Olasimbo Okusanya US Amala seller: Pé mo jẹ́ Alamala kò ní kí n máa múra ìdọ̀tí, ibi tí Amala títà f'Oyinbo gbé mi dé rèé

Àkọlé fídíò, 'Mo kọ́kọ́ máa ń ro Amala mi fáwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́fẹ̀ẹ́ l'Amẹ́ríkà kí ojú mi tó ṣí tó ń já owó gidi fún mi báyìí'

Ẹni to ba mọ ọna aa gba gidi gan to si tun foju wo ilẹ daadaa, yoo mọ ọna ati mu owo wọle ni ilu oyinbo.

Ọmọ bibi ilu Ijebu Arabinrin Olasimbo Okusanya Idowu to jẹ oludari ati alaṣẹ ileeṣẹ Alamala kan ni ilu orilẹede Amẹrika.

"Tori pe mo n ta Amala, ko tumọ si ki n mura ni imura idọti, bi eeyan kan o ba fẹ jẹ Amala tẹlẹ̀ gan, to ba ti ri imura mi, Amala yoo wu u jẹ".

Olasimbo ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba ṣalaye bi o ṣe maa se oriṣiriṣi ounjẹ ilẹ Afirika to fi n tọ́ awọn eeyan lẹnu wo ni oniruuru ayẹyẹ nilẹ Amẹrika koda ko yọ awọn oyinbo silẹ ti wọn n yọ abọ sọwọ niwaju rẹ lati gba Amala ati Gbẹgiri.

"Ti mo ba se Amala, mo kọkọ maa n fun awọn eeyan jẹ ni ọfẹ ni amọ igba ti awọn eeyan bẹrẹ si ni sọ fun mi pe ounjẹ ti mo se dun gan ti mi o dẹ ri iṣẹ kankan ṣe tẹlẹ ni mo ba sọ ọ di iṣẹ".

Olasimbo Alamala yii ti di ilumọka bayii, kii ṣe tori pe o ni ile ita ounjẹ nikan amọ bo ṣe maa n yọ bi ọjọ pẹlu koko Amala gbigbona ati oriṣiriṣi ọbẹ Yoruba to fi mọ Ẹmu Ogurọ fawọn ọmọ Naijiria to wa loke okun.

Bo ṣe bẹrẹ iṣẹ yii naa kii ṣe pe o dede burẹkẹ, o ṣalaye bi ko ṣe kọkọ ri nkan ṣe nigba to de London ko to fẹ ọkọ rẹ to mu u lọ Amẹrika nibi to ti jẹ oniṣowo nla Alamala bayii.