You are a Goat comment: Leke ọmọ́ Pásítọ̀ Adeboye tọrọ̀ àforíjì ,ó kọ̀wé ẹ̀bẹ̀ sí ìjọ Redeem

Aworan Leke ati Pasitọ Adegboye

Oríṣun àwòrán, Instagram/lekeadeboye

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ọmọ Pasitọ alakoso ijọ Redeem,Leke Adeboye ti palu ẹnu da to si tọrọ aforijin lọwọ awọn pasitọ ijọ naa to pede abuku si.

Loju opo rẹ ni Instagram to ti bẹnu atẹ lu wọn naa lo pada si to ti ni ki wọn fori jin oun tori aṣiṣe ni iwa toun hu jẹ.

Adegboye ti ṣaaju tẹnbẹlu awọn Paitọ ijọ naa to ni wọn laya lati lọ ṣe iwaasu ti wọn lyin ti adari ijọ Redeem Pasitọ Enoch Adeboye ṣe iwaasu tan.

Ninu ọrọ rẹ to fi sọko ọrọ si wọn, Leke ni awọn to ṣe bẹẹ kii ṣe ọmọ bi kii ṣe pe ''ẹran ni wọn''

Ọrọ rẹ yi to kọ mu inu bi ọp eeyan kaakiri opju opo ayelujara ti awọn kan si kesi ijọ naa lati paṣẹ pe ko lọ rọọkun nile.

Mo kuna,mo si gba ijiya ti ijọ Redeem da fun mi

Leke to jẹ ọmọ bibi Pasito Enoch Adeboye la gbọ pe o koju igbimọ iwadii ẹlẹni mẹta ijọ naa lọjỌru.

A ko mọ aridaju ijiya ti igbimọ naa gbe kalẹ lori Leke ṣugbọn ninu ọrọ rẹ to kọ soju opo Instagram, o ni ohun fi tọkan tkan gba idajọ ijiya ti wọn gbe kalẹ.

Àkọlé fídíò, Leke Adeboye: Àwọn aláwáda tó fẹ́ irànlọ́wọ́ iléèwé

Ẹwẹ ninu iwe aforijin to kọ soju opo ayelujara, o ni ki wọn fori jin oun lori ''ọrọ asọju ti mo sọ''

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Bakan naa lo ni ki gbogbo adari ijọ ati awọn Pasitọ ijọ naa ti ọrọ naa ba ta ba pe ki wọn fori jin oun.