Ayo Fayose PDP Ticket: Kìí ṣe Atiku, Saraki nìkan ló lè díje dupò ààrẹ ní ẹgbẹ́ òṣèlú PDP

Gomina tẹlẹri nipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose ti bura pe oun ko ni kọ iwe fi ipo silẹ lori erongba rẹ lati dije dupo aarẹ ni ọdun 2023.
Fayose lasiko to n ba Ileeṣẹ iroyin Channels TV sọrọ ni iṣesi awọn ẹgbẹ oṣelu lori ki ẹgbẹ pa ẹnu pọ mu eniyan kan ti wọn n pe ni ''consensus'' ko ba oun lara mu.
O ni iṣesi yii yoo mu ki awon oludije bii ti oun ma ri aaye ti oun nilo lati dije dupo to wu wọn.
- Ọgá Báńkì tàá tú sílẹ̀, tórí ọjọ́ orí rẹ̀ àti ọlá Ramadan ni - Ajínigbé
- Wo ǹkan tí o kò mọ̀ nípa ESABOD tí òun àti Lizzy Anjorin jọ ń fi omi èpè wẹ ara wọn
- Ẹ̀ṣọ́ Ààrẹ Nàìjíría tẹ́lẹ̀ rí Goodluck Jonathan méjì pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀
- 'Olówó tabua ní Tinubu kó tó wọ òṣèlú, iṣẹ́ àánú ló ń ṣe kiri'
- Ẹ wo ohun tó mú ọkùnrin ẹni ọdún 67 fẹ́ kó sí ''lagoon'' l'Eko l'ọ́jọ́ ìbí rẹ̀
- BBC ṣé ìwádìí lórí fídíò ajínigbé nínú igbó tó gbòde, àbọ̀ wà rèé lórí rẹ̀
''Wọn ni wọn fẹ ki a wa gbimọ pọ yan eniyan kan, amọ mo ti gba fọọmu, mi o si ni tẹ fun ẹnikẹni''.
''Ko si ẹni to mọ ọkan awọn ọmọ Naijiria, ohun ti wọn fẹ? nitori naa ni mo ṣe ma a kopa ninu idibo naa, ti mi o si ni tẹ fun eniyan kankan.''
Saaju ni Fayose ti wọ ọgba ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ilu Abuja to si gba fọọmu idije fun ipo aarẹ pẹlu ogoji miliọnu naira.
Eleyii mu ki o jẹ ẹni akọkọ ti yoo gba fọọmu idije lati guusu Naijiria saaju idibo sipo ẹgbẹ ni abẹle.
Ṣe orukọ yii Oshoko naa ni ẹ o fi gori oye aarẹ?
Oshoko jẹ orukọ ti ko sẹni ti ko mọ ẹni to n jẹ ninu gbogbo eeyan to ba n gbọ nipa awọn oloṣelu Naijiria.
Fayose n sọrọ lori ifọrọwanilẹnuwo kan to ni pẹlu ileeṣẹ amohunmaworan Channels to si da atọkun eto lohun pe ki wọn kaakiri igboro awọn ipinlẹ Naijiria, wọn yoo gbọ orukọ wọn.
"Ẹ o ri pe mi o fi iwa mi bo, bi mo ṣe gba fọọmu ipo aarẹ tan lana ni mo ya sile iya Alamala ti mo lọ lo Amala fẹlẹfẹlẹ. Emi o ki n ṣe bi awọn oloṣelu to n dibọn lati gbe igbe aye nla lẹyin ti wọn ba kuro lori oye".
Fayose ni o yẹ ki awọn oloṣelu maa ṣe eto silẹ de igba ti wọn yoo ba kuro lori oye adari ti wọn ba wa.
Bí mó bá dì ààrẹ Nàìjíríà mo máa dá ipò Mínísítà fètò 'stomach infrastructure'' sílẹ̀-Fayose

