Ondo School bus fire: Pẹ̀lú ìbínú, àwọn ọmọ fẹ́ dáná sún dẹ́rẹ́bà ọkọ náà, ọ̀rọ̀ rèé lẹ́nu ará àdúgbò náà

Àkọlé fídíò, Bí wọ́n ṣe ń gbé àwọn akẹgbẹ́ mi tó jóná nínú ọkọ̀ jáde, ṣe lara wọn ń bó, wọ́n ń tẹ́ wọn s'atẹ́gùn - Akẹkọ̀ọ́ Akungba

Ọkan lara awọn ara adugbo awọn ọmọ ile ẹkọ kan ni Akungba, ipinlẹ Ondo nibi ti bọọsi to ko awọn kan ti gbina sọ gbogbo ohun to ṣlẹ gẹlẹ bo ṣe ṣoju rẹ lọjọ naa fun BBC Yoruba.

"Ye ye ye, ikunlẹ abiyamọ̀ o" ni ariwo ti Eunice Onigiobi ni oun gbọ lati inu ile ti oun fi sa sita.

O ṣalaye pe kii tilẹ ṣe pe ọkọ naa ni ijamba amọ o kan ṣaa duro soju kan ni lo si dede gbina.

"Awọn mii wa nita ti wọn duro sayika ti wọn ro aṣọ inura mọ idi tori wọn fẹ lọ wẹ lasiko naa ni ti ọpọ eeyan n mura ibi iṣẹ".

Eunice tun sọ pe gbogbo ara awọn to wa ninu ọkọ yẹn lo jo, pẹlu bo dẹ ṣe jo naa ni ara wọn tun n bo.

Nibi ti isẹlẹ naa ti waye pẹlu iroyin ti a gbọ, bi eeyan ba si jẹ ori ahun, yoo sunkun nipa ọsẹ ti ijamba naa se.

Bakan naa, Ọgbẹni John Oluwasegun to jẹ Pasitọ ijọ kan ni agbegbe naa ba BBC sọrọ pe nigba ti arakunrin naa ra ọkọ yẹn, oun baa sọrọ to si sọ fun oun pe ara ẹya ara ọkọ naa bajẹ amọ lati igba naa awọn ko sọrọ kankan nipa rẹ.

Ki ni Ọlọpaa Ondo sọ?

"Kete ti Ọlọpaa gbọ nipa rẹ a kọkọ sare lati doola awọn to wa ninu ọkọ naa jade".

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Arabinrin Funmilayo Odunlami sọ pe ko pẹ naa lawọn ko wọn lọ si ile iwosan.

Bakan naa lo sọ fun wa pe awọn ti ọrọ kan lori ọrọ yii ti wa ni ahamọ awọn fun iwadii.