Pro-Oduduwa, Biafra, Ambazonia Rally: Ilana Omo Oodua ní òun kò ní kópa nínú ìwọ́de náà

Awọn eeyan to gbe asia ẹgbẹ IPOB ati Yoruba Nation lọwọ to n se iwọde

Ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua ti ṣalaye pe oun ko mọ nipa iwọde ti awọn ẹgbẹ ajijagbara IPOB n ṣeto fun oṣu kẹfa ọdun 2022.

Alukoro ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua lagbaye, Maxwell Adelẹyẹ ṣalaye fun BBC News Yoruba pe, ẹgbẹ ajijagbara to n pe fun ominira ẹya Yoruba naa ko mọ nipa iwọde naa.

Maxwellfikun pe ẹgbẹ Ilana Omo Oodua ko le da kopa ninu iwọde naa, ti wọn ni yoo waye lolu ileeṣẹ ajọ orilẹede ilẹ Yuroopu lorilẹede Belgium.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹede Biafra, IpoB kede laipẹ yii pe awọn n gbaradi fun iwọde onimiliọnu kan eeyan, lati ja fun ominra awọn ẹya gbogbo ni Naijiria.

Alukoro ẹgbẹ IpoB, Emma Powerful ṣalaye ninu atẹjade kan lọjọ Iṣẹgun pe IpoB ati awọn ẹgbẹ ajijagbara ilẹ Ooduwa ati Ambazonia lo n ṣe eto iwọde naa.

Àkọlé fídíò, Oluyemisi Orisabiyi: Ẹ̀ẹ̀mẹta péré làwọn òṣìṣẹ́ KAI bẹ̀ mí wò, mo kọ̀wé sí wọn lái rí èsì

Amọ, Ilana Ọmọ Oodua ni oun ko gbọ si irufẹ iwọde bẹẹ to ba tilẹ maa waye lootọ.

Ọgbẹni Maxwell Adelẹyẹ ko ṣai tu yan an pe eyi ko tumọ si pe ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua tako ẹgbnẹgbogbo to lọwọ ninu iwọde yii o, ṣugbọn ohun to ṣẹlẹ ni pe awọn ko mọ si iwọde ti wọn n gbaradi fun lọwọ.

Alukoro IpoB, Emma Powerful ṣalaye pe eredi iwọde ti awọn fẹ ṣe naa ni lati ko awọn ẹya to n pe fun ominira ẹya wọn jọ lati sọ ilakaka ati ipenija wọn fun gbogbo agbaye lọna.

Ẹgbẹ naa ni awọn alaṣẹ ajọ ilẹ Yuroopu ti buwọlu iwọde naa.

Amin iyasọtọ kan

IPOB àti Yoruba Nation ń gbèrò ìwọ́de alágbára:

Awọn eeyan to gbe asia ẹgbẹ IPOB ati Yoruba Nation lọwọ

Bẹẹ ba gbagbe, ikọ ajijagbara ilẹ Igbo táa mọ si Indigenous People of Biafra, IPOB sọ pé àwọn n palẹmọ ìwọ́de eeyan miliọnu kan ni olú ileesẹ àjọ Yúrópù to wa ni Brussels.

Wọn ni awọn nikan kọ ní yóò se iwọde yi bi kìí se pé àwọn akẹgbẹ wọn tó n beere idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa ati awon ti Ambazonia naa ni Cameroon yoo darapọ mọ wọn.

IPOB ni eyi yoo waye lẹyìn igbesẹ tàwọn jijọ n gbe lori gbigba ominira wọn gẹgẹ bí orile-ede ti yóò dá wa lọtọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Alukoro IPOB, Emma Powerful,lo fiidi ọrọ yi múlẹ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Ìṣẹgun.

Powerful salaye pe iwode yii wa lati kéde ipenija tàwọn orileede to n gbe ori bọ yi n koju kí aráyé baa le mọ.

IPOB ni awon adari àjọ EU ti buwọ́lù iwọde tàwọn mẹtẹta yi fẹ ṣe ni Brussels.

