Sunday Igboho: Bí Nàíjíríà bá dàbí Benin Republic ni, ń kò ní lọgun fún òmìnira Yorùbá

Ile ni abọ sinmi oko, ko sibi to si dabi ile ni ẹy n ke.
Eyi lo mu ki gbajugbaja asaaju ijagudu fun ominira Yoruba, Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho fi kede pe oun n bọ wa sile laipẹ jọjọ.
Sunday Igboho fi ọwọ idaniloju sọya bẹẹ ninu fidio kan to se pẹlu ọjọgbọn Banji Akintoye, Wale Adetiran ati agbẹjọro rẹ, Ibrahim Salami.
- Àwọn DSS àti ṣọ́jà ló kọlu ilé mi, mo fojú mi kòrókòró rí wọn - Sunday Igboho
- Wo ìgbà márùn-ún tí wọn saáyan láti mú Sunday Igboho
- Ifasooto gbòmìnira lẹ́yìn oṣù mẹ́fà látìmọ́lé DSS lórí ẹ̀sùn pé ó ń ṣ'òògùn fún Sunday Igboho
- DSS 20, Sọ́jà 200 àti Babaláwo mẹ́ta ló kọlu ilé Sunday Igboho
- DSS kò mú mi lọ́dọ̀ Guru Maharaji, èmi rèé n‘Ibadan, ẹ sinmi àhesọ ọ̀rọ̀ - Sunday Igboho
- Ìyàwó Adogan tí DSS pa nílé Sunday Igboho ń fi ẹkún bèèrè òkú ọkọ rẹ̀
- Mo gbọ́ pé babaláwo mẹ́ta ló tẹ̀lé àwọn DSS lọ sí ilé Sunday Igboho- Gani Adams
- Ìkọlù DSS sílé Sunday Igboho tàpá sófin, ìwà ìjọba ológun ni - Falana
- Ẹgbẹ́ ìlànà ọmọ Oodua fi ìròyìn ayọ̀ ránṣẹ́ lórí Sunday Igboho
Ajafẹtọẹni naa wa n ke tantan pe ko si ohun to le da oun duro lai pada si orilẹede Naijiria nitori ilu ẹni, ni ilu ẹni.
Sunday Igboho to ṣe fidio naa ni ọjọ Keje, Osu Kẹrin, ọdun 2022 eyi to tẹ BBC Yoruba lọ́wọ́, ni ọjọ naa lo pe oṣu kan ti wọn gba oun silẹ ni ọgba ẹwọn ilu Cotonou lorilẹede Benin Republic to wa.
Ijọba Naijiria yoo san gbogbo owo to jẹ mi - Sunday Igboho
Bakan naa, nigba to n salaye awọn ohun ti yoo se to ba de Naijiria pada, Sunday Igboho ni oun yoo gba gbogbo owo tijọba Naijiria jẹ oun pada.
"ijọba Niajiria gbọdọ san gbogbo owo ti wọn jẹ mi, iyẹn ogun biliọnu naira ti ileẹjọ ni ki wọn san pada fun mi gẹgẹ bi owo gba ma binu ti ileẹjọ ni ki wọn fun mi."
Bẹẹ ba gbagbe, ile ẹjọ lo pasẹ pe ki ijba apapọ san ogun biliọnu naira fun Igboho lẹyin ikọlu ti awọn osisẹ DSS ṣe ikọlu sile rẹ, ti ẹmi awọn olubaṣiṣẹ rẹ meji si lọ si iṣẹlẹ naa.
Bakan naa ni wọn ba ọpọ dukia jẹ eyi to to ọpọ biliọnu naira, ti wọn si tun ko awọn alabasisẹpọ rẹ mejila si ahamọ wọn.
Ẹsun iditẹgbajọba ni ijọba orilẹede Naijiria fi kan Sunday Igboho lasiko naa, ti wọn si ni o n ko ohun ijagun jọ lati gbogun ti ijọba orilẹede Naijiria.

