Francis, ẹ̀ṣọ́ aláàbò nílé ijó tó di Póòpù tó mú àyípadà ńlá bá ìjọ Kátólíìkì

Pope Francis

Oríṣun àwòrán, EPA

    • Author, Busayo James-Olufade & Olumide Owaduge
    • Role, BBC News Yoruba
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Iyansipo Pope Francis, bẹrẹ oriṣiriṣi nnkan ti ko ṣẹlẹ ri.

Bo tilẹ jẹ pe titi de opin lo n mu awọn atunto ba ijọ Katoliiki, ṣibẹ ifẹ rẹ lọkan awọn ti ko faramọ awọn atunto naa, ko dinku.

Oun ni Poopu akọkọ to wa lati ilẹ America tabi Hemisphere. Lati ọdun 741 ti Gregory III lati syria, ti ku, ẹnikẹni ti kii ṣe ọmọ ilẹ yuroopu ko jẹ Poopu.

Bakan naa, oun naa tun ni Jesuit (ẹya awọn onigbagbọ kan ninu ijọ Katoliiki) ti wọn yan si ori itẹ Peteru Mimọ – Lati ayebaye ni Roomu ko ti fi inu ta awọn Jesuit.

Poopu to ṣaaju Francis, Benedict XVI, ni Poopu akọkọ to finu-findọ kọwe fi ipo silẹ lati bi ẹgbẹta ọdun, eyi to mu ki ijọ naa yan Poopu nigba meji laarin ọdun mẹwaa.

Gẹgẹ bi Cardinal Bergoglio ti Argentina, o ti le ni ẹni aadọrin ọdun nigba to de ipo Poopu lọdun 2013.

Ọpọ ọmọ ijọ Katoliiki lo ti kọkọ lero pe, ọdọ ni ẹni ti yoo jẹ Poopu tuntun.

Bergoglio fi ara rẹ han gẹgẹ bi ẹni to n ṣe oju meji – o n fa oju awọn onigbagbọ atijọ mọra pẹlu iha to kọ si ọrọ ibalopọ, nigba to n fa oju awọn onigbagbọ ode-oni mọra nipa iha to kọ si ọrọ idajọ lawujọ.

Ireti ọpọ ni pe bi ko ṣe wa lati ilana igbagbọ atijọ, yoo mu irapada ba igbimọ oludari ijọ naa, ti yoo si tun sọ iṣẹ ihinrere ji.

Ṣugbọn laarin awọn alaṣẹ ijọ, diẹ lara igbesẹ ayipada ti Francis gbe lo ba atako pade, ti ẹni to fi ipo naa silẹ fun un, si jẹ aayo laarin awọn onigbagbọ ilana igbaani titi to fi ku lọdun 2022.

Pope Francis

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O pinnu lati yatọ

Lati igba ti wọn ti dibo yan an, Francis fihan pe oun yoo ṣe awọn nnkan lọna to yatọ. Ọna ọtọ lo fi gbalejo awọn to wa nipo Cardinal, niṣe lo dide duro lati ki wọn, dipo ko jokoo lori itẹ Papa Mimọ.

Lọjọ kẹtala, oṣu Kẹta, dun 2013, Pope Francis yọju si gbagede ile rẹ to kọju si gbagede St. Peter's Square.

Pẹlu aṣọ funfun to wọ, o jẹ orukọ miran, eyii to bu iyi fun St Francis ti Assisi to jẹ oniwaasu ati ẹni to fẹran ẹranko.

O jẹ ẹnikan to gbe iwa irẹlẹ leke ju iyi ati ọla lọ.

Bẹẹ ni o tun yan lati maa lo ọkọ akero bọọsi pẹlu awọn alufaa ẹgbẹ rẹ dipo ọkọ ayọkẹlẹ limounsine ti wọn gbe fun un.

Pope Francis and Pope emeritus Benedict XVI

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ilu Buenos Aires, lorilẹede Argentina ni wọn ti bi Jorge Mario Bergoglio lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kejila, ọdun 1936 gẹgẹ bii akọbi ninu ọmọ marun un ti awọn obi rẹ bi.

O jẹ ẹni to fẹran ijo tango nigba ewe rẹ, o si jẹ ololufẹ ikọ agbabọolu San Lorenzo.

Gẹgẹ bii ọmọde, o ṣaisan Pneumonia, eyii to mu ki wọn ṣiṣe abẹ fun un lati yọ diẹ lara ẹdọforo rẹ, ori lo ko o yọ ti ko gba ibẹ lọ.

Ni bayii to ti di agbalagba, orokun rẹ ọtun n dun un, eyii to juwe gẹgẹ bii ohun to n ti oun loju.

Jorge Mario Bergoglio

Oríṣun àwòrán, Ẹbi rẹ ni Elvis

Àkọlé àwòrán, Jorge Mario Bergoglio gẹgẹ bii ọmọ ile ẹkọ niluu Buenos Aires ni 1940s

Bergoglio gẹgẹ bii ọdọ ṣiṣẹ ẹṣọ abo nile ijo, o si fi akoko igba kan gba ilẹ ko to kẹkọọ jade ninu imọ Chemistry.

Nileeṣẹ kan lagbegbe wọn, o ṣiṣẹ pẹlu Esther Ballestrino to n tako ijọba Baṣorun Gaa orilẹede Argentina. Ijọba ọhun fi ọpalamba iya jẹ obinrin naa ki wọn to pada ri oku lẹyin naa.

