Yemi Osinbajo: Èrò ọmọ Nàíjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ìkéde Osinbajo láti dupò ààrẹ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Professor yemi osinbajo / facebook
Lowurọ ọjọ Aje, ọjọ kọkanla ọdun 2022, ni igbakeji aarẹ Naijiria, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo kede erongba rẹ lati dije fun ipo aarẹ, fun gbogbo aye.
Eyi si ti fa ọpọlọpọ itakurọsọ lori ayelujara ati lagbo ijiroro ọrọ oṣelu gbogbo.
Kii ṣe ikede rẹ gan an lo n fa awuyewuye nitori ọpọlọpọ lo wulẹ ti n reti pe yoo ri bẹẹ.
- Kí ló dé tí ọkùnrin yìí fi dojúkọ Kìnìún ààyè?
- "Ẹ̀yin onítíátà, ẹ gbàdúrà fún Kemi Afolabi, Ọlọ́run nìkan ló mọ ibi tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò já sí"
- Oluwo ṣe àbẹ̀wò sí Aláàfin lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tó gbé ìyàwó tuntun
- Mo gbìyànjú láti ṣẹ́yún àkọ́bí mi saájú ìgbeyàwó - Iyabo Ojo
- Àwọn ọmọ Palestine kọlu ìbòjì Josẹfu ọmọ Jakọbu, wọ́n dásá sún
- Àgùnbánirọ̀ ya fọ́tò Bàbá Onílù láti tà á, òjò owó rọ̀ fún bàbá
- Bí Sunday Igboho bá sọ èròǹgbà rẹ̀ nípa Yoruba Nation, inú gbogbo ọmọ Yorùbá yóò dùn - Banji Akintoye
- Tí mo bá di ààrẹ, ìwúrí ni màá jẹ́ fọ́mọ Nàíjíríà - Tunde Bakare
- Ìtara láti du ẹ̀mí mi gbópọn si torí ìfẹ́ tẹ fi hàn mí - Kemi Afolabi
Amọṣa, ohun to n fa ariyanjiyan lori rẹ ko ju bi ọrọ naa yoo ṣe ja si laarin igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo pẹlu Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu to jẹ ọga rẹ tẹlẹ.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe ko yẹ ki erin fọn ki ọmọ rẹ naa tun fọn; lawọn miran n woye pe ko si bi ọbọ ṣe ṣe ori ti inaki ko ṣe o.
'N ṣe lo yẹ ki Tinubu gba adura pe ki Osinbajo ju oun lọ gẹgẹ bii baba si ọmọ - Igun Osinbajo sọrọ
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba, Amofin Kayọde Ajulọ to jẹ gbajumọ amofin, ajafẹtọ araalu to tun jẹ alabaṣepọ Igbakeji aarẹ Muhammadu Buhari ni igbesẹ ti ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria ti n reti ni igbesẹ ti Osinbajo gbe naa.
O ṣalaye pe idi ti igbesẹ ati kede erongba rẹ ṣe pẹ bayii ko to jade ko ju wi pe igbakeji aarẹ Naijiria naa nilo asiko lati forikori pẹlawọn eekan gbogbo kaakiri lati lee mọ ibi ti yoo gbe ọrọ gba.
Lori boya ọrọ naa ko ni fara jọ ẹsun ọdalẹ ti awọn eeyan kan fi n kan igbakeji aarẹ pẹlu bi o ṣe fẹ dije tako Tinubu, ti ọpọ woye gẹgẹ bii oloore rẹ ni.
Amofin Ajulọ ṣalaye pe, ni ilẹ Yoruba, gbogbo obi lo maa n gbadura ki ọmọ wọn ju awọn lọ.
O darukọ awọn eekan ilẹ Yoruba bii Baba Abraham Adesanya, Baba Daodu, Baba Ayọ Adebanjọ ati Mama Abibatu Mọgaji maa n gba fun Aṣiwaju nigba naa ni pe yoo ga ju wọn lọ , to si ri bẹẹ.
"Adura to yẹ ki aṣiwaju maa gba bayii fun Osinbajo bayii naa ni pe iwọ ọmọ mi o waa ga ju mi lọ."
Ọrọ yii dabi ọmọ to fẹ ba baba rẹ du iyawo ni - Igun Tinubu ero rẹ
Ninu ọrọ tirẹ, Abdulhakeen Adegoke, adari ẹgbẹ Yoruba Welfare Group ṣalaye fun BBC News yoruba pe ohun ti ko yẹ ko waye ni ikede erongba igbakeji aarẹ Osinbajo pe oun naa fẹ dije lẹyin ti ẹni ti a lee pe ni ọga ọga rẹ ti bọ si gbangba lati sọ pe oun fẹ dije fun ipo naa.
Abdulhakeen Adegoke ni osibajo ti ṣi ẹsẹ gbe lori igbesẹ naa nitori ko si bi igbesẹ rẹ ko ṣe ni di igbesẹ Yoruba lati di aarẹ lowo ati pe ni iwoye toun o, itanje lasan lawon eekan ni apap ariwa Naijiria n fun un ti wọn n sọ oe awọn wa lẹyin.
O wa rọ awọn agbagba Yoruba lati pe ajọ to nironu fun yiyanju ọrọ ọhun ki alaafia lee jọba laaarin awọn mejeeji.
To ba jẹ pe ṣaaju igba ti Aṣiwaju kede tirẹ ni Osinbajo ti kede ni, ọpọ gan ni yoo maa rọ aṣiwaju pe ko sinmi naa ki ọmọ rẹ, iyẹn Aṣiwaju Osinbajo lee dije.
"Ọrọ yii dabi ọmọ to fẹ ba baba to bii du iyawo. Ki awọn baba wa nilẹ Yoruba tete pe aro ati ọdọfin inu wa silẹ."

