Insecurity in Nigeria: Ilana Omo Oodua kín àgbààgbà Àríwá lẹ́yìn pé kí Buhari kọwe fí ipò sílẹ̀

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ to n polongo fun idasilẹ orilẹ-ede Yoruba, Ilana Omo Oodua, Ọgbẹni Maxwell Adeleye, ti sọ pe ko si nkan to buru ninu bi awọn agbaagba ni Ariwa Naijiria ṣe sọ pe ki Aarẹ Muhammadu Buhari kọwe fi ipo rẹ silẹ.

O sọ eyi gẹgẹ bi esi si atẹjade ti ẹgbẹ Northern elders Forum fi sita lọjọ Iṣẹgun pe Buhari ko kajuẹ lati pese aabo fun orileeede Naijira.

Ọgbẹni Adeleye sọ pe asiko iwulo Buhari fun Naijiria ti tan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"A nilo aarẹ ti yoo gbọ nkan ti oriṣiriṣi ẹya to wa ni Naijiria n sọ."

O ni ka ni Buhari n ṣe daadaa ni, ko ni si idi kankan fun ẹgbẹ Ilana Omo Oodua lati ma a beere fun idasilẹ oríle-ede Oduduwa, tabi Biafra ti awọn Igbo n beere fun.

Adeyeye sọ pe ko si nnkan to buru ninu ki Buhari kọwe fi ipo silẹ, bo tilẹ jẹ pe o ti lo ọdun meje nipo.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn Àgbààgbà Àríwá ní kí Buhari kọwe fí ipò sílẹ̀ tí kò bá rí ojútùú sí ààbò tó mẹ́hẹ

Awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Agbarijọpọ awọn agbaagba ilẹ Ariwa Naijiria ti kesi ààrẹ Muhammadu Buhari pe ko kọwe fipo silẹ.

Wọn ni igbesẹ yii di dandan pẹlu bi ko ṣe kajuẹ lati pese aabo fun orileeede Naijira.

Agbẹnusọ awọn agbaagba fun ariwa naa, Hakeem Baba-Ahmed lo fi ọrọ yi sita ninu atẹjade kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn agbaagba naa sọ pe idojuti nla ni pé lẹyìn nkan bi ọdun meje ti Buhari wa lórí aleefa, ko ri ojutu si ipenija aabo to n koju Naijiria.

Atẹjade naa ni "Ko jọ pe ijọba ààrẹ Buhari ni idahun sí àwọn ipenija aabo tá n koju"

Àkọlé fídíò, Oluyemisi Orisabiyi: Ẹ̀ẹ̀mẹta péré làwọn òṣìṣẹ́ KAI bẹ̀ mí wò, mo kọ̀wé sí wọn lái rí èsì

"A ko le máa gbé igbe aye aifọkanbalẹ labẹ awọn ajinigbe, apaniyan ati awon to n fipa ba ni lopọ, ti wọn ti gba ẹtọ igbe aye alaafia ati aabo lọwọ wa"

Atẹjade naa tẹsiwaju pe iwe ofin Naijiria fi igbalaye silẹ pe ki olori ti ko ba rojutu ìjọba to n dari, fi t'inu fẹdọ kọwe fipo silẹ"

O ni nitori naa "asiko ti to ki ààrẹ dipo silẹ nitori ijọba rẹ kuna lati pese aabo fun araalu.O ye wa bi ọrọ yi se wuwo sí bẹẹ náà ni ko ruju pe a ko le máa gbé igbe aye ibẹrubojo bayi titi di ọdun 2023 ti aarẹ Buhari yoo fipo silẹ"

Ipo wo ni aabo Naijiria wa bayi?

Ko fẹẹ si apa kan orileede Naijiria ti ipenija aabo to n koju Naijiria yii ko dé.

Yala nipa awọn agbebọn, agbesunmọmi, ajinigbe tabi awọn janduku, ipenija aabo yii jẹ nkan to n koju araalu.

Ni apa Ariwa Naijiria, o sebi ẹni peleke ju awọn ibomiran lọ pẹlu bi awọn janduku ti ṣe jẹ gaba lori araalu, ti awọn eeyan sí wa ninu ibẹrubojo.

Lẹnu ọjọ mẹta yíi, iroyin orisirisi ni o gba ori afẹfẹ kan, ti a sì n gbọ nipa àìmọye eeyan ti o padanu ẹmi wọn lọwọ àwọn alaburu naa.

