Yewande Adekoya: N kò fẹ́ ní òkú èèyàn lọ́rùn, ẹ má bú ọkọ́ mi lórí ayélujára mọ́

Oríṣun àwòrán, others
Oṣerebinrin, Yewande Adekoya ti bẹ awọn ololufẹ rẹ lati jawọ ninu bibu ọkọ rẹ, Abiodun Thomas.
Opin ọsẹ ni iroyin jade pe igbeyawo Yewande ati ọkọ rẹ, ti oun naa jẹ oṣere tiata lede Yoruba, ti tuka.
Eyi ni iroyin sọ pe ko ṣẹyin bi Thomas ṣe n ṣe agbere, ti ko si pọn iyawo rẹ le rara.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló dé tí ọkùnrin yìí fi dojúkọ Kìnìún ààyè?
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ní pé Osinbajo dalẹ̀ Tinubu pẹ̀lú bó ṣe kéde láti du ipò ààrẹ?
- Àwọn ọmọ Palestine kọlu ìbòjì Josẹfu ọmọ Jakọbu, wọ́n dásá sún
- "Ẹ̀yin onítíátà, ẹ gbàdúrà fún Kemi Afolabi, Ọlọ́run nìkan ló mọ ibi tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò já sí"
- Oluwo ṣe àbẹ̀wò sí Aláàfin lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tó gbé ìyàwó tuntun
- Mo gbìyànjú láti ṣẹ́yún àkọ́bí mi saájú ìgbeyàwó - Iyabo Ojo
- Àgùnbánirọ̀ ya fọ́tò Bàbá Onílù láti tà á, òjò owó rọ̀ fún bàbá
- Adigunjalè kọlu iléeṣẹ́ Rédíò Yinka Ayefele ní Ibadan
Lati asiko naa si ni awọn mọ Naijiria, paapaa lori ayélujára Instagram ti n kọ awọn ọrọ eebu ati epe si oju opo ayélujára Ọgbẹni Thomas.
Ṣugbọn ninu ikede kan to fi sita lori ayélujára Instagram rẹ ni owurọ ọjọ Aje, Yewande sọ pe oun n bẹbẹ pe ki awọn eniyan ro ti ikunlẹ abiamọ mọ ọ oun lara.
"Mo mọ pe gbogbo yin lẹ n fẹ ire fun wa, ṣugbọn ẹ jọwọ, ẹ fi opin si bibu Baba Precious lori ayélujára."
Arabinrin Yewande sọ pe ti kii ba ṣe pe oun fẹ ẹ já irọ ti wọn n pa mọ oun ni, oun ko ba ma sọ nkankan nipa igbeyawo oun to tuka ni gbangba.
"Ẹ jọ ọ nitori Ọlọrun ẹ ma jẹ ki n ni oku eeyan lọrun."
O ni lootọ ni ọkọ oun ti ṣe ọpọ aṣiṣe.
"Ṣugbọn erongba mi fun ni pe ki igbeaye rẹ yi pada si rere, boya o wa pẹlu mi tabi bẹẹkọ."

