Fake Army General: Ayédèrú ọ̀gágun lú jìbìtì N266.5m

Oríṣun àwòrán, EFCC
Ile ẹjọ kan ni Ikẹja, nilu Eko ti paṣẹ ki wọn fi ayederu ọgagun kan ti orukọ rẹ n jẹ Bọlarinwa Abiọdun si ahamọ lori ẹsun lilu jibiti ọtalenigba o le mẹfa milọnu naira. (N266.5 million)
Adajọ Oluwatoyin Taiwo paṣẹ ki wọn fi si ahamọ lọgba ẹwọn to wa ni Ikoyi lẹyin ti ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria, EFCC fi ẹsun mẹtala to da lori jibiti kan an.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló dé tí ẹnu ń kun ìgbeyàwó Funke Akindele pé ó ti dàrú? Àbọ̀ ìwádìí wa rèé
- "Àwọn ọmọ ogun Russia fipá bá mi lòpọ̀, wọ́n tún pa ọkọ mi"
- Rògbòdìyàn ṣẹlẹ̀ n‘Ibadan, ọwọ́ tẹ jàǹdùkú nílé Olopoeyan pẹ̀lú káàdì ìdámọ̀ ẹgbẹ́ Auxillary
- Ìjà ńlá bẹ́ sílẹ̀ l‘Eko láàrin igun MC Oluomo àti ẹgbẹ́ awakọ̀ márúwá TOOAN
- Ẹ̀yin obìnrin, ẹ tètè jápa tí ìgbéyàwó yín bá ti la ìgbájú-ìgbámú lọ - Olori Silekunola
- Ìdí tí Tinubu fi ṣèpàdé pẹ̀láwọn gómìnà APC lẹ́yìn tí Osinbajo kéde lati dupò ààrẹ
- Àwọn ọlọ́pàá ti fi páńpẹ́ òfin gbé ọkọ olórin ẹ̀mí “Ekwueme” fẹ́sùn lílu ìyàwó rẹ̀ dójú ikú
- Kí ló dé tí ọkùnrin yìí fi dojúkọ Kìnìún ààyè?
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Àwọn agbébọn pa ènìyàn 135 lọ́jọ́ kan ṣoṣo
- Oko kìí jẹ́ ti baba tọmọ kó mà ní ààlà; Mi ò ní ọmọ tó dàgbà tó le jáde láti dupò Ààrẹ- Tinubu
Alukoro fun ajọ EFCC, Wilson Uwujaren ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita pe ẹsun fifi ọna eru gbowo, yiyi iwe ati nini awọn ayederu iwe nikawọ kun ara ẹsun ti wọn fi kan an.
Ajọ EFCC ni ileeṣẹ kan ti orukọ rẹ n jẹ Kodef Clearing Resources lo mu ẹjọ rẹ tọ ajọ naa wa pe o lu awọn ni jibiti ọtalenigba o le mẹfa milọnu naira, (N266.5 million).
Bawo ni ọgbẹni to pe ara rẹ ni ọgagun agba naa ṣe lu jibiti ọhun?
Ajọ EFCC ni afurasi onijibiti naa, ti orukọ n jẹ̀ Bọlarinwa parọ fun awọn eeyan naa pe ọgagun agba loun jẹ nileeṣẹ ọmọogun oju omi lorilẹede Naijiria.
Bakan naa lo ni aarẹ Naijiria, Muhammadu Buhari ti mu orukọ oun ati eeyan kan silẹ gẹgẹ bi ẹni ti yoo yan si ipo ọgagun agba ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ ni Naijiria.
O wa ku si awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa lati ran oun lọwọ pẹlu "owo ti oun yoo lo fi ṣiṣẹ lori bi ipo naa yoo ṣe tẹ oun lọwọ."
Oṣu kini ọdun 2022 ni ọwọ awọn agbofinro tẹ arakunrin naa ni ile rẹ to wa lagbegbe Magodo nilu Eko.
Ọgbẹni Abiọdun tun fun awọn alaṣẹ ileeẹ naa ni ayederu kaadi idanimọ ileeṣẹ ọmọ ogun oriilẹ Naijiria kan, ti nọmba rẹ jẹ 387140.

Oríṣun àwòrán, other
Bakan naa ni wọn tun ni o tẹ ayederu iwe ifinihan kan 'Letter of Recommendation" kan eyi to fihan pe aarẹ ana, oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ buwọlu lati fi eeyan kan ti orukọ rẹ n jẹ Adebayọ Rasaq Adebọla pẹlu nọmba igbaniwọle sisẹ ologun No 77RRI/OG/556/0032555 ati Adeogun Emmanuel Adeṣọla ti nọmba igbaniwọle tirẹ jẹ No 77RRI/OG/352/0123751.
Bakan naa lo tun ṣe ayederu iwe ifọwọsi kan to ni pe olu ileeṣẹ ọlọpaa fun oun
Awọn lẹta wọnyi lo lo lati fi wọ ibudokọ ojuomi to wa ni Apapa
EFCC ni awọn tun ri ibọn mẹfa ọta ibn mẹta, ọpa itilẹ ologun ati omilẹgbẹa awọn ayederu iwe gbogbo.


















