Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ Mínísítà lẹ́yìn ẹ̀sùn ìfipá bá ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún lò pọ̀

Oríṣun àwòrán, Namibian presidency/Facebook
Minisita to n ri si ọrọ iṣẹ ọgbin lorilẹede Namibia, Mac-Albert Hengari, ni wọn ti gba iṣẹ naa lọwọ rẹ bayii, latari ẹsun ifipa ba ọmọde lo pọ ti wọn fi kan an.
Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe wi, ọdun marun-un sẹyin ni iṣẹlẹ ifipabanilopọ naa waye.
Wọn ni ọmọ ọdun mẹrindinlogun (16) ni Mac-Albert Hengari, fipa ba lo nigba naa.
Satide to kọja yii ni wọn tun mu un, lẹyin ti wọn lo n fi owo ẹyin bẹ ọmọ to ti pe ọdun mọkanlelogun bayii, lati gbe ẹjọ naa kuro lọdọ awọn agbofinro.
Hengari, ẹni ọdun mọkandinlọgọta (59), loun ko jẹbi ẹsun naa nigba to foju han ni kootu lọjọ Aje.
Kootu ko faaye beeli silẹ fun un.
Ẹ o ranti pe laipẹ yii ni obinrin gba ipo aarẹ lorilẹede Namibia, iyẹn Netumbo Nandi-Ndaitwah.
Ẹsun ti minisita yii n jẹjọ rẹ ni awuyewuye to tobi julọ latigba ti iya naa ti depo yii loṣu to kọja.
Atẹjade to ti ọfiisi Aarẹ wa, ko sọ pato idi ti wọn fi gba iṣẹ lọwọ Hengari, ṣugbọn wọn ti le ọkunrin naa kuro nile igbimọ aṣofin pẹlu.
Yatọ si ẹsun ifipabanilopọ, awọn ẹsun mi-in ti wọn tun ka si Hengari lẹsẹ ni ijinigbe ati ṣiṣe eeyan niṣekuṣe, gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe sọ.
Minisita tẹlẹ naa yoo wa lahaamọ titi di ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, bi kootu ṣe paṣẹ.