Awuyewuye ń lọ lóri pé ìgbéyàwó òṣèrébìnrín Yewande Adekoya forí sánpọ́n
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe gbajugbaja oṣerebinrin lagbo tiata Yoruba, Yewande Adekoya ti pinya pẹlu ọkọ rẹ, Ishola Abiodun lẹyin igbeyawo ọdun mẹjọ.
Ninu aworan ati ibanisọrọ idakọnkọ ti Yewande ṣe pẹlu alakoso oju opo Gistlover, lo ti sọ bi o ṣe ṣẹlẹ, amọ Yewande funra rẹ ko fi iroyin naa sita.
Ninu ọrọ to ba Gistlover sọ lo ti sọ wi pe ainaani igbeyawo awọn lati ọdọ ọkọ oun ati ibanujẹ ọkan ojojumọ, lo mu ki igbeyawo wọn dopin.
- Ìtara láti du ẹ̀mí mi gbópọn si torí ìfẹ́ tẹ fi hàn mí - Kemi Afolabi
- Ṣé Iyabo Ojo ń gbèrò láti ṣe ìgbéyàwó? Wo àwọn ohun tó sọ nípa olólùfẹ́ rẹ̀
- Àyè wá dà, èmi ti ní ọ̀rẹ́kùnrin míràn nítèmi o - Nkechi Blessing
- Ẹkùn sọ bí ìròyìn ikú gbajúgbajà olórin ẹ̀mí tó kọ orin 'Ekwueme' ṣe jáde
- Mo tọrọ àforíjì pé mo parọ́ ìgbéyàwó! Mi ò ṣe ìgbéyàwó kankan!
- Wo ǹkan tí o kò mọ̀ nípa ESABOD tí òun àti Lizzy Anjorin jọ ń fi omi èpè wẹ ara wọn
Bi o tilẹ jẹ pe o salaye bi ọrọ naa ṣe ṣẹlẹ, amọ o bẹ pe ki awọn eniyan ma tabuku ọkọ oun loju opo ayelujara.
Gẹẹ bi ọrọ rẹ, pẹlu bi o ṣe ni ifẹ ọkọ rẹ to , ti wọn si ti ni ọmọ meji, niṣe ni ọkọ rẹ ma n sọrọ si lai naani rẹ gẹgẹbi obinrin.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Gistlover
Ọkọ mi kan fẹ ma a jaye kaakiri ni, ki emi ma a nikan ṣe ohun to tọ ninu igbeyawo - Yewande
Bakan naa ni o fẹsun kan an pe ko jẹ olootọ si oun ninu igbeyawo naa to si n fẹ orisirisi obinrin.
"Fun ọdun mẹrinla ni mo fi jiya ninu ile ọkọ mi, to si ma n ba mi sọrọ sakala. Ojojumọ ni mo ma n sun ẹkun ti a ba jọ wa papọ, ti mo si ma n bẹẹ ki o fi ifẹ han si mi.''
''Emi ni mo n fi owo silẹ ninu ile fun ni gbogbo igba ti a ti wa papọ, ti mi o si fi igba kan sọrọ si lori rẹ.''
''Ohun ti mo n bẹbẹ fun ni ki ọkọ mi ṣe bi ipo rẹ, ki o si bọwọ fun igbeyawo wa.''
''O kan fẹ ma a jaye kaakiri, ki emi ma a nikan ṣe ohun to tọ ninu igbeyawo''

Oríṣun àwòrán, Gistloversgram
"Ibanujẹ ati ipaya lo jẹ fun mi nigba ti mo ri pe ọpọlọpọ obinrin ni ọkọ mi n ba dọrẹ ikọkọ kaakiri"
Yewande fikun un pe oun ni ifẹ ọkọ oun, ti ko si si otitọ ninu iroyin pe oun lo pin igbeyawo wọn.
Gbajugbaja oṣerebinrin naa ni ko si otitọ ninu iroyin naa nitori ọkọ oun lo ko kuro nile, oun ko si si ni họtẹli, ile baba ati iya oun ti ko jina si ile wọn ni oun wa.
''Diẹ lo ku ki n ya were, amọ mo dupẹ lọwọ ẹbi mi, lilọ fun iranwọ ni ile iwosan ati Ọlọrun to duro ti mi.''
''Ọkọ mi lo gba ibale mi, oun ni ẹni ọkunrin ti mo kọkọ mọ, amọ ọsan kan, oru kan ni ọkọ mi ko kuro ninu ile lai sọ fun mi, ohun lo fi mi silẹ.''
Lara awọn eniyan to n fesi si iṣẹlẹ naa lori Instagram sọrọ iwuri nipa oṣerebinrin naa, nitori o jẹ ọkan lara awọn obinrin to pegede ni agbo oṣere, ti ko si ni iwa aṣemaṣe lọwọ.
Wọn ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi obinrin rere, to si jẹ ẹni to bọwọ fun igbeyawo.
Agbo oṣere naa ni ọkọ rẹ ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bi osere ati adari eto ati fiimu ni Nollywood.

Oríṣun àwòrán, Gistloversgram
Ta ni Yewande Adekoya:
Odu, ti kii se aimọ fun oloko ni Yewande Adekoya lagbo tiata lede Yoruba, to si jẹ ọmọ bibi ilu Ososa-Ijebu Remo nipinlẹ Ogun.
Ile ẹkọ fasiti Babcock to wa nilu Ilisan Remo si ni gbajumọ oserebinrin naa ti kẹkọ jade gba oye imọ ijinlẹ nipa ibaraẹnisọrọ ta mọ si Mass Communication.
Ọdun 2002 lo dara pọ mọ isẹ tiata, to si ti kopa ninu ọpọlọpọ ere sinima, amọ eyi to mu ko gbajumọ ni Ọmọ Ẹlẹmọsho to gbe jade ldun 2012.
Ọdun mẹjọ sẹyin ni oun ati ọkọ rẹ, Ishola Abiodun se igbeyawo, ti ọba oke si fi ọmọ meji si aarin wọn.
Yewande Adekoya ti gba ọpọ ami ẹyẹ ninu isẹ tiata, to si jẹ ilumọọka osere labẹle ati loke okun.
















