"Kò sí ẹnìkankan tó ń gbé ní ìjọba ìbílẹ̀ kan mọ́ torí Boko Haram, a kò le lọ ra oúnjẹ láì sí ológun lẹ́yìn wa, inú ìbẹ̀rù là ń gbé"

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn ìròyìn kan láti ìpínlẹ̀ Borno sọ pé àwọn ìjọba ìbílẹ̀ kan ní ìpínlẹ̀ náà ló wà lábẹ́ àkóso ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Boko Haram àti Iswap.
Ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá, Sẹ́nétọ̀ Ali Ndume sọ fáwọn akọ̀ròyìn nílùú Abuja pé àwọn ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́ta ló wà lábẹ́ àkóso Boko Haram ní ìpínlẹ̀ Borno.
Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ náà ni Gudumbari, Marte àti Abadam.
Láìpẹ́ yìí náà ni gómìnà ìpínlẹ̀ Borno, Babagana Zulum kọminú pé ìkọlù àwọn Boko Haram àti Iswap tún ti ń peléke si àti pé ìjọba àpapọ̀ nílò láti tètè mójútó ìkọlù náà kó tó le ju bí ó ṣe wà báyìí lọ.
Àwọn èèyàn tó ń gbé ní agbègbè yìí sọ fún BBC News Pidgin pé láti ọdún mẹ́fà sẹ́yìn ni àwọn ti ń gbé lábẹ́ àkóso Boko Haram àti Iswap, tó sì jẹ́ pé inú fu àyà fu ni àwọn fi ń gbé ayé.
"Inú ìbẹ̀rù ni àwọn èèyàn tó wà ní agbègbè náà fi ń gbé ayé, Awọn agbesunmọmi máa ń gba ìṣákọ́lẹ̀ àti oúnjẹ lọ́wọ́ àwọn èèyàn"
Ẹnìkan tó ń gbé ní Gudumbari tí kò fẹ́ kí a dárúkọ òun sọ pé àwọn kò rí ìrànlọ́wọ́ lọ́tọ̀dọ̀ ìjọba àpapọ̀ àtàwọn iléeṣẹ́ ológun láti ọdún 2018. Ó ní abẹ́ àkóso àwọn agbéṣùmọ̀mí náà ni àwọn wà láti ọdún 2018 tí wọ́n ti ṣe ìkọlù sí àgọ́ àwọn ológun tó ń ṣọ́ àwọn ìlú kan ní ìjọba ìbílẹ̀ Gudumbari lọ́dún náà.
"Láti ọdún 2018 tí wọ́n ti ṣe ìkọlù sí àgọ́ ológun, bíi ìlú mẹ́wàá ló ti wà lábẹ́ àkóso Boko Haram àti Iswap.
"Ìlú Gudumbari nìkan ló wà ní abẹ́ àkóso àwọn ológun, abẹ́ àkóso àwọn agbéṣùmọ̀mí ni ọ̀pọ̀ àwọn ìlú tó kù wà."
Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé inú ìbẹ̀rù ni àwọn èèyàn tó wà ní agbègbè náà fi ń gbé ayé nítorí àwọn agbéṣùmọ̀mí náà máa ń kọjá nígbàkúgbà tó bá wù wọ́n.
Bákan náà ló ní wọ́n máa ń gba ìṣákọ́lẹ̀ àti oúnjẹ lọ́wọ́ àwọn èèyàn náà nítorí iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ọ̀pọ̀ wọn máa ń ṣe.
Ó ní wọ́n máa ń fìyà jẹ ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ̀ nígbà míràn àti pé àwọn kò lè lọ sí ìlú Maiduguri láti ìjọba ìbílẹ̀ náà nítorí ọ̀rọ̀ ààbò.
"Tí ẹ bá rí èèyàn tó lọ sí Gudumbari láti Maiduguri, yálà kó jẹ́ pẹ̀lú gómìnà tàbí káwọn ológun tẹ̀ lé e."

Oríṣun àwòrán, BOKO HARAM
"Kò sí aráàlú kankan tó ń gbé ní ìjọba ìbílẹ̀ Abadam"
Ní ìjọba ìbílẹ̀ Abadam, kò sí èèyàn tó ń gbé ní àwọn ìlú tó wà níbẹ̀ mọ́ nítorí ọ̀rọ̀ ààbò.
Ẹnìkan sọ fún BBC pé kò fẹ́ ẹ̀ sí èèyàn kankan tó ń gbé ní ìjọba ìbílẹ̀ náà mọ́ yàtọ̀ sáwọn ológun tó ń gbé ní oríkò ìjọba ìbílẹ̀.
"Àwọn ológun nìkan ló ń gbé ní oríkò ìjọba ìbílẹ̀ náà nítorí gbogbo àwọn èèyàn ti sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.
"Bíi ìdajì àwọn èèyàn tó ń gbé ní ìjọba ìbílẹ̀ náà ló ti sá lọ sí Niger tán, táwọn mìíràn sì ti fọ́n ká sáwọn ìlú tó súnmọ́ ìpínlẹ̀ Borno."
Ó fi kun pé orílẹ̀ èdè Niger ni àwọn èèyàn agbègbè náà máa ń gbà dé Maiduguri báyìí nítorí wọn ò lè gba ojú ọ̀nà wọn mọ́.
"A kò lè ra oúnjẹ àyàfi táwọn ológun bá tẹ̀lé wa"
Àwọn èèyàn tó ń gbé ní ìjọba ìbílẹ̀ Marte náà tis á àsálà fún ẹ̀mí wọn tán.
Ọ̀kan lára àwọn olùgbé ìjọba ìbílẹ̀ náà, Babagana Ali sọ pé kò sí èèyàn kankan mọ́ ní ìlú Marte àtijọ́ mọ́.
Ó ní ibòmíràn tó jẹ́ Marte tuntun, tó jìnà sí Marte àtijọ́ ní ìwọ́n kìlómítà méjìlá láwọn èèyàn wà báyìí.
"Síbẹ̀ inú ìbẹ̀rù láwọn èèyàn wà nítorí àwọn agbéṣùmọ̀mí máa ń ṣe ìkọlù sí wọn ní lóòrèkóòrè.
Ali ní ìṣòro mìíràn táwọn èèyàn ń kojú ni pé wọn ò lè lọ máa ra oúnjẹ láwọn ìlú tó súnmọ́ wọn bíi Dikwa.
"Àwọn èèyàn kò lè lọ máa ra oúnjẹ tí kò bá di ìparí oṣù táwọn ológun máa sìn wọ́n lọ."
Àwọn aráàlú ń bẹ ìjọba láti báwọn dá àlááfíà padà sí agbègbè wọn.
Láti bíi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn ni ìpínlẹ̀ Borno ti ń kojú ìpèníjà ààbò èyí tó ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí lọ, táwọn mìíràn sì ti sa kúrò nílé wọn.















