Obìrin méjì pàdánù ẹ̀mí wọn lábé ilé tó dàwó ni Ojodu-Berger, orí kó mọ́kànlá yọ

Ile to dawo ni Ojodu
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA, ti kede pe eeyan mọkanla lawọn ri yọ labẹ ile to dawo ni adugbo Ọrẹmẹta, ni Ojodu-Berger.

Adari ajọ naa, Olufemi Damilola Oke-Osanyintolu, lo fi ọro naa lede ninu atẹjade kan.

Atẹjade naa so pe "Iṣẹ ṣi n lọ lọwọ nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

"A ri obinrin agbalagba mọkanla yọ labẹ ile naa, wọn si ti gba itọju lẹsẹkẹsẹ.

"Bẹẹ naa ni a tun ri oku meji yọ labẹ ile ọhun ti awọn naa jẹ obinrin, a ti fi oku wọn ṣọwọ sile igbokupamọsi.

"Awọn adoola ẹmi ṣi wa nibẹ lati maa ba iṣẹ lọ, a o maa fi to yin leti bi isẹ naa ṣe n lọ."

Aarin aago mẹjọ si mẹsan an arọ ọjọ Abamẹta ni ile alaja meji naa dawo.

Akọroyin BBC to lọ sibẹ jabọ pe iṣẹ ṣi n lọwọ lori ile naa ati pe wọn ko tii pari aja meji ori rẹ amọ wọn ti n ọja ni isalẹ rẹ ko to dawo.

Ọ̀pọ̀ èèyàn há sínú ilẹ̀ níbi ilé alájà mẹ́ta tó dàwó ní Eko

Àwòrán láti ilé alájà mẹ́ta tó dàwó ní Eko
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Èèyàn márùn-ún ni orí tik ó yọ lọ́wọ́ ikú òjijì báyìí bí ilé alájà mẹ́ta kan ṣe dàwó ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kọkàndínlógún ní ìpínlẹ̀ Eko.

Ní agbègbè Oremeta, Ojodu-Berger ni ilé náà dàwó ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ òwúrọ̀ gẹ́gẹ́ bí nǹkan táwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ṣe sọ.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, ọ̀gá àgbà àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko ìyẹn Lagos State Emergency Management Agency, LASEMA, Damilola Oke-Osanyintolu sọ pé iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ láti ṣàwárí àwọn tó há sábẹ́ ilé náà.

Ó ṣàlàyé pé àwọn máa ṣe iṣẹ́ náà dé ìsàlẹ̀ pátápátá láti ṣe àrídájú rẹ̀ pé gbogbo àwọn tó há sábẹ́ ilé náà láwọn yọ.

Ó ní àwọn ti yọ èèyàn márùn-ún láàyè àmọ́ tí ìbẹ̀rù wà pé ó ṣeéṣe káwọn mìíràn ti pàdánù ẹ̀mí wọn sínú lábẹ́ ilẹ̀ tí wọ́n wà.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ṣe sọ, ilé oúnjẹ kan wà níbi ilé náà kó tó dàwó àti pé kìí ṣe ilé tí wọ́n ti kọ́ ọ tán.

A kò le sọ pé iye èèyàn báyìí ní pàtó ló wà lábẹ́ ilé náà lásìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ.

Àwòrán láti ilé alájà mẹ́ta tó dàwó ní Eko
Àwòrán láti ilé alájà mẹ́ta tó dàwó ní Eko