Samuel Ogundeji Endsars Victim: Ohun tójú mi rí ní ọfíìsì àwọn ọlọ́pàá kògbéregbè Endsars

Àkọlé fídíò, 'Ojú mi méjèjì pé lọ sí ọ́fíìsì àwọn ọlọ́pàá SARS, bí mo ṣe di afọ́jú ọ̀sàn gangan lórí ẹ̀sùn jíjí pọ́ọ̀sì “customer” tí mi ò mọ

Ṣe ẹ ranti iwọde lodi si iṣẹ awọn ọlọpaa kogberegbe Endsars ni Naijiria eyi tawọn eeyan ti n pariwo ṣaaju iwọde ti wọn tun ṣe ati ọpọlọpọ fa ki n faa to waye laarin ijọba atawọn araalu eyi ti ko tii tan nilẹ titi di asiko yii?

Ọkan lara awọn ti igbaju, ifọti, igbamu ati lilu awọn ọlọpaa Endsars ti yi agọ ara rẹ pada sọ ohun to la kọja lọwọ awọn ọlọpaa fun BBC Yoruba.

Samuel Ogundeji Endsars Victim

Ẹni ọdun mẹtalelogun ni Samuel Ogundeji Olamide to si ni ipenija oju bo tilẹ jẹ pe wọn ko bii ni afọju, ọrọ rẹ jẹ kayefi.

Nitori ko ma di ẹru si awọn obi rẹ lọrun, o bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bi oṣiṣẹ ile igbafẹ kan ni agbegbe rẹ ni ilu Ibadan.

Ọrọ apo owo onibara kan to sọnu ninu yara lo sọ ọ di "da bi mo ṣe da doni o latari iru ijiya to ni awọn ọlọpaa Endsars fi le oun lara.

"Awọn ọlọpaa yẹn ni ki awọn ọọfisa bẹrẹ si ni fi iya jẹ wa ki a ba le jẹwọ nipa ibi ti a fi apo owo naa si.

'Ìgbátí kan ti ọlọpaa naa fun mi, ẹ̀jẹ̀ ti bò mi lójú hìì hìì!'. Samuel ṣalaye pe igba ti yoo fi di asiko ti ọkan lara awọn ọga ileeṣẹ oun wa, iyalẹnu lo jẹ fun un pe oun ko riran mọ.

Samuel Ogundeji Endsars Victim

Koda o ni wọn o dide iranlọwọ kankan fun oun titi di ọdun 2019. "Wọn pe mi wa sori eto Yinka Ayefele ni Fresh FM ni lo fun mi lanfani ati ri iranlọwọ gba latọdọ awọn ẹlẹyinju aanu toun ri eeyan san owo ile ẹkọ fun un nile ẹkọ awọn to ni ipenija oju ni Oyo.

Pabanbari inu iroyin yii eyi to pakasọ ni pe Samuel sọ fun BBC Yoruba pe, lọdun 2017, ọga oun nibi iṣẹ yẹn pada wa sọ fun oun pe kii ṣe pe onibara yẹn tilẹ sọ apo owo rẹ ọhun nu, wọn ni o gbagbe rẹ si ile ko to wa gba yara ni ile itura ti oun ti n ṣiṣẹ ni.

Koda, o tun pada gbọ iroyin pe Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti dide fun iranlọwọ oun to si ti fun un ni ẹkọ ọfẹ eyi ti kii ṣe owo kekere rara.

Amọ ọrọ ko ba mọ, oju Samuel ti bábá fọ lọdọ awọn ọlọpaa SARS.

Samuel Ogundeji Endsars Victim