Lẹ́yìn ìsìnkú Póòpù Francis, Ìjọ Kátólíìkì kéde ọjọ́ tí wọn yóò yàn póòpù tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ipade idakọnkọ naa yoo bẹrẹ ninu ile ijọsin Sistine Chapel ni ọjọ keje oṣu karun un. Awọn alufa agba marundinlogoje lati tibu toro agbaye ni yoo kopa nibi ipade naa.
Eyi n waye lẹyin iku Popu Francis, lẹni ọdun mejidinlaadọrun. Ọjọ ọdun Easter ni Popu Francis ku ti wọn si ti ṣeto isinku rẹ ni ọjọ Abamẹta to kọja.
Ko si gbendeke iye akoko ti wn gbọdọ lo lati yan popu tuntun ṣugbọn bi eeyan ba wo bi irufẹ eto yii ti ṣe lọ lasiko yiyan awọn poopu meji sẹyin laarin ọdun 2005 si 2013, ọjọ meji pere ni wọn lo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Alukoro fun ijọ katoliki, Matteo Bruni ni awọn alufaa naa yoo kopa nibi eto isin idakẹjẹjẹ kan ni ijọ St Peter's Basilica, lẹyin naa lawọn to ba lẹtọ lati dibo yoo ko ara jọ si ijọ Sistine Chapel fun idibo naa.
Ni kete ti wọn ba ti wọ inu ile ijọsin Sistine Chapel, awọn alufa naa ko gbọdọ ba ẹnikẹni sọrọ titi di igba ti wọn yoo yan popu tuntun.
Ọsan ọjọ akọkọ tiwọn ba wọ inu ipade idakọnkọ naa ni wọn yoo di ipele akọkọ idibo naa. Amọ, yoo to igba mẹrin ọtọọtọ ti wọn yoo maa dibo lojoojumọ lẹyin eyi.
Ẹni ti yoo di olori tuntun fun ijọ Aguda yoo ni lati ko ida meji ninu mẹta idibo ki o to le wọle- eleyii yoo gba akoko diẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kaadi pelebe kọọkan ti wọn kọ ọrọ kan lede Latin si to sọ pe: "Mo dibo fun pontiff" ti wọn yoo kọ orukọ oludije ti wọn fẹ si, ni wọn yoo fi dibo.
Bi wọn ko ba ri ọrọ naa yanju lẹyin ọjọ kẹta, awọn alufaa agba naa le simi diẹ fun ọjọ kan lati gba adura.
Ni ita, awọn eeyan yoo duro si gbagede ayika ile ijọsin Sistine Chapel lati maa reti eefin ti wọn yoo fi kede yiyan Popu tuntun.
Bi eefin to baru jade nibẹ ba jẹ dudu, a jẹ wipe wọn yoo tun tẹsiwaju pẹlu ipele idibo miran. Amọṣa bi eefin to bar u jade nibẹ ba jẹ funfun, a jẹ wi pe wọn ti yan olori ijọ Katoliki tuntun naan iyi.















