Emmanuel Tuloe: Ọ̀kadà ni mò ń wà àmọ́ ọ̀pọ̀ oríire wọlé tọ̀ mi torí mo jẹ́ olóòtọ́

Ọrọ nkan to ṣẹlẹ si arakunrin Emmanuel Tuloe lorileede Liberia fẹ jọ bi arosọ.
Arakunrin ẹni ọdun mọkandilogun to wọ aṣọ ileẹkọ alawọ omi aro yii yatọ si awọn to wa ni kilasi rẹ nitori o gba to ọdun mẹfa lọwọ ọpọ ninu wọn.
Amọ idunnu ati ayọ lo fi darapọ mọ awọn akẹkọọ akẹgbẹ rẹ.
Lọdun to kọja, Emmanuel ṣi n tiraka gẹgẹ bi ọlọkada, ki o to he owo to to ẹgbẹrun lọna aadọta dọla lẹgbẹ titi.
Owo naa, to jẹ owo dọla ilẹ Amẹrika ati owo ilẹ Liberia, wa ninu ọra kan to ti ri he.
Iru owo ọhun, fun ọpọ eeyan lee dabi pe adura ti gba niyẹn ṣugbọn kaka ko ko owo yii pamọ fun ilo ara rẹ, Emmanuel gbe fun anti rẹ kan ko ba oun gbe pamọ.
Nigba ti ẹni to ni owo naa si kede lori redio ilẹ naa pe kawọn to ba ri owo naa ṣaanu oun, Emmanuel jade pe lọdọ oun ni owo naa wa.
Ọpọ oriire wọlke tọ Emmanuel tori pe o jẹ olotitọ:
Ariwisi ọtọọtọ lo ba igbesẹ rẹ ọhun wa, bawọn kan ṣe n fi ṣe yẹyẹ pe agọ ni, awọn mii sọ pe inu iṣẹ ohun oṣi ni yoo ku si.
Amọ nkan ti Emmanuel ṣe naa ko oriire mii ba, ti wọn si gba a si ileẹkọ gbajugbaja Ricks Institute to wa ni Liberia.
Lara oriire mii to tun de ba Emmanuel ni pe aarẹ George Weah tilẹ Liberia fun ni ẹgbẹrun mẹwa dọla, nigba ti oludasilẹ ileeṣẹ iroyin kan naa si ṣeto ẹdawo fun un lati ọwọ awọn oluworan rẹ.
Ẹni to ni owo ti Emmanuel ri he naa si fun ni ọja ti iye owo rẹ to ẹgbẹrun kan abọ dọla.
Pabanbari rẹ ni ile ẹkọ fasiti Amẹrika kan to gbọ nipa nkan ti Emmanuel ṣe, to si ni kete to ba pari ileẹkọ girama, eto ẹkọ ọfẹ n duro de e ni Amẹrika.

'O da ki eeyan jẹ olootọ'
Nigba to n woye bi awọn eeyan ṣe fi ṣe yẹyẹ tori pe o da owo pada, Emmanuel sọ pe oun le fi owo naa tun igbesi aye ara oun ṣe ṣugbọn ''oun yoo padanu oore to ba oun loni''
Emmanuel dupẹ lọwọ Ọlọrun to fun ni anfaani awọn ẹbun to ri yi, to si tun ni '' Mo dupẹ lọwọ awọn obi mi to kọ mi pe ki eeyan jẹ olootọ''
O ni ''Imọran mi sawọn ọdọ ni pe o da ki eeyan jẹ olootọ, ma mu nkan ti kii ba ṣe tiẹ''
Bakan naa ni awọn olukọ ni ile ẹkọ Ricks mọ riri bi Emmanuel ṣe wa si ile ẹkọ wọn.
''Kii ṣe pe a jẹ anfaani jijẹ olootọ rẹ nikan ni ile ẹkọ wa, oun ni aṣọle nidi ere bọọlu fun ikọ agbabọọlu wa.''
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Igboho ti dé padà! òòsà dé! mi ò sàìsàn! kokoko lára le - Sunday Igboho
- Ṣé Iyabo Ojo ń gbèrò láti ṣe ìgbéyàwó? Wo àwọn ohun tó sọ nípa olólùfẹ́ rẹ̀
- Àyè wá dà, èmi ti ní ọ̀rẹ́kùnrin míràn nítèmi o - Nkechi Blessing
- Wo àwọn ìlú tó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti èèwọ̀ ni kí ènìyàn kú níbẹ̀
- Àwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí ilé Kọmíṣọ́nà, jí ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ gbé lọ
- MC Oluomo di alága ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò ìpínlẹ̀ Èkó
N jẹ o si mọ pe alatilẹyin ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ni Emmanuel? to si maa n ba awọn akẹkọọ to sunmọ lọjọ ori gba bọọlu loore koore.
Awọn akẹgbẹ Emmanuel naa a tun maa dunnu si pe o darapọ mọ wọn ni ile ẹkọ wọn.
Akẹkọọ kan ẹni ọdun mọkanla, Bethelene Kelley pe Emmanuel ni ''ọrẹ gidi to nifẹ lati maa pin nkan to ni pẹlu awọn ẹlomiran, kii sọrọ pupọ. O jẹ olootọ, o si ni irẹlẹ''
Caleb Cooper, ẹni ọdun mejila naa loun mọ iyi rẹ nitori bo ṣe maa n huwa ninu kilasi ati ni ibugbe awọn akẹkọọ.
Nibi ti Emmanuel si ti fi awọn ọlọkada naa silẹ, ki jọ pe awọn wọnyi naa n jowu rẹ pẹlu bi nkan ṣe yi pada fun.

Oríṣun àwòrán, Getty images
Ọkan ninu awọn ọlọkada yii, Lawrence Fleming to jẹ ẹni ọgbọn ọdun sọ fun BBC pe oun ko pari ẹkọ oun ati pe oun n fọkan ba itan Emmanuel bọ.
''Nkan daada ni pe Emmanuel pada si kilasi. A dupẹ fun Ọlọrun''
Bi Lawrence ṣe duro lẹgbẹ ọkada rẹ ni agbegbe Brewerville, o fi ọrọ imọran tirẹ naa ṣe ọrọ ikẹyin.
''Ki Emmanuel ya pari ẹkọ rẹ ni nitori ọjọ iwaju rẹ, tawọn ọmọ rẹ...o ti ni anfaani ti ọpọ ninu wa ko ni''




















