Lizzy rains curses on ESABOD: Kí ló le tó bẹ́ẹ̀ láàrin Lizzy Anjorin àti ESABOD tí àṣírí títú ṣe pọ̀ tó yìí?

Lizzy Anjorin and ESABOD

Oríṣun àwòrán, OTHERS

"Inu saare ni maa ti maa ba ọkọ rẹ sun, tori o ni pe nitori mo fẹ maa fẹ ọkọ rẹ ni mo ṣe n bu ẹ".

Ọrọ to bẹ silẹ laarin gbajugbaja sọrọsọrọ ori ayelujara, Esther Aboderin ti ọpọ mọ si ESABOD ati gbajumọ oṣere Yoruba Lizzy Anjorin ti mu ki awọn eeyan maa bẹ awọn mejeji pe ko yẹ ki wọn baa debi ohun ti wọn n ṣe lọsẹ yii.

Ẹni to bẹrẹ ija yii gangan ko ye nitoripe ko i tii pẹ ti wọn ṣẹ jami lori ọrọ kan na laarin awọn mejeji torinaa ao le sọ boya ọkan lo wọ inu omii.

Ohun to tun ṣẹṣẹ n ru jade bayii to fara han loju opo awọn mejeji ni pe ojo epe n rọ bii omi wọọ laarin awọn mejeji ti ko si ṣee fẹnu sọ.

Ka fi ibi deeti taa ri lori awọn fidio taa ri sọ ọ:

Ninu fidio kan ti Mama ẹni ọdun mọkanlelọgọta naa, ESABOD fi sita lori ayelujara ni oṣu to kọja, o n ṣalaye pe oun ni ki Lizzy fi fọtọ awọn goolu kan ranṣ si oun amọ o mu u bu pe fidio ara rẹ lo n fi ranṣẹ.

O tun ni ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti Lizzy ṣe lo ti fi ẹnu ara rẹ tu aṣiri mọlẹbi rẹ sita paapaa ọrọ to sọ nipa awọn ọmọ ọkọ rẹ ti awọn iyawo tẹlẹ bi fun ọkọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Olaiya Igwe ló wá ra epo níbi tí mo ti ń di "nussle" epo mú mo bá bẹ́ mọ́ ọ́, bí ayé mi ṣe yí padà di òṣèré fíìmù rèé

Eyi tumọ si pe ọrọ ọja goolu gangan ni wọn kọkọ bẹrẹ si ni ba ara wọn sọ ko to di pe o di ọrọ ija de bi pe ESABOD bẹrẹ si ni sọ awọn ọrọ to lee run Lizzy ninu sita lori ayelujara bi oku oun yoo ṣe pin ẹra ara Lizzy yẹlẹ yẹlẹ ati bi oku oun yoo ṣe maa ni ibalopọ pẹlu ọkọ rẹ ninu saare. Koda o tun gbẹnu le ọrọ lori awọn ọmọ Lizzy.

Ki ni Lizzy sọ?

Ni idakeji, Lizzy Anjorin naa fi fidio kan sita ninu eyi to ti binu gidi to ni ẹni to ba o ku na ti oun a gbee gba atawọn mii ti wọn ba jọ n ṣe bẹẹ... Epe lo fi bẹnu fun oun ati awọn ọmọ rẹ.

"Adabi ti mo ba ṣẹ ẹ, adabi ti mo ba jẹbi gbogbo ẹsun too fi kan mi, adabi ti mo ba sọrọ awọn ọmọ ẹ". Lo ba kẹnu bọ epe lati fesi si gbogbo ọrọ ti ESABOD sọ nipa oun ati idile rẹ.

Lizzy Anjorin ni "Esther Tokunbo Aboderin, im o ni jọ lori aye mi, ile mi, ifọkanbalẹ mi ati ile mi, ati iwọ atawọn to n ṣiṣẹ fun, atawọn to n gbeja". Oun naa ba fi epe ranṣẹ si awọn ọmọ ESABOD.

Àkọlé fídíò, 'Ojú mi méjèjì pé lọ sí ọ́fíìsì àwọn ọlọ́pàá SARS, bí mo ṣe di afọ́jú ọ̀sàn gangan lórí ẹ̀sùn jíjí pọ́ọ̀sì “customer” tí mi ò mọ

ESABOD ti wa ṣaaju sọ pe ṣebi Lizzy loun fẹ pa oun ni tori naa to ba pa oun ni oku oun yoo ṣe gbogbo nkan ti oun n sọ yii o.

Ohun ti mama yii ṣe dun Lizzy to bẹẹ to pe orukọ gbogbo awọn ọmọ rẹ ni kọọkan to si n ṣepe fun wọn amọ to ni ki gbogbo epe to n ṣẹ fun idile oun ati Arike to jẹ amugbalẹgbẹ rẹ parapọ ko di adura fun awọn.

Lizzy ni ESABOD ti ṣẹ oun o si ṣẹ iṣẹda oun to si ni ninu ibanujẹ loun fi n pa aṣẹ ṣepe fun oun ati idile rẹ.

"O ti ba mi jẹ o ti ba mi mu, o ti ba mi mulẹ o ti gba ninu oogun mi, o dẹ da mi, latoni lọ Tokunbo..." Epe ba tun bẹrẹ.

Ninu fidio mii ti ESABOD fi sita, o ni Lizzy pe oun lori fidio ori foonu to si n sọrọ bii pe o n pee bii awọn aye, atohun ati Arike to si ni oun n dahun lohun amọ to n fi oun wọle pe ki Arike mu oun so ko ma jẹ ki oun lọ.

Bi ẹ ko ba gbagbe, aarin ESABOD ati Lizzy Anjorin dan mọran gidi gan tẹlẹ to bẹẹ to jẹ wipe ESABOD funra rẹ ni awọn jọ wa pọ tẹlẹ ni bẹẹ si ni Lizzy naa ni awọn jọ wa tẹlẹ ni koda ti wọn jọ n gbeja ara wọn lori awọn to n tako wọn nile ati loke okun amọ o ni o da oun gidi bayii.

Àkọlé fídíò, Seye Malaolu: Bí mo ṣe rí àgbára ẹ̀jẹ̀ tó kúnlẹ̀, mò ń bèrè pé ṣé wọ́n pa Turkey níbí ni,