Seyi Makinde: Láàrin àáwọ̀ àárín ẹgbẹ́ PDP, ìdí tí mo fi fẹ́ lọ fún sáà kejì gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Oyo rèé

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, SeyiMakinde/Facebook

Àkọlé àwòrán, Mo fe se isẹ rere

Gomina ipinlẹ Oyo Seyi Makinde ti fesi si idi to fi fi erongba rẹ han lati dije du ipo gomina fun saa keji.

Agbẹnusọ fun gomína ìpinlẹ Oyo Taiwo Adisa fi aridaju iroyin naa han pe gomina ipinlẹ Oyo Seyi Makinde ti fì erongba rẹ hàn látí dìje dupo gomìnà ípìnlẹ̀ Oyo.

O jẹ ko di mimọ pe nigba ti gomina fi ọrọ naa lọ awọn eeyan ni ẹlẹgbẹ jẹgbẹ ni ipinlẹ Oyo bẹ Makinde lati dije lẹẹkan sii.

Bo tilẹ jẹ pe aawọ oriṣiriṣi lo wa nínù ègbẹ ṣùgbọ́n gòmìnà Makinde ti gbé igbèṣẹ̀ látì mu òpìn ba gbògbò ikùnsínù to wa nínù ẹgbè oṣelu PDP nìpìnlẹ óyò nìtórì gbògbò ádárì inu ẹgbẹ ni gòmìnà Makinde ṣe ìpàdé pẹlu.

Àkọlé fídíò, Seyi Makinde: Ẹ̀yin tẹ́ fẹ́ fi ọ̀rọ̀ ẹ̀sin ba Oyo jẹ́, ẹ ṣọ́ra ṣe
Àkọlé fídíò, Makinde vs Adelabu: Makinde ní ìjọba Ọyọ yàtọ̀ sí ti Ọṣun àbí Ekiti tí APC lé dànù

O ṣalaye pe awọn iṣẹ ìlù tì gòmìnà Mákìndè ti bẹrẹ látí 2019 ló ní láti ṣe pari.

Lara aawọ mii to tawọn eeyan tun maa n sọrọ gẹgẹ bii aawọ to wa laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP nilẹ Yoruba tun ni eyi to wa laarin Makinde ati Ayo Fayose, gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ.

Ẹwẹ, ọrọ yii ko yọju rara ninu iwadii wa tori gomina Seyi Makinde ni ko si ẹnikẹni ti ẹgbẹ yan ti oun ko ni ti lẹyin.

"Niwọn igba to ba ti jẹ afẹnuko ẹgbẹ wa ni, digbi ni mo wa lẹyin ẹni ti ẹgbẹ ba fẹnuko le lori koda bo ṣe gomina Ekiti tẹlẹ, Ayo Fayose".

Ti ẹyin ara ilu Oyo ba gba mi laaye, ṣe mo ri 'kan sii?

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti fi ero rẹ han lati dije dupo gomina fun saa keji ni ipinlẹ Oyo.

Makinde fi eyi lede ninu lẹta ti o ma n fi lede fun awọn eniyan ni ẹẹmẹji ni oṣu.

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, O ni oun ti ṣeleri ninu lẹta oun ti saa to kọja wi pe nigba ti eleyii ba ma a fi jade, oun ati pinnu boya lati dije dupo fun saa keji gẹgẹ bi gomina nipinlẹ Oyo.

Àkọlé fídíò, Bí wọ́n ṣe ń gbé àwọn akẹgbẹ́ mi tó jóná nínú ọkọ̀ jáde, ṣe lara wọn ń bó, wọ́n ń tẹ́ wọn s'atẹ́gùn - Akẹkọ̀ọ́ Akungba

''Ọsẹ to kọja ni mo gba fọọmu lati fi ero mi han nipa idije dupo fun saa keji gẹgẹ bi gomina awọn eniyan rere ni ipinlẹ Oyo''

''Bẹẹni mo fẹ ṣiṣẹ fun awọn ara ilu ipinlẹ Oyo lẹẹkeji ti wọn ba gbami laaye''

''Lati nkan bi ọdun mẹta ṣẹyin ni a ti n ṣiṣẹ takuntakun, ti a ko si yọ agbegbe kankan silẹ''

Seyi makinde n se ibura g bi gomina tuntun ni Ọyọ

''A ti ṣiṣẹ lati mu ipinlẹ Oyo di ilu igbalode ti awọn eniyan yoo ti ni igbeaye irọrun ti gbogbo iṣọrọ to n koju wọn yoo si di ohun igbagbe.

Gomina ipinlẹ Oyo naa fikun pe o wu oun lati ṣe gudugudu meje yaya mẹfa ju ti tẹlẹ lọ.

Ọdun 2019 ni awọn ara ipinlẹ Oyo dibo yan Seyi Makinde lati ẹgbẹ oṣelu PDP gẹgẹ bi gomina wọn.