Oluwo‘s Wedding: Àwọn èèyàn ìlú Iwo ní kò sí ìṣòro pé ọba àwọn fẹ́ ẹ̀yà Hausa ní aya, àwọn gan gbọ́ èdè náà
Lonii ọjọ Satide ọjọ Kọkandinlogun osu Kẹta ọdun 2022, ni obinrin kan to jẹ alejo tuntun yoo wọ Ilu Iwo wa lati ilu Kano, to wa ni apa ariwa Naijiria.
Orukọ obinrin naa ni Firdauz Abdullahi, tii se ọmọọba lati ile Emir ana nilu Kano, Ado Bayero.
Ohun ti alejo obinrin naa si n bọ wa se nilu Iwo ni lati di aya oriade ilu naa, tii se Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, Telu Kinni.
Iyawo tuntun yii kọ ni akọfẹ fun Oluwo nitori o ti ni iyawo kan saaju akoko yii, ti wọn jọ wọ aafin lọdun meje sẹyin to gori itẹ.
- Taa ni Firdauz Abdullahi, ọmọbabìnrin Kano tí yóò di olorì tuntun fún Oluwo?
- Ọ̀rọ̀ èmi àti Olorì Chanel Chin kò yé ara wa mọ́ nínú ilé- Oluwo
- Oluwo àti Olorì àná, Chanel Chin tahùn síra
- Oluwo fẹ fi oye Waziri lọle nilẹ Yoruba
- N kò fẹ́ eégún onídọ̀tí ní ààfin mi - Oluwo
- Kíni kí a pé Oba tí kìí se ojúlówó ọmọ Oodua tórí pé ó kọ̀ láti se ètò tó yẹ kó tó jọba tó tún wá ń bú ìran bàbá rẹ̀?
- Ẹ dẹ́kun bíba ìjọba lórúkọ jẹ́ - Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun fèsì sí lẹ́tà Oluwo
- Ìgbà mẹ́rin tí ọ̀rọ̀ Oluwo dá awuyewuye sílẹ̀
- Ifọrọwerọ Oluwo lori awuyewuye pẹlu awọn Ọba
- Ẹ wo àwọn obìnrin tí kìí ṣe ọmọ Yorùbá tó jẹ́ ayaba ní ààfin ilẹ̀ Káàárọ̀ oòjíire
Orukọ obinrin naa ni Chanel Chin, ọmọ bibi orilẹede Jamaica nii se amọ oun ati Oluwo ti pinya bayii.
BBC Yoruba lọ silu Iwo lati mọ bi igbaradi se n lọ si laarin ilu naa nibayii ti ọjọ igbeyawo wọle de.
Bawo ni Ilu Iwo se n rọkẹkẹ si lati gbalejo Olori tuntun:
Ọpọ awọn araalu ati oloye lo fi idunnu wọn han pe ayaba tuntun yoo wọ aafin:
Wọn ni inu awọn dun, ti awọn si ti n foju sọna lati gba alejo olori tuntun naa nitori ọba to dara ni Oluwo, ọkọ rẹ jẹ si awọn.
Nigba ti wọn n sọrọ lori pe obinirn naa kii se ẹya Yoruba, ọpọ awọn eeyan to ba BBc Yoruba sọrọ ni eyi ko ni nnkan kan se pẹlu ajọsepọ awọn si ayaba tuntun naa.
Wọn ni lootọ ni Firdauz jẹ ẹya Hausa amọ ikannaa ni gbogbo wa ni Naijiria, ko si iyatọ.
Koda, Oloye to ba wa sọrọ ni ẹya Hausa gan ni iyawo kekere to wa ninu ile oun, ajọsepọ awọn si dan mọran.
Ta ni Oluwo tilu Iwo:
Ọkan ninu awọn ọba alaye to gbajumọ nilẹ Yoruba ni Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, Telu Kinni.
Oun ni Oluwo Kẹrindinlogun ti yoo jẹ nilu Iwo, osu Kọkanla ọdun 2015 si lo gori itẹ awọn baba nla rẹ.
Orilẹede Canada ni Oluwo ti wa sile wa jẹ ọba, to si maa n fi ojoojumọ wa lawọn oju ewe iwe iroyin tabi lori iroyin ayelujara nitori awọn igbesẹ rẹ.
O ti kọkọ fẹ iyawo akọkọ nigba to gori oye amọ awọn mejeeji ti pinya bayii.
BBC Yoruba wa n gbadura pe ọba oke yoo fi adun si igbeyawo tọkọ taya naa, iyawo yoo si bi isu ati iwalẹ.





