Ààrá sán pa èèyàn mẹ́ta ní ọjà ìrẹsì, márùn míì farapa

Lara awọn eeyan to faragba ninu ara to san pa eeyan mẹta ni Obidi Agwa, to wa ni ijọa ibilẹ Oguta, nipinlẹ Imo ti sọ ohun ti oju wọn to fun BBC.
Nigba ti akọroyin BBC lọ sibẹ, ọkan lara awọn ti ọrọ naa kan, Nwakaego Napoleon Eric ṣalaye pe inu ọja Uzhi, ti awọn obinrin ti n ta irẹsi ni ara naa ti san.
O ṣalaye pe "Mo ti ta apo ti mo gbe lọ inu ọja tan mo si fẹ maa lọ sile, ki obinrin kan to ra apo kan lọwọ to mi pe ki n wa gba owo ohun to ra, ojo ti bẹrẹ si n rọ diẹdiẹ lasiko yii.
"Mo fẹ gba owo irẹsi ti mo ta ni ara nla kan san, to si pa ọpọ eeyan, ara naa fa aṣọ mi ya, bẹẹ lo tu mi si ihoho"
"Bi mo ṣe ni ki n wo ẹyin wo lati gba owo naa bayi ni ara nla kan san to si pa ọpọ eeyan, ara naa fa aṣọ mi ya, bẹẹ lo tu mi si ihoho."
O ṣalaye fun BBC pe awọn eeyan agbegbe naa lo doola oun, lẹyin naa lo ke si ijọba fun iranlọwọ.
Ẹlomiran to tun farapa ninu iṣẹlẹ ọhun ni ọmọ ọdun mẹsan an kan.
Iya ọmọ naa, Nkechinyere Ughala, ni ṣe loun ran niṣẹ lọ lati ran nnkan ninu ọja naa ki oun to gbọ iroyin ohun to ṣẹlẹ nibẹ.
Aarẹ agbegbe Obidi Agwa, Oloye VC Eke sọ pe oun ko tii ri irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ ri lati igba ti wọn ti bi oun.
O ṣalaye pe eeyan mẹta lo ku lẹsẹkẹsẹ lẹyin ti ara naa san nigba ti awọn marun mii farapa.
Oloye ọhun wa ke si ijọba ipinlẹ Imo lati ṣe iranlọwọ fun awọn ti orọ naa kan.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin yii ni iṣẹlẹ naa waye.
Ṣaaju ki BBC to ṣabẹwo siluu naa ni fidio kan ti kọkọ gba ori ayelujara, ninu eyii ti ọkunrin kan ti n pariwo pe ara san pa eeyan meje ninu ọja naa.