Oríṣun àwòrán, Facebook/officialpdpnig
Gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan ri Ayodele Fayose ti gba fọọmu ikede erongba lati dije dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party,PDP.
Ni ilu Abuja lolu ileeṣẹ ẹgbẹ naa lo ti gba fọọmu yii ni Ọjọru.
Lẹyin to gba fọọmu naa tan, o ba awọn akọroyin sọrọ to si mẹnu ba awọn nkan ti yoo gbeṣe bo ba file ribi de ori alefa.
Ninu awọn nkan to sọ pato, Fayose ni oun yo ṣeto idasilẹ ileeṣẹ ti yoo maa mojuto awọn araalu torinaa oun yoo da ipo ''Minisita for stomach infrastructure'' silẹ.
''Ẹ ti mọ mi ṣaaju asiko yi ti ẹ si mọ pe kii ṣe akanṣe iṣẹ nikan lo ṣe pataki leto ijọba mi.A gbọdo ṣeto bi nkan yoo ṣe burẹkẹ fara ilu tori naa mo maa yan minisita feto ookun inu lafi gbe ti ita''
Nigba tawọn akọroyin beer lọwọ pe kini yoo ṣe ti yoo yatọ si nkan ti ijọba to wa lori alefa nṣe, Fayose ni wọn ko tiẹ ṣe nkankan.
Se ẹ ti ri orileede kankan lagbaye nibi ti awọn agbebọn ti n ṣe ikọlu si papakọ ofurufu tabi reluwee?

Oríṣun àwòrán, Facebook/officialpdpnig
''Yatọ si emi, eyikeyi oludije PDP, wọn ko ni jafara lati ṣe atunto orileede yi.''
Ni akotan Fayose ni oun yoo tẹle aṣẹ ẹgbẹ lori eto idibo abẹnu ati pe ohun to se pataki si oun ni ki ẹgbẹ PDP pada si ipo ni Naijiria.
- 'Olówó tabua ní Tinubu kó tó wọ òṣèlú, iṣẹ́ àánú ló ń ṣe kiri'
- Ẹ wo ohun tó mú ọkùnrin ẹni ọdún 67 fẹ́ kó sí ''lagoon'' l'Eko l'ọ́jọ́ ìbí rẹ̀
- Ádì̀yẹ̀ ń làágùn irun orí rẹ̀ ni kò jẹ́ ká mọ̀ ni ọ̀rọ̀ bí ìjọba ṣe ń kójú ìṣoro àbò ní Naijiria - Lai Muhammed
- Hafsat Abiola-Costello, o tàbùku àwa táa dìbò fún bàbá rẹ̀ pẹ̀lú bóo ṣé ṣàfiwé Yahaya Bello àti MKO
Lọwọlọwọ bayii, Fayose ni oludije ikẹrinla to fi aniyan silẹ lati wa tikẹẹti ẹgbẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP.
Ọkunrin mẹtala ati obinrin kan lo n wa tikẹẹti ẹgbẹ fun oludije ipo aarẹ Naijiria.
'Ayo Fayose tó gbangba sùn lọ́yẹ́ láti jẹ Ààrẹ orilẹede Naijiria'

Oríṣun àwòrán, Twitter
Agbẹnusọ fun Ayo Fayose to jẹ gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Lere Olayinka ti ni Ayo Fayose kun oju osuwọn lati jẹ aarẹ orilẹede Naijiria.
Lere Olayinka sọ eleyii lẹyin ti Ayo Fayose fi lede wipe oun ti setan lati dije dupo aarẹ labe ẹgbẹ oṣelu PDP lorilẹede Naijiria ti ọpọlọpọ ibeere si n jade lọtun losi.
O ni Fayose ni iriri to fi mọ ọgbọn, imọ ati oye bii Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, Yaradua ati awon agbaagba to ti se adari lorilẹede Naijiria.
- BBC ṣé ìwádìí lórí fídíò ajínigbé nínú igbó tó gbòde, àbọ̀ wà rèé lórí rẹ̀
- Wo iye ìgbà tí Olusegun Obasanjo ti fi òkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Ààrẹ Buhari àti ìjọba rẹ̀
- Òjò èpè! Tá ló dáa lẹ̀ láàrin Lizzy Anjorin àti Granma Florida, ESABOD tí àṣírí títú yìí ṣe ń gún wọn lára?
- NIMC mú ìlérí ìjọba Nàìjíría ṣẹ, àwọn nọ́mbà fóònù tí kò so mọ́ NIN kò lè pè síta
- Láyé! Ẹ ò lè rí mi mọ́ nínú fíìmù Yorùbá bí ìgbà ayé Saworoide - Araparegangan
''Niwọn igba ti ẹgbẹ oṣelu PDP ti sọ wipe ko si ẹni ti ko lee dije dupo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, nitori naa ko si iyọnu fun Fayose lati dije.''
''Bi o tilẹ jẹ pe Guusu lo yẹ ki aarẹ ti wa, amọ ẹgbẹ ti ni ẹnikẹni lati ibikibi lo leE dije dupo to fi mọ oke ọya ati isalẹ naa''
Agbẹnusọ fun Fayose naa ni o to gbangba sun loye lori eto oṣelu ati didari orilẹede Naijiria gẹgẹ bi aarẹ ni ọdun 2023.
Ayo Fayose to ti je gomina fun igba meji nipinlẹ Ekiti n jẹjọ ẹsun lilo owo ilu basubasu nigba to wa ni ipo.
Bakan naa ni iroyin fi lede pe ẹgbẹ oṣelu PDP ti yọ ọrọ igun kuro lori ẹni to le e dije dupo fun aarẹ lọdun 2023 ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.
Èmi "Osokomole" fúnra mi, mo ṣetán láti díje dupò Ààrẹ ní 2023 - Ayo Fayose
Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ ri, Ayodele Fayose ti kede pe oun naa yoo dije dupo fun aarẹ orilẹede Niajiria ninu idibo gbogboogbo ti yoo waye ni ọdun 2023.