Nǹkan mẹ́wàá tí màá ṣe fọ́mọ Naijiria tí mo bá fi di ààrẹ - Osinbajo

Oríṣun àwòrán, yemi osinbajo/facebook
Owurọ ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun 2022, ni igbakeji aarẹ Naijiria, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo kede erongba rẹ lati dije fun ipo aarẹ, fun gbogbo aye.
Osinbajo ninu fidio kan to fi si oju opo Twitter rẹ lo ti kede igbesẹ naa.
Eyi waye lẹyin to ti kọkọ kede fun awọn gomina kan to wa ninu ẹgbẹ osẹlu All Progressives Congress, APC, lọjọ Aiku.
Nkan mẹwaa gboogi ti Osinbajo ni oun yoo ṣe to ba di aarẹ Naijiria
- A gbọdọ pari nkan ti a bẹrẹ ni ẹka eto aabo
- Ṣiṣe aṣepari iṣẹ atunṣe to n waye ni ẹka idajọ, pẹlu afojusun lati mu owo oṣu ati ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ ni ẹka naa, to fi mọ riri daju pe idajọ ododo fi ẹsẹ mu
- Mimu idagbasoke to yara ba awọn iṣẹ idagbasoke, paapaa ina mọnamọna, opopona, reluwe, ati ẹrọ ayelujara ayarabiaṣa.
- Pipese ayika to dara fun awọn olokoowo lati ṣe aṣejere
- Mimu idagbasoke eto iṣẹ agbẹ lọ si ipele to kan, paapaa ni ilana igbalode.
- Riri daju pe awọn ileeṣẹ ijọba n ṣe iṣẹ wọn fun isin awọn olokowo
- Sise idasilẹ eto ọrọ aje ni ẹka imọ ẹrọ, fun ipese iṣẹ fun ọpọlọpọ miliọnu eeyan
- Atunṣe si ẹka eto ẹkọ - lati ri daju pe tọkunrin-tobinrin lo lọ sile ẹkọ; mimu eto ẹkọ wa ba igba mu fun awọn ipenija asiko yii
- Pipari iṣẹ to n lọ lori eto ilera kariaye fun gbogbo eniyan
- O ni nkan ti yoo jẹ akọkọ ninu afojusun ijọba oun ni ipese iṣẹ ati ọpọ anfaani idagbasoke fun awọn ọdọ
- Pipari iṣẹ to n lọ lori yiyọ ọgọrun miliọnu ọmọ Naijiria kuro ninu ìṣẹ́ ati òṣì ti yoo ba fi di ọdun 2030

Yemi Osinbajo kéde láti díje fún ipò ààrẹ lọ́dún 2023
Igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo ti kede erongba rẹ lati dije fun ipo aarẹ Naijiria ninu eto idibo ọdun 2023.
Osinbajo ninu fidio kan to fi si oju opo Twitter rẹ ni owurọ ọjọ Aje lo ti sisọ loju eegun pe oun maa dije fun ipo aarẹ.
Osinbajo ni "Pẹlu irẹlẹ ọkan ni mo fi n kede erongba mi lati dije fun ipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oselu APC.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
A maa mu ẹkunrẹrẹ awọn koko ọrọ to sọ nipa erongba rẹ lati dije naa wa fun yin laipẹ.