Ni itẹsiwaju,Powerful ni "ipaniyan ati ile jijo to n waye láwọn orileede mẹta go n gb'ori bọ yi kọja afẹnusọ.Awọn to n padanu ẹmi wọn lọwọ ijoba Naijiria ati Cameroon lojojumọ ko kere"

Atẹjade yi sọ pé ọjọ kẹrinla ati ikẹẹdogun oṣù Kẹfà ni àwọn yoo peju pesẹ lati jẹ ki gbogbo ayé mọ pé awọn to lati da dúró fún ara wọn gẹgẹ bi orileede.

Àkọlé fídíò, Abisola Odebode: Ẹ wo àkàndá ẹ̀dá tó ń kọ́ àwọn àgùnbánirọ̀ l‘Osun ní ọ̀dà ṣíṣe lọ́fẹ̀ẹ́

Igba àkọkọ ree ti Ambazonia yoo kun IPOB. ati awọn Oduduwa Nation

Awọn ajijagbara IPOB ati ti ilẹ Yoruba ko ṣẹṣẹ maa daba iwọde elero púpọ bayi ni ilẹ okere.

Ohun tí o kan yatọ ni pe wọn yoo kọwọrin pẹlu awọn ti orileede miran ni iwọ oorun Africa.

Ṣaaju asiko yi ni ọdun 2021 lasiko ìpàdé àpapọ àjọ isokan agbaye (UN General Assembly) awọn agbarijọpọ ajijagbara lati Naijiria kora jọ láti se iwode fún ọjọ meloo kan.

Iwode oni miliọnu kan ni wọn pe eleyii naa ṣugbọn iye eeyan to kopa ko sunmọ iye yi.

Bi ti eleyi ti wọn n mura nisinyi ,nise ni wọn ṣe ipolongo ti wọn sì n korin lagbegbe ọfisi UN ki wọn bàa lè mọ ero ọkan wọn.

Abajade iwọde eyi ti wọn ṣe ṣaaju ko foju hàn nítorí titi di asiko yi, wọn ko ribi seto idibo ṣọ ohun ti mo fẹ taa mọ sí Referendum yala ni ilẹ Igbo ni tabi ni ilẹ Yoruba ati awọn ipinlẹ mii tàwọn ajijagbara ti darapọ mọ wọn.

Awon to jẹ olori ìkọ IPOB ati ti Oduduwa Nation sí ni iṣẹ tó pọ níwájú wọn paapa ti wọn ba fẹ gba ominira lọwọ orile-ede ti wọn wa bayi.

Meji ninu awọn aṣaju ajijagbara yi,Sunday Adeyemo Igboho ati Nnamdi Kanu ṣi wa n ahamọ.

Awọn olori ìkọ to n pe fún ìdásílẹ̀ Oduduwa Nation ko ti fesi boya awọn yóò darapọ mọ IPOB nibi iwọde yi.

Amin iyasọtọ kan

Bí Sunday Igboho bá sọ èròǹgbà rẹ̀ nípa Yoruba Nation, inú gbogbo ọmọ Yorùbá yóò dùn - Banji Akintoye

Sunday Igboho:

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe Ọjọgbọn Banji Akintoye to jẹ adari ikọ to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, ''Yoruba Nation'' ti salaye bi awọn ṣe gba itusilẹ Sunday Igboho ni ẹwọn to wa ni orilẹede Benin Republic.

Banji Akintoye sọ eyi lasiko to n ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu akọroyin lori awọn igbeṣẹ ti wọn tẹle lati gba Igboho kuro ni ẹwọn fun igba diẹ.

Baba Banji ninu idahun rẹ ni ko si ohun to jọ wi pe Sunday Igboho gba itusilẹ fun igba diẹ.

O ni Igboho ti gba itusilẹ patapata, ahesọ nikan ni awọn ijọba Naijiria n gbe kaakiri.

