Òṣìṣẹ́ Access Bank tó ya fídíò ìhòhò obìnrin 400 níbi iṣẹ yóò fojú ba ilé-ẹjọ́

Aworan obinrin to karibọnu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti ni oun yoo gbe ọkunrin kan to jẹ oṣiṣẹ ileefowopamọ Access tẹlẹ, fun ẹsun yiya fidio ihoho irinwo eeyan, lai gba aṣẹ lọwọ wọn.

Eyi n waye lẹyin ti ileefowopamọ naa fi atẹjade sita lọjọ Aje pe, awọn ti fa ẹsun to ni i ṣe pẹlu fidio ihoho naa le ẹka to yẹ lọwọ.

Ninu atẹjade naa Access Bank ti sọ pe, awọn n ṣiṣẹ pẹlu awọn ẹka to yẹ, lati jẹ ki awọn oṣiṣẹ ati onibaara mọ pe ko si iṣoro fun aabo ati ihoho wọn.

Opin ọsẹ to kọja ni iroyin jade pe, oṣiṣẹ banki naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Stephen Ejezie, ya fidio ihoho awọn oṣiṣẹ obinrin ni ọkan lara awọn ẹka banki ọhun nipinlẹ Eko, ti iye wọn to irinwo.

Inu baluwẹ ti awọn obinrin naa n lo ni wọn lo ti n ya wọn lai jẹ ki wọn mọ, titi to fi wọ irinwo obinrin.

Iroyin sọ pe wọn ti kọkọ mu afurasi naa , ṣugbọn wọn pada fi i silẹ, o si n yan fanda pẹlu fidio ihoho awọn obinrin olobinrin to ni lọwọ.

Alukoro ọlọpaa Eko, Benjamin Hundeyin, sọ fun BBC pe, awọn fi aaye beeli silẹ fun afurasi naa tẹlẹ lati pari iwadii awọn ni.

"Lonii ti mo n ba yin sọrọ yii, afurasi naa ti wa lọdọ ọ wa.

''A n gbe e lọ si kootu bayii fun igbẹjọ"

Hundeyin lo sọ bẹẹ fun BBC laaarọ ọjọ Aje.

Báwo ni wọ́n ṣe rí i mú?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin FIJ ṣe sọ, bti wọn oṣiṣẹ banki naa to wa lẹka to n gba ipe awọn onibaara lori ipenija wọn, ba ti wa lẹnu iṣẹ, wọn maa n ṣiṣẹ di ọjọ keji nigba mii ti wọn yoo sun si ileefowopamọ naa.

Awọn wọnyi ni wọn maa n wẹ ni baluwẹ ti ileeṣẹ pese, nigba ti ilẹ ọjọ keji ba mọ. Wọn yoo si tun mura nibẹ.

Iroyin sọ pe afurasi yii maa n fi foonu to ti tan kamẹra rẹ silẹ, sinu ileewe naa, nibẹ lo si ti maa n ya fidio awọn oṣiṣẹ bii tiẹ ti wọn jẹ obinrin.

Lọjọ ti wọn ri i mu, ọkan ninu awọn ileewẹ naa to tun sa si ni wọn ti mu un.

"Nigba ti obinrin kan n wẹ lọwọ ni wọn mu un.

"Obinrin naa ri i pe foonu kan wa loke ileewẹ to n ya gbogbo bi oun ṣe n wẹ.

"Inu ile igbọnsẹ to wa lẹgbẹẹ ileewẹ ni foonu to n ya a naa si wa. Oun gan-an ko mọ, o kan ri apẹẹrẹ naa lojiji ni."

Bẹẹ ni iroyin wi.

Obinrin naa pariwo ohun to ri, awọn eeyan si rọ wa sibẹ lati mu afurasi yii.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn pada lọ wo ile afurasi ọhun ati foonu rẹ, nibẹ ni wọn si ti ri iru fidio ihoho bẹẹ to to irinwo.

Iroyin ti BBC ko ti i le fidirẹ mulẹ sọ pe, afurasi naa ma n ta awọn fidio naa lori ayelujara ni.

Wọn lo ni awọn onibaara ori ayelujara ti wọn jọ n ṣowo ọhun.

Ni bayii, a gbọ pe banki naa ti ṣofin pe ẹnikẹni ko gbọdọ sun nibẹ mọju mọ, ki kaluku gba ile rẹ lọ bi wọn ba pari iṣẹ.

AFIKUN ṢI N BA IROYIN YII. A O MAA MU UN WA BO BA ṢE N LỌ