'Ọjọ́ mẹ́rin ni ọkọ mi fi sá kúrò nílé lẹ́yìn tó gbọ́ pé ìbẹta ni mo bí'
Ohun ayọ lọmọ jẹ fun gbogbo abiyamọ, ohun ayọ yii naa ni lọkọlaya Jẹjẹ ni ilu Okitipupa ni ipinlẹ Ondo n reti nigba ti wọn rii pe arabinrin Iyanu Jẹjẹ to jẹ iyawo ti fẹraku.
Amọṣa nigba to di ọjọ ikunlẹ ti arabinrin Iyanu Jẹjẹ bi ọmọ ti wọn si rii pe ibẹrin ni ọrọ ti yi pada fun idile yii.
Ni kete ti ọkọ arabinrin yii, Arakunrin Jẹjẹ gbọ pe iyawo rẹ ti sọkalẹ anfani inu rẹ dun o si fijo fun ori rẹ. Amọṣa ni kete ti wọn fi too leti pe ọmọ mẹrin ni iyawo rẹ bi lẹẹkanṣoṣo lo ti di awati, to na papa bora.
"Nigba ti mo bimọ ti ọkọ ri pe ọmọ mẹta ni mo bi, ọkọ ti salọ. Mo pe e titi ko gbe aago mi."
Arabinrin Jẹjẹ sọ pe lootọ ni aworan inu oyun ti oun ṣe lawọn ile iwosan ti oun lọ lasiko iloyun oun ti fihan pe ọmọ mẹtan lo wa ninu oun.
O ni lẹyin ọjọ kẹrin ti oun bimọ lọkọ oun to pada dari wa sile. O ni nigba ti oun bii pe ki lo ṣẹlẹ, Arabinrin Iyanu Jẹjẹ sọ wi pe, alaye ti ọkọ oun ri ṣe fun oun ni pe, "ẹru lo ba oun, ati wi pe oun lọ wa owo ni".






