Tinubu visits Kaduna: Ìkọlù sí gbogbo wa ni ìkọlù Kaduna yìì; máà fún àwọn tó farapa ní N50M

Tinubu

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Aṣiwaju Tinubu

"Ẹni to ba ni Asiwaju n lọ si ilẹ Hausa lemọ lemọ lati le fa oju wọn mọra pẹlu owo tori idibo ọdun 2023, ko wii 're rara".

Agbẹnusọ fun Oloye Tinubu, Ọgbẹni Tunde Rahman ni kii ṣe akọkọ Asiwaju lati ṣe iru nkan bayii.

"Igba ti awọn agbebọn kọ lu wọn ni Zamfara, Katsina ati Niger, ẹ o rii pe wọn lọ sibẹ lati bẹ wọn wo ti wọn si ṣeranwọ owo fun wọn".

Bakan naa, o ni ni ipinlẹ Eko nigba ti wọn gbe igbimọ kan kalẹ fun iranwọ fun awọn eeyan, Asiwaju n dide sii.

Àkọlé fídíò, Olaiya Igwe ló wá ra epo níbi tí mo ti ń di "nussle" epo mú mo bá bẹ́ mọ́ ọ́, bí ayé mi ṣe yí padà di òṣèré fíìmù rèé

O mẹnu ba awọn to farapa nibi ikọlu Lekki toll gate nigba ifẹhonuhan EndSARS pe torii rẹ naa ni ijọba ipinlẹ Eko ṣe gbe igbesẹ lori rẹ kanmọ kanmọ ti wọn si n ṣeranwọ fawọn eeyan.

O ni Asiwaju sọ nigba to lọ si Kaduna wipe ti nkan ba kọlu ẹnikan, gbogbo eeyan lo kọlu.

Tunde tun mẹnu ba eto iranwọ kan ti Tinubu tun l ṣe ni ile ẹkọ giga kan ni Eko, LASU nibi ti wọn ti n kọ awọn ni eto adari.

Ibo ni Asiwaju Tinubu ti n ri owo to n na?

Awọn eeyan mii n sọ pe owo ori awọn ara ilu Eko ni Tinubu fi n ṣe ara rindin to si n fọn kiri gbogbo ibi to ti lọ n ṣe iranwọ kiri.

Ẹwẹ, agbẹnusọ rẹ jẹ ko di mimọ nipa mimu itan Tinubu wa fun awọn eeyan pe ko to tilẹ wọ inu oṣelu rara ni Asiwaju ti jẹ bọrọkini ọlọrọ.

"Asiwaju kii ṣe akuṣẹ eniyan, bo tilẹ jẹ pe awọn alatako yoo sọ nkan to ba wu wọn, ohun ti mo mọ ni pe ko to de inu oṣelu ni owo ati ọrọ rẹ ti n ṣan bii omi".

Àkọlé fídíò, Seye Malaolu: Bí mo ṣe rí àgbára ẹ̀jẹ̀ tó kúnlẹ̀, mò ń bèrè pé ṣé wọ́n pa Turkey níbí ni,

Ìkọlù sí gbogbo wa ni ìkọlù Kaduna yìì; máà fún àwọn tó farapa ní N50M - Tinubu

Eekan ẹgbẹ oṣelu All progressives Congress to tun jẹ ọkan lara awọn to fẹ gbe apoti ibo aarẹ lọdun 2023, Asiwaju Bola Tinubu ti lọ ṣe ibẹwo si ilu Kaduna lori ikọlu si ọkọ Reluwe to ṣẹlẹ laipẹ.

Bakan naa ni Tinubu kede pe oun yoo ṣe agbekalẹ Aadọta Miliọnu Naira fun awọ n to fara gba ninu ikọlu naa.

Ọgbẹni Tinubu kọwọ rin pẹlu Gomina ipinlẹ borno tẹlẹ, Sẹnetọ Kashim Shettima to jẹ pe ile rẹ ni gomina Nasir El-Rufai ti wa gbalejo Tinubu.

Awọn mii to kọwọ rin pẹlu Asiwaju lọ si ilu Kaduna ni adari ile igbimọ aṣoju-ṣofin tẹlẹ, Yakubu Dogara ati Sẹnetọ Abu Ibrahim.

Iṣẹlẹ yii fọwọ kan gbogbo araalu lọkan

Tinubu ati El-Rufai

Oríṣun àwòrán, Jubril Gawat

Ọgbẹni Bola Tinubu ṣapejuwe ikọlu Reluwee na gẹgẹ bii eyi to de ba gbogbogbo ni Naijria.

Gẹgẹ bo ṣe sọ ọ, gbogbo eeyan lo yẹ ko ni imọlara ikọlu to waye ni Kaduna yii to ti mu ẹmi ọpọ eniyan lọ ati dukia lọ.

O tun mẹnu ba a pe "wọn ko ni faaye gba ipaniyan latọwọ awọn agbebọn mọ".

Tinubu wa rọ gomina El-Rufai pe ko ma jẹ ki iṣẹlẹ aburu ba daadaa rẹ jẹ ninu didari ipinlẹ rẹ.

Bakan naa lo rọ awọn ọmọ Naijiria lati ṣatilẹyin fun ijọba ipinlẹ Kaduna ninu yiyanju ipenija ti awọn agbebọn n da silẹ kaakiri.

Ni idahun, Gomina El-Rufai dupẹ lọwọ Tinubu pe o wa fara jọ awọn ara ipinlẹ Kaduna lori ikọlu ọhun eyi to mu ki ayẹyẹ ọjọ ibi aadọrin ọdun oloye Tinubu lati bu ọla fun awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ.

El-Rufai tun sọ fun un pe oun ti gbọ nipa erongba Tinubu lati du ipo Aarẹ, o ni "agbede meji ọna ni Naijiria wa bayii ti wọn si gbudọ ṣe ipinu to le lati yan awọn adari to yẹ".

Àkọlé fídíò, Seye Malaolu: Bí mo ṣe rí àgbára ẹ̀jẹ̀ tó kúnlẹ̀, mò ń bèrè pé ṣé wọ́n pa Turkey níbí ni,