Mo pàdánù N10m sínú okoòwò CBEX - Taye Currency

Taye Currency
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja olorin Fuji, Taye Adebisi, ẹni ti ọpọ mọ si Taye Currency ti ṣalaye pe oun pẹlu awọn eeyan oun padanu owo sọwọ ileeṣe sogun di ogoji, CBEX.

Currency ni milọnu mẹwaa ni oun padanu sọwọ CBEX.

Ninu fọnran kan to jade sori ayelujara ni Currency ti kede eyi lasiko to n ṣere orin lọwọ.

O ni awọn eeyan kan to sunmọ oun pẹkipẹki lo ni ki oun kowo sinu Ileeṣẹ sogun di ogoji naa.

"Ni ọjọ kinni, oṣu kẹrin, Sodiq wa si ile mi, to si sọ fun mi pe Lateef ti gba owo, to si fa Alaba ati Small London wọle, ti awọn naa si gba owo pẹlu Brọda Muca.

Ninu fọnran ọhun, Currency fi ibinu rẹ han si awọn to ni ko wa fi owo sori CBEX.

"Ti ẹ ba ku re, ẹ le sun ree nitori jẹjẹ mi ni mo wa nigba ti ẹ gbe CBEX wa bami.

Ọpọlọpọ awọn eeyan to kowo le atẹ okoowo sogundogoji lori ayelujara, ti ọpọ eeyan mọ si CBEX, ti n gbarata lẹyin ti iroyin lu sita wi pe owo wọn ti wọgbo.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ajọ to n tanna wadi iwa ọdaran ni orilẹede Naijiria, EFCC ti fidi rẹ mulẹ pe oun ti n se iwadi si ẹsun kiko owo to to Trilliọnu kan ati biliọnu lna ọọdunrun naa jẹ lati ipasẹ eto idokowo ori ayelujara CBEX.

Gẹgẹ ohun ti o a ri ka, Ileeṣẹ CBEX ni wọn da silẹ tí ni ọdun 2022, eyiun ọdun mẹta sẹyin.

Cripto Currency ni wọn ni awọn n ṣe, ti wọn sọ owo awọn eeyan di ilọpo meji.

Ṣugbọn ni ọsẹ to kọja, CBEX ko jẹ ki awọn eeyan gba owo wọn sita ,ti ariwo si sọ.

Kete ti ileeṣẹ CBEX ko owo awọn eeyan ni awọn ọdọ kan yawọ ọfisi wọn niluu Ibadan, ti wọn si bẹrẹ si ni ko gbogbo ẹru wọn lọ.

Fọnran kan to lu sita lori ayelujara safihan bi awọn ọdọ kan ṣe binu yawọ ọfisi naa to wa niluu Ibadan, ti wọn si n da gbogbo nnkan ru, koda wọn ji ọpọlọpọ awọn nnkan ini wọn lọ.

Bakan naa ni ana ode yii ni Ileeṣẹ CBEX ko gba wọle, ti wọn si tun sọ fun onibara pe ẹni to ba ni apapọ owo to din ni ẹgbẹrun kan Dọla, san owo ọgọrun un Dọla, ti awọn to ni apapọ owo to le ni ẹgbẹrun kan Dọla, lọ san owo to jẹ igba Dọla.

Eyi lo bi ọpọlọpọ ninu sugbọn CBEX ni wọn ko ni anfani si owo wọn, ti wọn ko ba san owo tuntun ti wọn ni ki wọn san.