Ṣé lóòtọ́ọ́ làwọn báǹkì àtàwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga ń hùwà ìwà ìbájẹ́ nídìí pínpín owóyàá akẹ́kọ̀ọ́ tí Tinubu gbé kalẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Latigba ti ijọba apapọ ti kede eto ẹyawo fawọn akẹkọọ ileewe giga ilẹ yii ni bi eto naa yoo ṣe ri ti n mu awuyewuye dani.
Idi ni pe o fẹrẹ ma si akẹkọọ kan to jade pe oun ti jẹ anfaani ẹyawo naa.
Laipẹ yii ni ajọ National Orientation Agency (NOA) ati Nigerian Education Loan Fund (Nelfund), kede pe magomago kan n waye nipa ẹyawo naa.
Awọn ajọ yii fẹsun kan awọn banki ati ile ẹkọ giga, pe wọn n dari ẹyawo naa sọdọ wọn lai ya awọn akẹkọọ.
Lati ti okodoro ọrọ yii, BBC ba awọn akẹkọọ kan sọrọ, eyi ni iriri wọn.
Mi ò ní í sanwó tí mi ò yá- Moses
Akẹkọọ kan lati ile ẹkọ giga Federal University of Technology, to wa ni Owerri, ipinlẹ Imo, to pe orukọ rẹ ni Moses, ṣalaye fun BBC pe oun ko mọ idi ti ile ẹkọ yoo ṣe gba ẹyawo tijọba ṣe lorukọ oun.
Moses sọ pe ki lo mu yunifasiti maa gba owo lọwọ ajọ Nelfund, owo tijọba fẹẹ ya akẹkọọ, ki wọn si tun ni ki akẹkọọ sanwo ileewe lẹyin owo ti wọn ko gba.
''Emi Io le sanwo ti mi o ya fun Nelfund.
''Mama mi o rowo ileewe mi san, niṣe lo lọọ yawo nigba ti wọn ni ka san ida ogoji ninu owo naa ki n too le ṣe idanwo.
''Iya mi yawo tan, mi o ri ẹyawo ijọba gba. Bẹẹ ileewe wa ti sọ tẹlẹ pe awọn maa da owo ta a san ni saa ẹkọ 2023 si 2024 pada fun wa, a o ri nnkan kan.
" Ki lo de ti Nelfund ko ṣe maa sanwo ti wọn fẹẹ ya wa si akanti wa gan-an? Awa la maa sanwo ta a ba ya, ki i ṣe ileewe wa. O ti n han bayii pe wọn ti sanwo yẹn fun mi pẹlu awọn ajẹmọnu rẹ, mi o si gbowo kankan."
Akẹkọọ naa tẹsiwaju pe oun fẹ ki Yunifasiti Imọ ẹrọ to wa l'Owerri yii ṣalaye, nitori wọn ti ni awọn ko ni i da owo awọn akẹkọọ pada fun saa 2023/ 2024 ti wọn ti kọkọ lawọn yoo da pada fun wọn tẹlẹ.
"Wọn n fipa mu akẹkọọ pe ka san ida ogoji ninu owo saa ẹkọ 2024/ 2025 ka too le ṣe idanwo, emi o le sanwo ti mi o gba o."
'Ilé ẹ̀kọ́ tiwa kò tiẹ̀ sanwó kankan, wọ́n tún ní ká yọjú káwọn rí wa ni'
Akẹkọọ miran, Jerry Egwowa, lati Yunifasiti Calabar, ṣalaye fun BBC pe ile ẹkọ oun ko fun awọn akẹkọọ lowo kankan.
O ni wọn ni kawọn yọju ki wọn too le sanwo fawọn ni.
Egwowa ṣalaye pe owo apo ti wọn fẹẹ san naa ko tilẹ to owo ọkọ oun de ileewe, o loun le fi boun ṣe n nawo sọwọ si awọn alaṣẹ ileewe oun ki wọn ri i.
"Lati ọdun to kọja ti wọn ti fidi orukọ ati ohun gbogbo nipa mi mulẹ, mi o ti i ri owo kankan gba.
"Niṣe ni Unical n sọ fawọn akẹkọọ pe ki wọn waa fara han, emi o dẹ ro pe iyẹn ṣe koko, ki waa la ni ayelujara fun, nigba ti mo le fi ohun gbogbo nipa mi ṣọwọ si wọn lori ayelujara.
