VDM àtàwọn ọ̀dọ́ Arewa sọ̀kò ọ̀rọ̀ síra wọn lẹ́yìn tí Sultan Sokoto pe ayélujára nílé ìgbésùnmọ̀mí

Oríṣun àwòrán, @NgLabour/VDM
Ajafẹtọ ọmọniyan to tun jẹ gbajumọ lori ayelujara, Martins Vincent Otse, ti ọpọ mọ si Very Dark Man, VDM, ati olori awọn ọdọ ni iha ariwa, ti sọ oko ọrọ si ara wọn.
Gbas-gbos naa ko ṣẹyin fidio kan ti VDM ṣe lati tako ọrọ Sultan ilu Sokoto, Muhammadu Sa'ad Abubakar, lẹyin to sọ pe igbesunmọmi lawọn eeyan n ṣe lori ayejura.
Ṣaaju ni Sultan ti kọkọ sọ pe o yẹ ki ijọba gbẹsẹle tabi bẹrẹ si n ṣakoso ori ikansiraẹni lori ayelujara latari bi awọn eeyan ṣe n ṣi ori ikanni naa lo.
Amọ ọrọ naa ko dun mọ ọpọ ọdọ Naijiria ninu, ti pupọ ninu wọn si bu ẹnu atẹ lu ọrọ naa ti Sultan sọ.
Ọpọ ohun rere ni a n fi ori ayelujara ṣe – VDM
Lara awọn to bu ẹnu atẹ lu ọrọ Sultan ọhun ni VDM, to sọ pe ọrọ ti Sultan sọ ko tọ, nitori ọpọ eeyan lo n lo ori ayelujara fun nnkan rere.
VDM sọ pe kaka ki Sultan maa ti ẹnu bọ ọrọ ori ayelujara, niṣe lo yẹ ko lo ipo rẹ lati gbajumọ eto abo to dagẹgẹ ni Naijiria.
VDM sọ pe "Baba wa ni Sultan Sokoto, boya ẹnikan sọrọ kobakungbe nipa rẹ tabi lara awọn ọrẹ rẹ lori ayelujara lo jẹ ko fi itara sọrọ nipa ori ayelujara.
"Ẹ jọọ sa, ṣe ẹ le pe akiyesi ijọba apapọ si nnkan to n ṣẹlẹ ni Jos, nipinlẹ Plateau?"
VDM ni ori ayelujara kan naa ti Sultan n pe lori ikanni igbesunmọmi ni awọn ọdọ n lo lati ṣe rere lawujọ ati lati ja fun ẹtọ araalu.
A fẹ ki VDM tọrọ aforijin fun ẹtẹ to fi kan Sultan – Aarẹ Arewa
Ẹwẹ, lẹyin fidio VDM naa ni Aarẹ awọn ọdọ iha ariwa, Abdul DanBature, ke si VDM pe ko tọrọ aforinjin lọwọ Sultan fun ọrọ to sọ.
DanBature ni ọjọ meji pere ni awọn fun VDM lati yi ọrọ rẹ pada ko si tuuba lọwọ Sultan, bi bẹẹ kọ, yoo ri ibinu awọn eeyan Arewa.
Yatọ si Sultan, DanBature tun sọ pe VDM gbọdọ tọrọ aforijin lọwọ gbogbo awọn eeyan iha ariwa Naijiria.
Lẹyin naa ni VDM tun ṣe fidio mii to si sọ pe oun ko ri Sultan fin ninu ọrọ oun akọkọ.
O ni oun kii ri ori ade fin, eyii ti Sultan jẹ ọkan ninu wọn, amọ awọn ọdọ iha ariwa lo ṣi oun gbọ.
Lẹyin naa naa lo rọ DanBature pe ko dẹkun ati maa tete sọrọ lọjọ mii lai kọkọ mọ ohun ti ọrọ naa da le lori.