Ni ipinlẹ bii Kaduna, Plateau, Kebbi, Zamfara to fi mọ Borno ati ibomiran, ojoojumọ ni awọn araalu n gbe oku sin ti awọn alaburu ẹda sí n fun okun mọ alaafia ati aabo lọrùn.

Amin iyasọtọ kan

Èèmọ̀ wọ̀lú! Àwọn agbébọn pa ènìyàn 135 lọ́jọ́ kan ṣoṣo

Àwọn ìlú tí wọ́n jó níná
Àkọlé àwòrán, Àwọn ìlú tí wọ́n jó níná

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe kò dín ní ènìyàn márùndínlógóje tí àwọn agbébọn ṣekúpa ní ìpínlẹ̀ Plateau níbi ìkọlù oríṣiríṣi tó wáyé ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹwàá, oṣù kẹrin.

Ìlú mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìjọba ìbílẹ̀ Kanam ni àwọn agbébọn náà ṣe ìkọlù sí lórí ọ̀kadà, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní yìbọn mọ́ àwọn ènìyàn, jó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé, tí wọ́n sì tún jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ málùú gbé lọ.

Ọ̀kan lára àwọn olórí nínú àwọn ìlú náà tó bá ikọ̀ ìròyìn BBC sọ̀rọ̀ ní òkú ènìyàn márùnléláàdọ́ta ní àwọn ti rí ní ìlú Kukawa, tí àwọn sì ti tún rí mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ní ìlú Gyambau.

Bákan náà ló tún fi kun pé àwọn tún ṣàwárí òkú ènìyàn mọ́kànlélọ́gbọ̀n mìíràn ní ìlú méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ mìíràn.

Ó ní àwọn agbébọn mẹ́rìndínlógún náà bá ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún lọ.

Ọkan lara awọn eeyan to fara gbọgbẹ

Oríṣun àwòrán, TUKUR BUHARI

Ìwádìí fi hàn pé àwọn ọmọdé àti àwọn ọ̀dọ́ wà lára àwọn tó lùgbàdì ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà.

Bákan náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti di àwátì nígbà tí wọ́n sá kúrò ní ilé nítorí ìkọlù náà.

Àwọn ará ìlú ní àwọn ti sá kúrò nílé ṣaájú kí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò tó wá sí àwọn ìlú náà ní ọjọ́ kejì.

Wọ́n ní ìkọlù yìí ni èyí tó burú jùlọ láti ìgbà tí wọ́n ti máa ń ṣe ìkọlù sí agbègbè yìí.

Ìpínlẹ̀ Plateau ti máa ń kojú ìṣẹ̀lẹ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà àti ti ẹ̀sìn ṣùgbọ́n àwọn agbébọn àti àwọn ajínigbé ti mú kí ìkọlù náà tún peléke si báyìí.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Gbẹ̀fẹ́ ní àkókò tí mo lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àìrì aya mi nìkan ní ìyàtọ̀
Amin iyasọtọ kan

Afurasí ajínigbé pàgọ́ sí Eko, wọ àdúgbò kan lẹ́ẹ̀mẹta láàrin ọjọ́ méjì

Agbebọn

Oríṣun àwòrán, NPF

Bi wọn se n ge awọn ajinigbe lọwọ, bẹẹ ni wọn n bọ oruka yika orilẹede wa Naijiria.

Iroyin kan to tun n gbalẹ bayii ni bi awọn afurasi ajinigbe kan si pagọ si ẹba agbegbe ilegbe Ayobo to wa nilu Eko.

Laipẹ yii si ni ariwo sọ nipa bi wọnb se wọle pa ọkunrin meji ti wọn jẹ ọmọ iya kan soso, ti wọn si tun ji eeyan mẹta ladugbo naa lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Afurasi ajinigbe kọlu agbegbe Ayobo nigba meji laarin ọjọ mẹta:

Gẹgẹ bi iwe iroyin Tribune ti salaye, igba keji ree ti awọn afurasi ajinigbe to dihamọra pẹlu ohun ija oloro naa, yoo ya bo agbegbe Ayobo laarin ọjọ mẹta.

Lọwọ lọwọ bayii, awọn ara adugbo naa ti fẹsẹ fẹ nitori bi wọn se kẹẹfin pe awọn afurasi ajinigbe naa ti pagọ sẹba irekọja odo to wa lagbegbe naa.

