Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ara mee riri mo rori ologbo latẹ

Ki lo ri o?

Oṣiṣẹ banki kan ti wọn ni o ṣe fidio awọn akẹgbẹ rẹ obinrin nile igbonṣẹ wọn ma ti dero ahamọ ọlọpaa

Irọ o, ki lo loun ri lọbẹ to fi waru ọwọ?

Alaye wa lori ikanni BBC Yoruba

''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''

Iroyin ayọ

Bun mi gbọ o, ṣo o jẹ tẹtẹ ni

Rara o, Ileeṣẹ adojutofo awọn banki ni Naijiria NDIC lo kede pe

awọn ti bẹrẹ sisan lara owo awọn eeyan ti owo wọn ṣi ha si Heritage Bank to kogba wọle

Ba wo lemi naa ṣe le rowo mi to ha sibẹ gba?

Kan soju opo BBC.Com/Yoruba

''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''

B'onirese o ba fingba mọ, eyi to ti fin silẹ ko le parun

Bẹẹ ni o, akọrin takasufee Mohbad to doloogbe

Wa lara awọn olorin to gbami ẹyẹ Headies nibi ayẹyẹ to waye lana ọjọ Aiku niluu Eko

Iyawo rẹ Wunmi ati ọmọkunrin wọn Liam lo gbami ẹyẹ naa lorukọ oloogbe