Igboho ti dé padà! òòsà dé! mi ò sàìsàn! kokoko lára le - Sunday Igboho
Bakan naa, Sunday Igboho ti kede ipadabo rẹ si orilẹede Naijiria laipẹ nitori naa o ni ki awọn ọmọ Yoruba fi ọkan balẹ.
Ninu fidio to sẹsẹ gbe sita naa, lo ti bu ẹnu atẹ lu awọn ọrọ ahesọ ti awọn eniyan n sọ kaakiri nipa ilera rẹ.
Igboho ni ko si otitọ kankan ninu ọrọ to sọ wipe oun ṣe aisan, ti o si kan saara si aarẹ orilẹede Benin Republic to ṣe alaabo fun un.
''Mo dupẹ lọwọ awọn baba wa, Banji Akintoye, Ọjọgbọn Wale Adeniran ati agbẹjọro mi, Ibrahim Salami (SAN)''
"Ẹ bami dupẹ lọwọ awọn ọmọ Yoruba, ẹ ku aduro ti''
''Idi ti ifoya fi wa nipa mi ni pe awọn eniyan n bẹru wọn fẹ gbohun mi! alaafia ni mo wa''.
''Bakan naa irọ ni pe aarẹ orilẹede Benin Republic, Patrice Talon da ọmọ Yoruba''.
Sunday Igboho fikun un pe ara oun ya to si jẹ kokoko ni ara ọta le.
Ti Naijiria ba ri bi Benin Republic mi o ni lọgun fun Yoruba Nation- Sunday Igboho
Ninu fidio ti Sunday Igboho fi lede naa lo ti sọ awọn ohun ribiribi ti aarẹ Talon ṣe si ilu Benin Republic.
Igboho ni gbogbo amayedẹrun to fi mọ omi, ina ọba ti ko fi igba kan lọ ri ati eto aabo to munadoko.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtara láti du ẹ̀mí mi gbópọn si torí ìfẹ́ tẹ fi hàn mí - Kemi Afolabi
- Awuyewuye ń lọ lóri pé ìgbéyàwó òṣèrébìnrín Yewande Adekoya forí sánpọ́n
- $50,000 ti mo rí he, tí mo da padà, mú ìyípadà bá ayé mi - Emmanuel
- Igboho ti dé padà! òòsà dé! mi ò sàìsàn! kokoko lára le - Sunday Igboho
- Ṣé Iyabo Ojo ń gbèrò láti ṣe ìgbéyàwó? Wo àwọn ohun tó sọ nípa olólùfẹ́ rẹ̀
- Àyè wá dà, èmi ti ní ọ̀rẹ́kùnrin míràn nítèmi o - Nkechi Blessing
- Wo àwọn ìlú tó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti èèwọ̀ ni kí ènìyàn kú níbẹ̀
- Àwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí ilé Kọmíṣọ́nà, jí ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ gbé lọ
- MC Oluomo di alága ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò ìpínlẹ̀ Èkó
O dupẹ pe Aarẹ naa ri pe irọrun ni oun wa, ti ẹwọn kii si ṣe ibi iya fun oun, ti wọn si gba oun laaye lati ri awọn mọlẹbi rẹ ni igba de igba.
''Irọrun ni, ohun ti mi o le ṣe ni ẹwọn ni ki n ba iyawo mi ni ibaṣepọ, ohun gbogbo ni Aarẹ ilẹ Benin fi tẹ mi lọrun''.
''Gbogbo eniyan lo n gbe ni irọrun, osu meje ti mo lo ni ẹwọn ina ko ṣẹju, omi ko si lọ''.
''Olori pipe ni awọn to n ba aarẹ ṣiṣẹ, ko si idaṣẹsilẹ, ẹ bawa wa awọn eniyan bii Talon ni ilẹ Yoruba".
Sunday Igboho fi kun un pe ọ"rọ ẹyin ni pe ara mi o da, kokoko lara ọta le".





