Oríṣun àwòrán, LARU0004
Fayose fi ero re han ninu lẹta to fi ṣọwọ si ẹgbẹ oṣelu PDP lati fi ero rẹ han ni ilu Abuja.
Ninu lẹta naa ni Fayose ti kede pe oun ko ni kọpa ninu igbimo ti yoo yan ẹkun ti awọn oludije ti yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu naa ni idibo ọdun 2023.
- Wo iye ìgbà tí Olusegun Obasanjo ti fi òkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Ààrẹ Buhari àti ìjọba rẹ̀
- Ǹkan ọmọkùnrin rẹ ńgbálẹ̀ kiri, gbogbo ìlú ló wà fún; Gbas gbos tún bẹ̀rẹ̀ láàrin Tontoh dike àti olólùfẹ́ rẹ̀
- Ọ̀nà kan dí, ọ̀nà míì ṣí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀! Imáàmù táwọ́n aláṣẹ́ dá dúró ti ríṣẹ́ míì
- Ádì̀yẹ̀ ń làágùn irun orí rẹ̀ ni kò jẹ́ ká mọ̀ ni ọ̀rọ̀ bí ìjọba ṣe ń kójú ìṣoro àbò ní Naijiria - Lai Muhammed
- Ènìyàn tí a ṣì ń wá nínú ìkọlù Rélùwè Abuja si Kaduna lé ní 168 - NRC
- "Mo sá fún oògùn owó, igbó mímu, mo tún ní sùúrù fún ọdún 15 kí n tó di olókìkí"
O ni idi ti oun fi yọ ara oun kuro ninu igbimọ ọhun ni tori erongba oun lati dije dupo aarẹ lọdun to n bọ.
Gomina ipinlẹ Ekiti naa dupẹ lọwọ ẹgbẹ fun aduroti wọn to fi mọ iṣọkan ti wọn fi n tukọ ẹgbẹ naa.
Bakan naa lo ki wọn fun igbiyanju wọn lati yan awọn eniyan ni ẹkun ti wọn yoo ṣoju ẹgbẹ PDP.
''Gẹgẹ bi mo ṣe yan ni eti yin pe o ṣeeṣe ki n dije dupo aarẹ ni idibo abẹle to n bo ni ẹgbẹ PDP pẹlu igbagbọ pe ma a dije dupo aarẹ ni didbo gbogboogbo to n bo''
''Mo ti ṣetan bayii nitori naa mo fi ipo mi silẹ gẹgẹ bi ọkan lara igbimọ ti yoo yan ẹkun ti awn oludije ti yoo ṣoju ẹgbẹ naa yoo ti wa''
''Nitori ko bojumu ki n dije dupo ki n tun wa ninu igbimọ ti yoo yan ẹkun ti oludije yoo ti wa''
''Nitori naa mo na ọwọ arakunrin Gbenga Faseluka soke gẹgẹ bi ẹni ti yoo rọpo mi ninu igbimọ naa.''
Laipẹ yii ni alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Iyorchia Ayu ṣe igbekalẹ igbimọ ẹlẹni mẹtadinlogoji ti yoo sayẹwo ẹkun ti awọn oludije ninu ẹgbẹ naa yoo ti wa.
Ayo Fayoṣe ti jẹ gomina ipinlẹ Ekiti fun igba meji amọ to si n jẹjọ ẹsun ibajẹ lọwọ lori ẹsun pe o ṣe owo ilu basubasu nigba ti o wa nipo.



















