Pope Francis ti jáde l'áyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Poopu ijọ Aguda, Francis, ti jade laye lẹni ọdun mejidinlaadọrun.
Owurọ ọjọ Aje, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, tii ṣe ọjọ keji Ajinde Jesu lo ku, niluu Romu.
Olori awọn alufaa, His Eminence, Cardinal Farrell, to kede iroyin iku Poopu, pẹlu ibanujẹ, sọ pe, ni nnkan bi aago meje aabọ owurọ lo mi eemi ikẹhin.
Wọn yan Poopu Francis, ti orukọ abisọ rẹ n jẹ Cardinal Jorge Mario Bergoglio, gẹgẹ bi olori ijọ Aguda, lọjọ kẹtala, oṣu Kẹta, ọdun 2013, lẹyin ti Poopu Benedict XVI kọwe fi ipo naa silẹ.
Poopu Francis ni Poopu akọkọ to wa lati ilẹ America.
Lẹyin ti Poopu Gregory III to jẹ ọmọ bibi orilẹede Syria ku lọdun 741, ko si ẹnikẹni to jẹ lati ilẹ miran yatọ si awọn ọmọ ilẹ Yuroopu.
Poopu Francis naa tun ni ọmọ ẹgbẹ Jesuit akọkọ ti wọn dibo yan si ori itẹ Peteru Mimọ - awọn ọmọ Romu ma n fi oju ifura wo awọn ọmọ ẹgbẹ Jesuits.
Ẹni to fi ipo naa silẹ fun Francis, Benedict XVI, ni Poopu akọkọ to finufindọ fẹhinti lẹnu iṣẹ lẹyin bi ọdun 600 ti iru rẹ ti waye kẹhin.
Ifipo silẹ rẹ si lo mu ki Olu Ijọ Aguda, ni Poopu meji laarin ọdun mẹwaa.
Ana ọjọ Aiku, to jẹ ọjọ ọdun Ajinde kaakiri agbaye ni Poopu foju han ni ita gbangba kẹyin.
Asiko naa lo ṣadura ọdun fun awọn eeyan ni gbagede Vatican.
Bi eto isinku Fransis yoo ṣe waye
Eto isinku alayẹyẹ nla ti wọn n pe ni 'papal funeral' lo yẹ ki wọn ṣe fun oloogbe naa amọ o ti sọ ṣaaju pe oun ko fẹ eto isinku alariwo.
Inu posi alarabara ni wọn sin awọn poopu to ti lọ ṣaaju rẹ si ṣugbọn Pope Francis ti sọ pe inu posi ti wọn igi lasan ṣe ni ki wọn sin oun si.
Bakan naa lo tun sọ pe oun ko fẹ ki wọn gbe oku oun si ori gbagede nla ti wọn n pe ni 'catafalque' to wa ni St Peter's Basilica, nibi ọpọ eeyan yoo ti maa wo oku naa.
Kaka ki eyii waye, niṣẹ ni awọn abanikẹdun yoo wa ki pe o digbere nidi posi rẹ.
Fransis ni yoo tun jẹ poopu akọkọ ti wọn ko ni sin si Vatican lati ọgọrun un ọdun o le sẹyin.
Basilica to wa ni St Mary Major Rome ni wọn yoo sin oku rẹ si dipo Vatican.















