Lai Muhammed: Ìjọba ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti borí ìgbésùnmọ̀mí ní Naijiria

Lai Muhammed ati Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ijọba orilẹede Naijiria ti tako ọro ti aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri, Oluṣẹgun Ọbasanjọ sọ lori eto aabo to dẹnukọlẹ.

Obasanjo ni eku ko ke bi eku mọ, bẹẹ si ni ẹyẹ ko ke bi ẹyẹ mọ ni Naijiria nitori ọrọ eto aabo to dẹnukọlẹ.

Lai Mohammed

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Bakan naa ni o ni ko si ibi kankan to rọrun lati fori famọ si mọ ni Naijiria nitori gbogbo ibi ni ewu wa lai yọ agbegbe kan kan silẹ ni Naijiria.

Amọ, Minisita fun eto iroyin, Lai Mohammed lasiko to n fesi si ọrọ ti Obasanjo sọ ni kokoko ni ara ọta nle ni ọrọ awọn ikọ ologun ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, Seye Malaolu: Bí mo ṣe rí àgbára ẹ̀jẹ̀ tó kúnlẹ̀, mò ń bèrè pé ṣé wọ́n pa Turkey níbí ni,

Lai Mohammed ni awọn ologun n ṣiṣẹ takuntakun lati gbogun ti igbesunmọmi kaakiri orilẹede Naijiria.

O ni ko si otitọ kankan ninu ọrọ ti aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri naa sọ.

Minisita naa fikun un pe o da oun loju pe iru iṣẹlẹ to waye ni oju ọna irin Abuja si Kaduna ko tun ni waye mọ nitori ijọba n gbe igbesẹ nipa ipese ohun eto aabo si awọn ọna oju irin naa.

Àkọlé fídíò, Fake pastors:

Bakan naa lo fikun un pe awọn ẹṣọ alaabo yoo tunbo tẹra mọ iṣẹ lati ma a ṣọ awọn oju irin naa, to fi mọ ikọ awọn ọmọogun ofurufu.

O kere tan eniyan mẹjọ lo padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ ọkọ oju irin naa, ti eniyan mejidinlaadọjọ si di awati.

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa, ti ọpọ si sọ pẹ ijọba ko ṣeto lori iṣẹlẹ igbesunmọmi to fi mọ eto aabo to denukọlẹ ni Naijiria.

Ẹ̀tànjẹ lásán ni, tí ẹnì kan bá sọ pé òun le dá yanjú ìṣòro ètò ààbò ní Naijiria báyìí - Obasanjo

Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ Naijiria nigba kan, Olusegun Obasanjo ti kọminu pe ipenija eto aabo ti n kọja boseyẹ.

Obasanjo to sọ̀rọ̀ yii nilu Abeokuta lasiko to gbalejo oludije fun ipo aarẹ, Dokita Ugochukwu Williams lopin ọ̀sẹ̀, sọ pe ọrọ aabo ti de ibi ti ko ti si aabo loju popo, ko si aabo ninu ọkọ reluwe, ko si aabo ni papakọ ọkọ ofurufu.

Ọrọ to sọ yii jẹyọ lẹyin ọjọ diẹ tí àwọn agbesunmọmi ṣe ìkọlù ni oju ọna reluwe nipinlẹ Kaduna, ati papakọ ọkọ ofurufu nipinlẹ naa.

Àkọlé fídíò, 'Ojú mi méjèjì pé lọ sí ọ́fíìsì àwọn ọlọ́pàá SARS, bí mo ṣe di afọ́jú ọ̀sàn gangan lórí ẹ̀sùn jíjí pọ́ọ̀sì “customer” tí mi ò mọ

Eeyan mẹjọ lo kú. Ọ̀pọ̀ farapa, àwọn agbesunmọmi tun ji awọn kan gbe.

Obasanjo woye pe ipo ti eto aabo wa ni Naijiria, n pe fun igbesẹ to lagbara, lati ọdọ araalu, ki opin le de ba a.

O ni ipo ti eto aabo wa ni Naijiria lọwọ lọwọ tí kuro ni nkan ti ẹnikan le sọ pe oun yoo da yanju rẹ, laisi akitiyan to le láti ọ̀dọ̀ araalu.

Obasanjo sọ pe ẹtanjẹ lasan ni eyi jẹ, ti ẹnikẹni ba sọ pe oun le da yanju isoro eto aabo.

Àkọlé fídíò, 'Láti kékeré mo ti ní ọjọ́ kan lèmi náà ọ́ kọ́ Mọ́sálásí kékeré bíi àwọn bàbá wa'