Ẹba odo yii si ni wọn pa agọ wọn si, nibi ti wọn n gbe awọn ẹni ti wọn ba ji gbe lọ, ti wọn si n gba owo idoola ẹmi lori wọn.

Ko tan sibẹ, yatọ si tẹgbọn taburo tawọn afurasi ajinigbe naa ran sọrun ọsan gangan, alaga fẹgbẹ awọn onile lagbegbe naa tun ti dero ọrun.

Eyi ko si sẹyin ojora ati iporuru ọkan to mu lasiko tawọn afurasi ajinigbe naa ya bo agbegbe ọhun.

Idi si ree tawọn olugbe agbegbe Ayobo fi n rawọ ẹbẹ sijọba pe ko wa doola ẹmi awọn lọwọ awọn afurasi ajinigbe to mule ti wọn naa.

Àkọlé fídíò, 'Mo kọ́kọ́ máa ń ro Amala mi fáwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́fẹ̀ẹ́ l'Amẹ́ríkà kí ojú mi tó ṣí tó ń já owó gidi fún mi báyìí'

Ọwọ ti ba afurasi ajinigbe kan lori isẹlẹ yii - Ọlọpaa

Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti wa sisọ loju rẹ pe oun ko kawọ gbera lori itu tawọn afurasi ajinigbe n pa ladugbo Ayobo.

Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa Eko, David Hundeyin salaye pe lootọ ni awọn isẹlẹ ijinigbe ati ipaniyan naa waye lagbegbe naa.

Hundeyin ni Kọmisana ọlọpaa ni Eko ti wa pasẹ fawọn agbofinro lati tẹdo si agbegbe naa, ti ọwọ si ti ba eeyan kan to ni nnkan se pẹlu awọn isẹlẹ ọhun.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí ilé Kọmíṣọ́nà, jí ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ gbé lọ

Agbébọn

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Agbébọn

Àwọn agbébọn ti ṣe ìkọlù sí ilé igbé Kọmíṣọ́nà fétò àyíká ìpínlẹ̀ Plateau, Usman Bamaiyi, tí wọ́n sì jí ìyàwó àti ọmọbìnrin rẹ̀ gbé lọ.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, ilé ìgbé Kọmíṣọ́nà náà tó wà ní Gindiri, ìjọba ìbílẹ̀ Mangu, ìpínlẹ̀ Plateau ni àwọn agbébọn náà ya wọ̀ ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù kẹrin.

Óṣojúmi kòró kan tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní nǹkan bí aago méjì òru ni àwọn àwọn agbébọn náà ya wọ ìlú Gindiri tí wọ́n sì lọ tààràtà sí ilé Bamaiyi.

Bamaiyi, tó tún ti fi èròńgbà rẹ̀ láti díje dupò sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin lọ́dún 2023, ni kò sí nílé lásìkò tí àwọn agbébọn náà ṣe ìkọlù sí ilé rẹ̀.

Ó ṣàlàyé wí pé lẹ́yìn tí àwọn agbébọn ọ̀hún lọ tán ni àwọn tó mọ̀ wí pé wọ́n ti jí ìyàwó àti ọmọ Bamaiyi gbé lọ.

Agbébọn àti àwọn agbéṣùmọ̀mí ti máa ń ṣe ìkọlù sí ìlú wa púpọ̀

Ọ̀kan lára àwọn ara ìlú Gindiri, Ibrahim Chindo ní kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí àwọn agbébọn yóò ṣe ìkọlù sí ìlú àwọn.

Chindo ní inú fo àyà fo ni awọn ènìyàn ìlú náà máa ń wà ní gbogbo ìgbà nítorí kò jọ wí pé àwọn yóò móríbọ́ lórí ọ̀rọ̀ náà láìpẹ́.

Nínú oṣù kejìlá ọdún tó kọjá, àwọn agbébọn yabo ìlú yìí bákan náà tí wọ́n sì jí Ọba ìlú náà, Charles Mato gbé.

Àkọlé fídíò, 'Mo kọ́kọ́ máa ń ro Amala mi fáwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́fẹ̀ẹ́ l'Amẹ́ríkà kí ojú mi tó ṣí tó ń já owó gidi fún mi báyìí'

A ti ń sa gbogbo ipá wa láti wá wọn rí - iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Plateau, Ubah Ogaba fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ṣùgbọ́n ó ní àwọn ti ń ṣiṣẹ́ láti wá àwọn tí wọ́n jí gbé náà rí.