MC Oluomo NURTW: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko yan MC Oluomo gẹ́gẹ́ bí alága ìgbìmọ̀ adarí ẹgbẹ́ awakọ̀ Èkó

Oríṣun àwòrán, Instagram/mcoluomo
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti yan ọgbẹni Musiliu Akinsanya, MC Oluomo gẹgẹ bi olori igbimọ ti yoo ma ṣakoso awọn garaji ọkọ ero nipinlẹ naa.
Iyansipo Oluomo waye leyin wakati diẹ ti awọn alasẹ ẹgbẹ́ awakọ ero ni Naijiria, NURTW, yọ MC Oluomo nipo alaga ẹgbẹ́ naa nipinlẹ Eko. Atẹjade ti kọmisana eto iroyin nipinlẹ Eko, Gbenga Omotoso fi sita sọ pe ìjọba da igbimọ olusako naa silẹ, lati le mu adehun ti ijọba ṣe pe oun ko nii jẹ ki wahala to n waye ninu ẹgbẹ́ NURTW da eto aabo ilu rú. Ọgbẹni Omotoso sọ pe nitori naa ni ijọba ṣe lo agbara ofin lati ri pe aye adari ẹgbẹ́ awakọ ko ṣófo, eyi to le da alaafia ipinlẹ Eko ru.
- Lẹ́yìn tí wọ́n gba ipò alága NURTW lọ́wọ́ rẹ̀, MC Oluomo yapá kúró ní NURTW
- Wo ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa MC Oluomo àti ìdí tí ọ̀pọ̀ ṣe gbàgbọ́ pé alágbára ni
- Baba tó dàbí MC Oluomo láyé yìí kò sí, ẹni tó bá níi, ó ní ohun gbogbo- Ọmọ MC Oluọmọ
- Ta ló leè rò pé ọmọ mẹ̀kúnnù bí èmi leè dé ipò alága NURTW? - MC Oluomo
O ni "ojúṣe ti á ni re e si awọn eniyan ipinlẹ Eko, ati awọn olugbe ipinlẹ yi". Oṣu to kọjá ni ìjọba ipinlẹ naa kede pe oun ti ofin de isẹ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ NURTW. Igbesẹ naa waye lẹyin ti awọn adari ẹgbẹ́ naa ni Naijiria da MC Oluomo duro nitori iwa afojudi ati awọn ẹ̀sùn miran. Ni kete ti wọn kede igbesẹ naa, ni awọn adari NURTW nipinlẹ Eko sọ pe awọn ko ṣe ẹgbẹ́ mọ. Yatọ si Ọgbẹni Akinsanya ti yoo jẹ adari ìgbìmọ̀ tuntun naa, kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko nigba kan ri, Hakeem Odumosu, ni yoo jẹ alarina laarin igbimọ naa ati ijọba.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police
Eréepá, yẹ̀yẹ́ lásán lẹ̀ ń ṣe pẹ̀lú bí ẹ ṣe yọ mí nípò alága NURTW ní Eko - MC Oluomo

Oríṣun àwòrán, InSTAGRAM/MCOLUOMO
Alhaji Musiliu Akinsanya ti ọpọ eniyan mọ si MC Oluomo ti sọ pe ere ọmọde ati yẹyẹ ni wọn n ṣe pẹlu bi wọn ṣe yọ oun ni ipo gẹgẹ bi Alaga Ajọ National Union of Road Transport Workers (NURTW) nipinlẹ Eko.
Ọjọru ni Ajọ NURTW lapapọ yọ igbimọ muṣẹya ti NURTW to wa nipinlẹ Eko, ti wọn si yọ MC Oluọmọ gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ naa.
Igbimọ naa ni awọn yọ Oluọmọ gẹgẹ bi iwe ofin ẹgbẹ ṣe fi lọlẹ.
- Wo ǹkan tí o kò mọ̀ nípa ESABOD tí òun àti Lizzy Anjorin jọ ń fi omi èpè wẹ ara wọn
- Ẹ̀ṣọ́ Ààrẹ Nàìjíría tẹ́lẹ̀ rí Goodluck Jonathan méjì pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀
- 'Olówó tabua ní Tinubu kó tó wọ òṣèlú, iṣẹ́ àánú ló ń ṣe kiri'
- Bí mó bá dì ààrẹ Nàìjíríà mo máa dá ipò Mínísítà fètò 'stomach infrastructure'' sílẹ̀-Fayose
- Owolabi Ajasa police in Yoruba film: Irungbọ̀n tí mi ò ní ló mú mi ṣe oríire kíkó'pa ọlọ́pàá
- Ẹ wo ohun tó mú ọkùnrin ẹni ọdún 67 fẹ́ kó sí ''lagoon'' l'Eko l'ọ́jọ́ ìbí rẹ̀
Amọ, ninu esi rẹ si igbesẹ yii ni MC Oluọmọ ti ni ere ọmọde ni ajọ NURTW ti ijọba n ṣe, nitori ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Eko ti yọ ara rẹ kuro ninu ẹgbẹ NURTW.
Bakan naa lo beere lọwọ aarẹ ẹgbẹ NURTW idi to fi tapa si ofin to de ẹgbẹ to si gbe igbesẹ ajọ naa kalẹ.

Oríṣun àwòrán, @MC Oluomo
O fikun pe igbesẹ naa ko mu ọpọlọ dani.
''Igbẹsẹ yii safihan ohun ti a n sọ nipa iṣekuṣe to n waye ninu ijọba aarẹ Buhari gẹgẹ bi a ṣe sọ lasiko ti a n ba awọn oniroyin sọrọ saaju iṣẹlẹ yii''
''Bi wọn ṣe tuwaka ko mu ọpọlọ dani, amọ a ko ni iṣoro kankan pẹlu ẹgbẹ ni apapọ amọ aarẹ ni a ni iṣoro pẹlu.''
''Bakan naa ni a o bẹrẹ si ni woye ẹni ti wọn yoo fi si ipo lati tukọ ẹgbẹ naa nipinlẹ Eko.''
''Ibeere mi ni pe ṣe ẹgbẹ NURTW ni apapọ ni agbara ju ijọba ipinlẹ Eko to fofin de ẹgbẹ NURTW nipinlẹ naa.''
MC Oluomo ni ko bojumu pẹlu bi wọn ṣe yọ awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW ti ijọba ipinlẹ Eko ti fofin de ni abẹle.

















