan ninu wọn dori ka ina ibi ti wọn ti n dana.
- Eréepá, yẹ̀yẹ́ lásán lẹ̀ ń ṣe pẹ̀lú bí ẹ ṣe yọ mí nípò alága NURTW ní Eko - MC Oluomo
- Ènìyàn tí a ṣì ń wá nínú ìkọlù Rélùwè Abuja si Kaduna lé ní 168 - NRC
- Àwọn ológun ilẹ̀ òkèèrè ni máa fi kojú àwọn oníṣẹ́ ibi tó kọlu reluwé Abuja sí Kaduna - El-Rufai búra
- NIMC mú ìlérí ìjọba Nàìjíría ṣẹ, àwọn nọ́mbà fóònù tí kò so mọ́ NIN kò lè pè síta
Ninu fidio yi bakan naa a ri awọn nkan ọsin bi ẹran maalu ati aguntan nibẹ.
A ko ribi gbọ nkankan ninu fidio yi debi pe a o le sọ iru ede tawọn to wa ninu rẹ n sọ ṣugbọn o han kedere wi pe wọn rẹrin nigba ti wọn wo oke ti wn si ri diroonu to n ya aworan wọn.
Awọn wo gaan lo wa ninu fidio naa
Lara ohun ti iwadii wa ṣafihan ni iru aṣ tawọn to wa ninu fidio naa da bora ati orileede ibi ti wọn ti n da iru aṣọ yibora.
Gẹgẹ bi iwadii ṣe fihan, awọn ẹya to n gbe agbegbe Pokot, Samburu, Baringo ati Turkana ni iwọ oorun orileede Kenya lo maa n fi iru aṣọ yi bora.
Bakan naa la ri pe awọn to wa ni agbegbe yi a maa koju ikọlu loore koore.
Bi a ba fi aṣọ wọnyi we tawọn ajinigbe tabi janduku Naijiria,wọn ko papọ.
Idi ni pe lọp igba, awọn janduku ajinigbe Naijiria a maa wọ aṣọ to jọ tawọn ologun ti wọn a si maa da ibori dudu bo ori wọn.
Awọn to gbe ibọn dani ninu fidio yi kan ko wọ aṣọ rara ti wọn si tun de fila sori.
Ki lorisun fidio yi?
Ni ọjọ Kẹta oṣu Kẹrin ọdun 2022 ni wọn kọkọ gbe fidio yi soju opo Facebook.
Ileeṣẹ kan to n pese aabo ni Kenya taa mọ si Victory Security Africa Group lo gbe soju opo wọn pẹlu akọle''Awọn janduku ti diroonu ya aworan wọn ni Laikipia''
Laikipia jẹ agbegbe kan ni Kenya
Awọ ẹlomiran loju opo ayelujara ni Kenya ba bẹrẹ si ni pin fidio yi pẹlu akọle orisirisi
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Koda oloṣelu kan ni Naijiria torukọ rẹ n jẹ Jackson Ude ṣalabapin fidio yi loju opo Twitter to si kọ sibẹ pe awọn janduku Fulani ti wọn ya aworan wọn ni ibuba wọn lo wa ninu fidio naa.
Ko darukọ inu igbo ti wọn ti ya aworan yi amọ awọn eeyan wo fidio naa niwọn igba ẹgbẹrun mẹwaa.
O ti pada yọ fidio naa kuro to si tọrọ aforijin lori bi o ṣe alabapin iroyin ofege yi.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Oloṣelu miran ni Naijiria torukọ rẹ njẹ Joe Igbokwe fi fido yi sọwọ loju opo rẹ ni Facebook to si ni inu igbo kijikiji kan ni Naijiria ni wọn ti ya aworan naa.
O tun sọ pe awọn kunrin to wa ninu rẹ lawọn janduku ajinigbe to n ji awọn eeyan gbe.
O le ni igba ẹgbẹrun mẹta ti awọn eeyan ti wo fidio ti o ṣalabapin yi. Ọkẹ aimoye eeyan loti tun ṣalabapin fido naa.
Lọwọlọwọ Naijiria n koju ipenija aabo paapa ikọlu lọwọ awọn janduku ni apa ariwa ilẹ naa nibi ti ijinigbe ati ipaniyan ti peleke.
Laipẹ yi, Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El Rufai sọ pe awọn alaṣẹ Naijiria mọ ibi tawọn janduku yi wa ṣugbọn ileeṣẹ ologun k lati lọ doju ija kọ wọn.
O ni wọn n bẹru pe ki wọn ma pa awọn eeyan toii wa ni ibuba wọn ti wọn ji pamọ sibẹ.
Lọsẹ to kọja awọn agbebọn ajinigbe ṣe ikọlu si ọkọ oju irin reluwee ni Kaduna to ko ero to to ọọdunrun.
Wọn pa eeyan mẹjọ ti wọn si ji aimọye salọ ninu ọkọ reluwee to n ko ero lọ si Kaduna lati olu ilu Naijiria, Abuja.
