''Ohun to ṣẹlẹ ni pe Sunday Igboho ko fẹ ki ẹnikẹni mọ ero ọkan rẹ lo ṣe dakẹ fun igba diẹ, awọn ti ko fẹ ko jade kuro ni ẹwọn lo n gbe iroyin ẹlẹjẹ pe wọn ko jọwọ rẹ ni kiakia.''

''Otitọ ibẹ ni pe wọn ti fi Sunday Igboho silẹ nitori eniyan jankanjankan ni, ti o ba si safihan ero to ni fun awọn Yoruba laipẹ yii, inu gbogbo awọn ọmọ kaarọ ojiire ni yoo dun patapata.''

Àkọlé fídíò, Restructuring: Àgbékalẹ̀ orílẹ̀èdè Nàìjíríà lọ́wọ́ yìí kò lè fàyè

Bi a ṣe gba itusilẹ Igboho re e...

Ọjọgbọn Banji Akintoye ti ni kii ṣe ohun to dẹrun ni lati gba itusilẹ Sunday Igboho amọ ọpẹlọpẹ gbogbo awọn to sun mọ ọ.

''Emi ati ọjọgbọn Wale Adeniran to jẹ igbakeji mi pẹlu ikọ awọn oluranlọwọ wa lo jẹ ko ṣeeṣe, paapaa Adeniran to gbọ ede Faranse ṣe iranwọ fun wa lọpọlọpọ.''

''Lẹyin iṣẹju diẹ ti wọn fi panpẹ ọba mu Sunday Igboho ni papakọ ofurufu ni Cotonou la gbọ iroyin naa, ti a si bẹrẹ iṣẹ lẹṣẹkẹsẹ.''

''Bi o tilẹ jẹ pe alẹ ni iṣẹlẹ naa waye, a ri agbejọro to dantọ to si ṣiṣẹ takuntakun ni oru ọjọ naa mọju laisun.''

''Ohun ti a gbọ ni pe wọn fẹ gbe Igboho pada wa si Naijiria ni alẹ ọjọ naa, ti a si sa gbogbo ipa wa lati ri pe ko ri bẹẹ.''

''Lẹyin naa ni a bẹrẹ ọrọ ile ẹjọ, ti a ko si jẹ ki awọn ọmọ Yoruba to wa ni ibode Naijiria ati Cotonou yabo ileẹjọ naa.''

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Kò sí ìdí tí à ó fi bínú sí Akeredolu lórí ọ̀rọ̀ Yorùbá Nation

Mo da majẹmu pe n ko ni pada si Naijiria titi ti Igboho yoo fi gba idande:

Baba Akintoye fikun un pe, Osu Kọkanla ọdun naa ni awọn bẹrẹ ijiroro pẹlu awọn lọbalọba, to fi mọ awọn eniyan jankan ni ijọba orilẹede Benin Republic.

''Amọ mi o gbọdọ gbagbe akẹkọọ ọjọgbọn Adeniran to ṣiṣẹ takuntakun ni Cotonou lati ran wa lọwọ lati igba de igba.''

Akintoye ni bi o tilẹ jẹ pe oun ati ọjọgbọn Adeniran rin si asiko ti ijọba Naijiria fi panpẹ ọba mu Sunday Igboho, oun da majẹmu pe oun ko ni kuro ni ilu Benin ayafi ti wọn ba fi Sunday Igboho silẹ.

''Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe opin ti de si asiko naa bayii ati gbogbo awọn ọmọ ilẹ Yoruba ni ile ni oko to duro ti Sunday lai wẹyin pẹlu adura pe ko jade ni ayọ ati alaafia.

Bakan naa ni wọn dupẹ lọwọ gbogbo awọn ọmọ ilẹ Benin Republic to ṣe atilẹyin fun wọn, to fi mọ aarẹ orilẹede naa, Patrice Talon.

Àkọlé fídíò, Fìdíhẹẹ́ ní Banji Akintoye nínú YWC, lílọ ni yóò lọ - Tola Adeniyi