Tinubu Presidential ambition: Bode George fọ́nu, ó sọ ìdí tí kò fi gba ti Tinubu gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Nàìjíríà

2023 Presidency: Bode George kìí ṣe ọmọ Yorùbá- Yoruba Welfare Group

Eekan ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, Oloye Bode George tí tutọ soke ó sì fojú gba a pé kii ṣe lójú òun nínú orileede Naijiria ni Bola Ahmed Tinubu yóò ti ṣe aleefa ipò Ààrẹ Naijiria.

O fi gbogbo ẹnu sọọ pé ṣe ni oun yoo kúrò lorileede Naijiria bí Tinubu to jẹ eekan àti oloye ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress bá di Ààrẹ orileede yìí.

Bode George ń sọ èyí níbi ìpàdé oniroyin kan n'ilu Eko.

"Inu mi dùn pé Ààrẹ tí buwolu ìwé abadofin eto idibo.

Àkọlé fídíò, Oluwo‘s Wedding: Àwọn èèyàn ìlú Iwo ní àwọn ń fojú sọ́nà láti tẹ́wọ́gba aya tuntun

O ni "gbogbo ọna ti i bàa wù kí Tinubu gba de Aṣọ Rock gẹgẹ bi Ààrẹ, mi o ni wa lara orileede yìí. Mo lè lọ sí Ghana kí n sì maa fi ojú ọọkan wo bo ṣe ń lọ ni Naijiria". Ó ni ẹ o ri nkan ti yoo sẹlẹ.

"Tinubu ni Ọga nla ni ilu Eko báyìí. Yóò tun wá ọna ẹburu mìíràn láti fi kò owó yín. Ìyàwó rẹ yóò wà di Ààrẹ ile Asofin àgbà. Ọmọ rẹ ọkùnrin yóò di gomina ipinle Eko.

Ọmọ rẹ obìnrin yóò jẹ Iyaloja gbogbo ìlú Èkó.

Bode George ni "ki ni Tinubu ti ṣe to fi yẹ kí ẹnikẹ́ni ní Naijiria yẹ ẹ sì?.

Oloye Bola Ahmed Tinubu to jẹ gomina ipinle Eko tẹ́lẹ̀ lo ti kede erongba rẹ láti du ipò Ààrẹ Naijiria lọdun 2023.