"Owo t imo maa fi wọkọ lọọ fi ara han gan-an pọ ju owo apo ti mo fẹẹ gba lọ. "
BBC kan si awọn alaṣẹ ile ẹkọ giga mejeeji yii fun alaye, ṣugbọn wọn ko fesi titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii.
Báǹkì àti àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga ló ń kówó àwọn akẹ́kọọ̀ọ́ pamọ́ -Nelfund, NOA
Lori ayelujara, awọn akẹkọọ kan n sọ pe akọsilẹ ti banki ni nipa akanti awọn ki i ṣe tawọn.
Bẹẹ lawọn kan n sọ pe o n han pe awọn ti gbowo lai ti i ri kọbọ kan gba lati ọwọ ile ẹkọ awọn.
Akẹkọọ kan, Akintunde Micheal, sọ loju opo X rẹ pe UBA ni ileefowopamọ toun n lo, ṣugbọn Unity ni banki ti wọn kọ orukọ oun si.
Akintunde sọ pe nọmba to wa nibẹ gan-an ki i ṣe toun.
Akẹkọọ miran, Christian Micheal, sọ pe o n foju han pe oun ti sanwo ileewe oun.
"Mo ṣẹṣẹ n ri i bayii pe mo sanwo ileewe ni, ko han tẹlẹ loju opo mi. "
Nigba to n n fesi si awọn nnkan wọnyi, National Orientation Agency (NOA), sọ pe awọn ile ẹkọ kan lo n tọju owo naa.
Paul Odenyi, agbẹnusọ NOA, ṣalaye ninu atẹjade ajọ naa, pe iwadii awọn fi han pe awọn ile ẹkọ giga kan n lẹdi apo pọ mọ awọn banki lati ma ṣe fun awọn akẹkọọ lowo.
"Iwadii wa fi han bawọn ile ẹkọ kan ṣe n lẹdi apo pọ pẹlu banki, ti wọn n mọ-ọn-mọ da owo awọn akẹkọọ to peregede duro. Wọn n lo owo naa fun anfaani ara wọn. "
Nelfund kìlọ̀
Bakan naa ni ajọ Nelfund funra wọn naa sọ pe awọn ile ẹkọ kan wa ti wọn ki i sọ fawọn akẹkọọ nipa owo to tọ si wọn.
Akintunde Sawyerr, ọga agba Nelfund, lo sọ eyi di mimọ.
Bakan naa lo kilọ fun awọn ile ẹkọ lati maa jẹ ki awọn akẹkọọ mọ nipa ẹyawo wọn to ba ti bọ si i.
Akintunde ni ki wọn yee beere owo lọwọ awọn akẹkọọ ti wọn ko ya lowo.
" Ka maa tọju owo ati ohun to yẹ kawọn akẹkọọ mọ nipa owo wọn lodi si ofin ti wọn tori ẹ gbe Nelfund kalẹ .
A ko ni i woju ẹnikẹni ta a maa fi gbe igbesẹ ofin lori ile ẹkọ to ba n huwa arumọjẹ. "
Bí wà á ṣe mọ̀ bóyá Nelfund ti fowó ránṣẹ́ sí ilé ẹ̀kọ̀ rẹ

Oríṣun àwòrán, Nelfund@X
Nelfund kede pe akẹkọọ le mọ eyi nipa :
Gbigba atẹjiṣẹ ti a mọ si 'Upkeep Disbursement Alert' – Eyi wa fun awọn ti wọn n beere ẹyawo owo apo.
Ikede Dashboard Notification – Eyi yoo fi alaye kikun nipa ẹyawo ile ẹkọ han.
Yiyẹ orukọ atawọn alaye yooku wo deede
Mimọ ọjọ ti wọn yoo sanwo
Mimọ boya wọn ti sanwo naa tabi bẹẹ kọ.(Disbursed)
Mimọ iru ẹyawo to o fẹ
Bi o ba ri "Disbursed", o tumọ si pe Nelfund ti sanwo ileewe si apo wọn niyẹn.
Ṣugbọn bi wọn ko ba ti i ri i gba, ki wọn fi to awọn oṣiṣẹ Nelfund leti lẹka ayelujara wọn.














