Jimi Solanke: Bí a ṣe bẹ̀rẹ̀ eré òṣùpá láyé àtijọ́ táa mú ìtàn Yorùbá sísọ dé America padà walé

Àkọlé fídíò, Jimi Solanke: Bí a ṣe bẹ̀rẹ̀ eré òṣùpá láyé àtijọ́ táa mú ìtàn Yorùbá sísọ dé America padà

Bẹẹ ba jẹ ololufẹ itan ilẹ Yoruba, bẹẹ ba tilẹ jẹ irọ èèyàn to n jẹ Jimi Solanke, ẹ o mọ nipa rẹ gidi gan tori oguna gbongbo ni Solanke to jinlẹ gidi gan ninu aṣa ilẹ yoruba ati fifi le ọmọ ati irandiran lọwọ.

Gbajugbaja akọtan ohun asọtan, olorin ibilẹ, akọ ewi to tun jẹ agba oṣere ni Alagba Jimi Solanke onimọ tiata si ni pẹlu.

O ti le ni aadọta ọdun to ti lo ninu iṣẹ tiata nipa gbigbe aṣa ibilẹ Yoruba ati agbegbe rẹ ga.

Jimi Solanke

Fun ọpọlọpọ to wo awọn ere ori itage bii Kurunmi ati Ovonramwen Nogbaisi ti Ola Rotimi kọ, Death and the King's Horseman ti Wole Soyinka kọ ati bẹẹ bẹẹ lọ, wọn mọ pe gbagada ni oju Jimi solanke wa ninu awọn ere naa tori oun ni o ko ipa to tobi julọ ninu wọn.

"Emi ni Kurunmi ninu ere Kurunmi, emi ni Ovonramwen ninu ere Ovonramwen Nogbaisi emi si ni Elesin gangan ninu ere "Iru Olokun Esin" eyi to mu mi gbe ni ilẹ Benin fun nkan bii ọdun mẹfa".

Ni ẹka ti orin, ọpọlọpọ orin ati orin itan ni Baba Solanke ti kọ ati eyi ti ko tilẹ tii gbe jade rara rara.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo manigbagbe yii pẹlu BBC Yoruba, ẹni ọgọrin ọdun yii kọ lara awọn orin rẹ fun wa.

Awọn orin ọmọde naa ko gbẹyin nibẹ gẹgẹ bi ohun baba Solanke ṣi ṣe n dan ninu orin yii:

"Eni bi eni, eji bi eji, ẹta ntagba, ẹrin wọrọkọ, arun nkolo..."

Jimi Solanke sọ idi ti ko fi le fi ọrọ aṣa Yoruba ati Ifa silẹ lailai tori o ni iṣ ti oun n ṣe lo ṣi mu oun wa laye di oni.