Ṣé lóòtọ́ ni Yemi Osinbajo fẹ́ kojú Tinubu fún ipò ààrẹ Nàìjíríà?

Oríṣun àwòrán, yemi osinbajo/facebook
saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe lẹyin ọpọlọpọ akoko ijiroro ati ifikuluku, o dabi ẹni pe igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo ti ṣetan bayii lẹyin o rẹyin lati dije fun ipo aarẹ orilẹede Naijiria ldun 2023.
Kii ṣe iroyin abẹnu mọ pe oniruuru ẹgbẹ, ọgba ati igun lo ti bọ sigboro lati gbe lẹyin agba amofin naa pe ki oun pẹlu darapọ mọ awọn oloṣelu to fẹ dije fun aṣia ẹgbẹ oṣelu APC fun ipo aarẹ lorilẹede Naijiria.
Ni oṣu karun un ọdun 2022 ni eto idibo lati mọ ẹni ti ẹgbẹ oṣelu APC yoo fa kalẹ fun idije ipo aarẹ lasiko idibo apapọ ọdun 2023 yoo waye.
Gẹgẹ bi awọn iroyin kan to jade lati ile aarẹ, Aso Rock Villa nilu Abuja lọjọ Aiku ṣe sọ, igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria naa ti bun awọn gomina bii mejila kan gbọ nipa erongba rẹ lati dije.
Iroyin naa sọ pe, Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo fi to awọn gomina naa ninu eyi ti Nasir El-Rufai (Kaduna), Dapo Abiodun (Ogun), Abdullahi Sule (Nasarawa), Babagana Zulum (Borno) ati Babajide Sanwo-Olu (Eko) leti lasiko apejẹ iṣinu awẹ Ramadan, Iftar to pe nibi to ti jẹ ko di mimọ fawọn gomina naa nipa erongba rẹ lati tẹsiwaju pẹlu iṣẹ ti ọga rẹ, Aarẹ Muhammadu Buhari ba ṣe ku lasiko ti saa iṣejọba rẹ ba pari ldun 2023.
Awọn oloṣelu wo lo ti fi erongba ati dije ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023 han?

Oríṣun àwòrán, yemi osinbajo
Bola Ahmed Tinubu:
Bọla Tinubu jẹ ọkan lara awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC, ohun si ni gomina ipinlẹ Eko laarin ọdun 199 si 2007.
Rochas Okorocha:
Okorocha ni gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ, igba akọkọ rẹ si kọ niyi lati dije, lẹyin to ti kọkọ gbe igba ibo fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu AA nigba kan ri.
Rochas Okorocha fi erongba rẹ lati dije han ninu lẹta kan to kọ ranṣẹ si aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnetọ Ahmad Lawan lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kini ọdun 2022.
Khadija Okunnu -Lamidi:
Oun ni obinrin akọkọ to jade lati kede pe oun fẹ dije fun ipo aarẹ lọdun 2023. Ko tii kede ẹgbẹ oṣelu kankan ti o wa bayii na. Ohun to sọ ni pe ẹgbẹ oṣelu to ba ni iran kan naa pẹlu oun loun yoo ba lọ.

Oríṣun àwòrán, twitter/Omotoyosi Adeolu Adetayo
Dele Momodu:
loṣu kẹta ọdun 2023 ni Dele Mọmọdu kede pe oun naa yoo dije ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP.
Igba akọkọ kọ niyi ti Dele Mọmọdu yoo maa fifẹhan si didije fun ipo aarẹ ni Naijiria.
Yahaya Bello:
Yahaya Bello ni gomina ipinlẹ Kogi lọwọ yii. Laipẹ yii loun pẹlu kede pe oun naa nifẹ si ipo aarẹ lọdun 2023.
Awọn miran to tun ti gbe igbesẹ yii kan naa ni aarẹ ile aṣofin agba tẹlẹ ri, Dokita Bukọla Saraki, alaga igbimọ awọn gomina lorilẹede Naijiria, NGF to tun jẹ gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, minisita fọrọ oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ, Dokita Chris Ngige ati bẹẹ lọ.



