Lẹyin imọ ẹkọ ninu "philosophy" o si ṣiṣẹ olukọ nipa imọ 'literature' ati 'psychology' ko to pada di Jesuit.

Ọdun mẹwaa lẹyin naa lo di alufaa, o si goke agba ninu iṣẹ naa titi to fi di ọga agbegbe kan ni Argentina lọdun 1973.

Pope Francis holds up an insignia of the football team he supports

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Pope Francis fẹran ere bọọlu

Awọn ẹsun ti wọn fi kan an

Awọn kan gbagbọ pe ko ṣe daadaa to lati gbogun ti ijọba ologun Argentina.

Wọn tilẹ fi akoko igba kan fẹsun kan an pe o lọwọ ninu bi ijọba ologun naa ṣe ji awọn alufaa meji gbe lasiko ogun 'Dirty War' to waye laarin ọdun 1976 si 1983.

Bo tilẹ jẹ pe wọn fiya jẹ awọn alufaa meji naa, wọn pada ri wọn ni ihoho nibi kan ti wọn ti loogun orun fun wọn.

Lara ẹsun ti wọn fi kan Bergoglio ni pe, o kuna lati ṣo fun ijọba pe ijọ lo buwọlu iṣẹ awọn olufaa naa bo tilẹ jẹ pe iṣẹ naa ko koju oṣuwọn.

Nigba ti wọn beere lọwọ rẹ lẹyin ọpọ ọdun, eredi ti ko fi sọrọ soke lori iṣẹlẹ naa, o ni ko rọrun fun oun lati ṣe bẹẹ lọdun naa lọhun.

Pope John Paul II ati Poopu lọla, Pope Francis

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Pope John Paul II yan Jorge Mario Bergoglio gẹgẹ bii Archbishop ilu Buenos Aires ni 1998

Ọkunrin ti ko lagbaja

Wọn fi joye aṣoju alufaa agba ilu Buenos Aires lọdun 1992 ko to wa di alufaa agba funra rẹ.

Pope John Paul II fi joye 'cardinal' lọdun 2001, o si ṣiṣẹ ninu ijọ ilu Curia.

Lara awọn nnkan rere ti aye n sọ nipa rẹ ni bi ko ṣe jẹ ki aye jọ oun loju ti ko si gbe ara rẹ ga bii alufaa agba.

Nipa ti aṣọ wiwọ, lọpọ igba ni kii wọ aṣọ ti yoo fi han bii olori awọn alufaa.

Gẹgẹ bii Poopu, o gbiyanju lati pari aawọ ijọ ila oorun ilẹ Europe.

Pope Francis, Shimon Peres and Mahmoud Abbas

Oríṣun àwòrán, Reuters

Fransis ṣiṣẹ pẹlu ijọ Anglican, Lutheran ati Methodist, o si ke pe awọn Aarẹ ilẹ Israel ati Palestine lati darapọ mọ oun ninu adura.

Lẹyin ti awọn onijagidijagan Musulumi kan n gbogun, o sọ pe ko tọ lati maa fi orukọ jagidijagan pe awọn Musulumi.

O ni "ti mo ba sọrọ nipa iwa ipa awọn Musulumi, mo gbọdọ mẹnuba iwa ipa ijọ katoliki pẹlu."

Pope Francis and former President Fidel Castro.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Pope Francis ati Aarẹ Fidel Castro lasiko abẹwo rẹ si Havana lọdun 2015

Ẹni to fẹran ẹtọ ọmọniyan

Ninu awọn ẹkọ rẹ, o fi han pe oun fẹran ẹtọ ọmọniyan.

Lara awọn nnkan to ti sọrọ le lori ni idajọ iku ọrọ oyun ṣiṣẹ, ẹtọ eeyan lati wa laaye, bi awọn alufaa yo ṣe yẹra fun ibalopọ, eti bẹẹ bẹẹ lọ.

O sọ pe ijọ gbọdọ tẹwọ gba awọn eeyan lai wo igbagbọ wọn nipa ibalopọ.

Bo tilẹ jẹ pe ko sọ pe ki akọ ati akọ tabi abo ati abo maa gbe ara sile bii lọkọlaya, ko fi bẹẹ bu ẹnu atẹ lu iwa naa.

Lẹyin to gori itẹ Poopu lọdun 2013, o kopa ninu ifẹhonuhan lodi si oyun ṣiṣẹ nibi to ti sọ pe awọn oyun inu naa ni ẹtọ lati wa laaye.

O fi akoko naa ke pe awọn oniṣegun lati maa lo eero ọkan wọn ninu iṣẹ wọn, ati pe lati igba ti oyun ba ti waye ni ọmọ naa ti ni ẹtọ lati wa laye.

Pope Francis

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Pope Francis laarin awujọ awọn eeyan

Gbigbogun ti iwa ipa si ọmọde

Pope Francis meets with Ukrainian President Volodymyr Zelensky

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Pope Francis ati Aarẹ Ukraine, Volodymyr lọdun 2023

Ipenija meji nla ni Poopu yii dojukọ.

Akọkọ ni awọn to gbagbọ pe ko gbogun ti iwa ipa si ọmọde, atawọn mii ti wọn sọ pe o n mu eewọ wọ inu igbagbọ.

Lara awọn nnkan ti wọn n sọ ni pe o faaye gba ituka igbeyawo ati pe o faye gba awọn alufaa ti igbeyawo wọn ti tuka lati maa gba ara Oluwa.