Àwọn ọmọ Palestine kọlu ìbòjì Josẹfu ọmọ Jakọbu, wọ́n dáná sun-ún

Oríṣun àwòrán, Times of israel
Awọn alaṣẹ ijọba ni orilẹ-ede Israel ti fi ẹsun kan orilẹ-ede Palestine pe o ba ibi mimọ kan jẹ nilu Nablus.
Eyi n waye ni bi ogun to n waye laarin orilẹ-ede mejeeji ṣe tun l'agbara si ni awọn ilu Isreal kan bi West Bank ati River Jordan.
Oju opo ayélujára ijọba orilẹ-ede Isreal kan lori Twitter fi fídíò kan sita, to si sọ pe fídíò naa n ṣafihan bi awọn ọmọ ogun Palestine ṣe n kọlu agbegbe kan ti igbagbọ wa pe nibẹ ni iboji Josẹfu ọmọ Jakọbu wa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló dé tí ọkùnrin yìí fi dojúkọ Kìnìún ààyè?
- Nǹkan mẹ́wàá tí màá ṣe fọ́mọ Naijiria tí mo bá fi di ààrẹ - Osinbajo
- "Ẹ̀yin onítíátà, ẹ gbàdúrà fún Kemi Afolabi, Ọlọ́run nìkan ló mọ ibi tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò já sí"
- Oluwo ṣe àbẹ̀wò sí Aláàfin lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tó gbé ìyàwó tuntun
- Bí Sunday Igboho bá sọ èròǹgbà rẹ̀ nípa Yoruba Nation, inú gbogbo ọmọ Yorùbá yóò dùn - Banji Akintoye
- Mo gbìyànjú láti ṣẹ́yún àkọ́bí mi saájú ìgbeyàwó - Iyabo Ojo
- Adigunjalè kọlu iléeṣẹ́ Rédíò Yinka Ayefele ní Ibadan
- Ìtara láti du ẹ̀mí mi gbópọn si torí ìfẹ́ tẹ fi hàn mí - Kemi Afolabi
Ileeṣẹ iroyin ori ayélujára kan ni Isreal, Times of Israel sọ pe Olootu ijọba, Naftali Bennett bu ẹnu atẹ lu ikọlu naa to waye ni ọjọ Aiku.
O ni "lasiko ti awọn ọmọ Palestine n ba iboji Josẹfu jẹ, ogunlọgọ wọn lo ṣe nkan eewọ ni ilẹ mimọ wa".
"Wọn fọ awọn okuta iboji naa, wọn si tun dana sun awọn iyaara to wa ninu ọgba naa."
Iroyin sọ pe bi ọgọrun ọmọ Palestine lo yabo iboji naa ni orumọju ọjọ Aiku, ti wọn si dana sun, ko to o di pe awọn ọmọ ogun Israel tu wọn ka.
Kilo de ti wọn doju kọ iboji Joseẹfu?

Oríṣun àwòrán, @IsraelArabic
Kii ṣe igba akọkọ re e ti awọn ọmọ Palestine kọlu iboji yii. Koda, ija igboro ma n waye nibẹ ni oorekoore.
Lọdun 2015, wọn dana sun iboji naa, ko to o dipe ijọba pada tun kọ.
Abẹ iṣakoso Isreal ni ilu Nablus wa tẹlẹ, ko to o di pe wọn yọnda rẹ fun Palestine ni ọdun 1995.
Ọjọ ti pẹ ti ariyanjiyan ti n waye lori ọrọ iboji naa. Awọn ẹlẹsin Kristiẹni, Musulumi ati Juu lo ma n bọwọ fun ibẹ.
Awọn eeyan Juu kan gbagbọ pe Josẹfu inu bibeli ni wọn sin oku rẹ sinu iboji naa, ṣugbọn awọn Musulumi sọ pe Ṣeiki kan ni wọn sin sibẹ.
Oru nikan ni awọn Juu ni anfaani lati jọsin ni iboji naa, lẹẹkan ni oṣu.
Wọn si ma n sẹ eyi labẹ aabo to peye lati ọdọ awọn ọmọ ogun Israel.
Agbegbe Area A nilu West Bank ni iboji Josẹfu naa wa, botilẹ jẹ pe abẹ iṣakoso orilẹ-ede Palestine ni ilu naa wa.
Kini ijọba orilẹ-ede mejeeji sọ lori ikọlu yii?
Titi di asiko yii, ijọba orilẹ-ede Palestine ko ti i sọ ohunkohun.
Ṣugbọn minisita eto aabo ni Israel, Benny Gantz, sọ pe ikọlu naa tako ominira ti awọn eeyan ni lati ṣe ẹsin to ba wu wọn.













