"N kò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ilé kíkùn pẹ̀lú owó gbígbà, owó ọkọ̀ àti oúnjẹ Noodles nìkan ni wọn ń fún mi"
Yoruba ni ori lo mọ isẹ asela, bẹẹ si ni idi isẹ ẹni la ti n mọ ni ni ọlẹ.
Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu akinkanju obinrin kan, Bankole Jesupemi to jẹ akọni obinrin tori isẹ to yan laayo, eyi tii se isẹ akunle.
Ọpọ eeyan lo mọ pe isẹ kikun ile kii se isẹ awọn abo bikose isẹ ọkunrin amọ ohun iyalẹnu lo jẹ pe obinrin kan yan isẹ yii ni aayo.
Ninu iroyin yii, Jesupemi salaye bo rin irin ajo aye rẹ to fi di ẹni to yan isẹ ile kinkun ni aayo bi o tilẹ jẹ pe o kẹkọ jade nile ẹkọ fasiti.

"Isẹ aworan yiya lo wu mi, amọ nigba ti mo de ile ẹkọ giga, mo bẹrẹ si ni kun ile fun awọn eeyan"
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Bankole Jesupemi ni isẹ ayaworan ni oun lọ kọ ni fasiti.
"Ero awọn obi mi ni pe iṣẹ agbẹjọro ati isẹ dokita lo n mu ki eeyan se aseyọri amọ ninu mi, mo mọ isẹ to wu mi, ti mo fẹ se nile ẹkọ fasiti.
Isẹ aworan yiya lo wu mi, amọ nigba ti mo de ile ẹkọ giga, mo bẹrẹ si ni kun ile fun awọn eeyan.
Idi ni pe eeyan to ba jẹun kanu bii akẹkọ ni yoo sọ pe oun fẹ ya aworan ara rẹ, amọ mo mọ pe onikaluku maa n nifẹ lati kun yara wọn.
Idi ree ti mo se pa aworan yiya ti, ti mo si bẹrẹ si kun ile.
N ko bẹrẹ ile kikun yii pẹlu owo gbigba, ohun ti mo kan maa n beere ni pe ki wọn se ounjẹ Noodles fun mi ati owo mọto.
Ohun to sa wu mi ni pe ki n kun ile nitemi, ki n sa fi ọda sere"

"Ọ̀pọ̀ ìpèníjà ni mo rí nídìí iṣẹ́ ilé kíkùn, mo ti jábọ́ lórí àkàsọ̀ rí dáadáa lásìkò tí mò ń kunlé"
Bankole Jesupemi tun salaye ọpọ ipenija to n koju nidi isẹ kikun ile, to si ni ọpọ igba ni oun ti ja bọ silẹ lasiko ti oun m kun ile.
"Mo ti ja bọ ri daadaa lati ori akasọ nibi ti mo ti lọ kun ile.
Bakan naa, Jesupemi ni orukọ ti ko dara ni awọn eeyan miran maa n pe awọn osisẹ to yan ile kikun ni aayo.
O ni nibikan, wọn ti pe oun ni Apọda ri tabi akunle.
O wa koro oju si awọn orukọ yii, to si ni isẹ to se mu yangan ni isẹ ile kikun nitori kii se isẹ ole jija tabi owo Nabi.
Jesupemi fikun pe awọn eeyan kan tiẹ wa ti ẹnu maa n ya pe obinrin naa yan isẹ ile kikun ni aayo.
"Obinrin kan tiẹ wa to sọ fun mi pe aburo mi, o ti rẹwa ju isẹ ile kikun ti o n se lọ"

"Lasiko igbele arun Coronavisrus, ti ọda ko wọ orilẹede yii, ni mo bẹrẹ si se ọda funra mi"
Jesupemi tẹsiwaju pe lara ipenija nla ti oun koju nidi isẹ ile kikun to yan laayo ni akoko igbele arun Coronavirus, ti a tun mọ si Covid-19.
"Asiko igbele Covid-19 yii , ni ọpọ eeyan fẹ kun ile amọ ọda ko wọ orilẹede yii wa.
Akoko yii ni mo roo pe emi naa le po ọda papọ, mo kọ ọ loju opo YouTube, t imo si bẹrẹ si se ọda temi funra mi.
Mo wa n rọ awọn eeyan ti ko ni isẹ lọwọ lati wa nkan se, ko baa jẹ isẹ amọle.
Ọpọ awa ti a jẹ akẹjade fasiti, igberaga ti ba ti ọpọlọpọ wa jẹ.
A kii fi ara balẹ fun awọn eeyan ti ko kawe lati ran wa lọwọ, otitọ ọrọ to wa nibẹ niyẹ,"






