Lẹ́yìn-o-rẹ̀yìn, Portable sun ọgbà ẹ̀wọ̀n Oke-Kura n‘Ilorin mọ́jú, wọ́n fá irun rẹ̀ tó kùn ní ọ̀pọ̀ àwọ̀, kodoro

Gbajugbaja olorin takasufe n ni, Badmus Habeeb Okikiola (Portable) lo sun ọgba atunse to wa ni Oke-Kura ni ilu Ilorin mọju owurọ yii.
Koda, a tun rii gbọ pe, irun ori rẹ ti o kun lorisirisi awọ ni wọn ti yọ abẹ si ni ọgba atunse naa, ti wọn si faa kodoro.
Tẹ o ba gbagbe, lana ọjọ Aje ni ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara wọ Portable wa Ileẹjọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti olorin Fuji kan, Saheed Osupa fi kan-an.
Lotitọ ni ile-ẹjọ ti gba beeli ati oniduro olorin naa sugbọn ko tii gba ominira maa tatile wa sẹjọ nitori awọn gbendeke beeli rẹ to soro fun-un lati ri.
Alaga ẹgbẹ PMAN ni Kwara, kọ lati yọju si Portable lati jẹ oniduro fun-un
Nibi igbẹjọ naa to waye lana, adajọ ni ki Portable pese millionu kan naira, eeyan kan to ni dukia ori ilẹ ati alaga Performing Musicians Association of Nigeria PMAN ẹka ti ipinlẹ Kwara, fun ile ẹjọ ko to le maa tatile wa sẹjọ.
Pẹlu gbogbo igbiyanju Portable ati awọn eniyan rẹ, gbendeke ẹlẹkẹta jẹ eyi to yi bobo fun-un.
Ohun ti a gbọ ni wi pe Alhaji Adisa Owala, ti o jẹ alaga ẹgbẹ PMAN ni Kwara, kọ lati yọju si Portable lati jẹ oniduro fun-un.
A o mọ idi ti alaga naa fi ṣe eyi, awọn kan ni ọwọ ti kan ọwọ, sugbọn ohun to da wa loju ni pe titi ilẹ fi su, ko yọju sibẹ lati duro fun were olorin naa.
Idi ni yii ti Portable ọmọ Olalomi ṣe gba atẹgun moju lọgba atunse Oke-Kura.
"Bi Portable se n ga apa lọgba atunse lo jẹ fa irun rẹ lati ja irawọ rẹ, ko maa ba ma sẹnu bele bele nigba to ba jade tan"
Ọkan lara osisẹ ile itura naa to ni ka fi orukọ bo ohun lasiri fi to BBC News leti pe, Portable wa lalafia ara ninu ọgba naa.
"Ko si ẹni to luu tabi fọwọ kan-an nibẹ, koda o tun forin da wa lara ya ni.
"Nnkan ẹyọ kan ti a kan ṣe fun nipe, a ti fa irun ori rẹ, idi ti a si fi ṣe eyi nipe bi wọn ṣe gbee wọle lo n sọ pe, "ogo ni mi"
"Bi o se n gapa yii lo faa ta fi fa irun rẹ lati ja irawọ rẹ, ko maa ba ma sẹnu bele bele nigba to ba jade tan.
"Lẹyin eyi, ko si nkan ti wọn fi se Portable ọmọ Olalomi, o wa lalafia ara".
Báyìí ni ìgbẹ́jọ́ ẹ̀sùn ìbanilórúkọjẹ́ tí Saheed Osupa fi kan Portable ṣe lọ nílé ẹjọ́ n'Ilorin

Ajọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti wọ gbajugbaja olorin takasufe n ni, Badmus Habeeb Okikiola, ti ọpọ mọ si Portable lọ Ile ẹjọ Upper Area kan niluu Ilorin ipinlẹ Kwara lonii ọjọ Aje ọjọ kẹrinla oṣu Kẹrin.
Iwaju adajọ agba, Họnọrebu Sunday Adeniyi, ni wọn wọ olorin naa wa lonii.
Nise ni olorin takasufe naa n bomi loju poro poro nile ẹjọ.
Gẹgẹ iwe ipẹjọ ti awọn ọlọpaa gbe wa sile-ẹjọ, ẹsun ibanilorukọjẹ, idunkokomọni, dida rogbodiyan silẹ ati itabuku ẹni lori ayelujara ni wọn fi kan an.
Ẹni ti o si fi ẹsun naa kan an ni ilumọka olorin fuji, Saheed Osupa.
Bí ìgbéjó ṣe lọ ní ilé-ẹjọ́
Ni ibẹrẹ igbẹjọ ni adajọ ni ki wọn ka awọn ẹsun ti wọn fi kan afurasi ọhun si i leti gẹgẹ bi o se wa ninu iwe ipẹjọ awọn ọlọpaa.
Wọn ka a wi pe Saheed Osupa fi ẹsun ibanilorukọjẹ kan Portable lori Instagram ati lori itakun ayelujara mii.
Iwe naa sọ pe Portable ni Saheed maa n sọ pe ki wọn yọ orin oun kuro lori ẹrọ Sportify ti o si maa n mu oun padanu owo gobọi.
Lẹyin eyi, Portable sọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan oun.
Oniduro fun Portable, Isaac Adebayọ, bẹbẹ pe ki wọn fun onibaara oun ni beeli.
O ni yoo ma wa ile ẹjọ ni gbogbo ọjọ igbẹjọ.
Agbefọba Abubakar Issa tako ọrọ naa wi pe ibanilorukọjẹ ti di baraku fun afurasi naa.
O ni o lewu ti wọn ba gba beeli rẹ nitori yoo tun ṣẹ ẹsẹ to ju eyi lọ.
Ìdájọ́ Adájọ́ lórí béèlì Portable
Ninu idajọ ranpẹ adajọ, o gba beeli ati oniduro Portable ni pẹlu millionu kan naira.
O tun ni ki o mu olori awọn ẹgbẹ olorin ni Naijiria PMAN, ẹka ti ipinlẹ Kwara ati eeyan kan ti o ni ilẹ ni ilu Ilorin wá sí ile ẹjọ.
Ile ẹjọ ni Portable yoo wa ni ile atunse Oke-Kura titi yoo fi pese awọn ohun ti o ka kalẹ yii.
Portable tún dèrò àtìmọ́lé ọlọ́pàá lẹ́yìn tí Saheed Osupa fẹ̀sùn ìbanilórúkọjẹ́ kàn án

Oríṣun àwòrán, Portable
Gbajugbaja olorin fuji, Okunola Saheed, ti ọpọ mọ si "Saheed Osupa" ti fi ọlọpaa mu olorin takasufe, Habeeb "Portable" Okikiola Badmus.
Ọjọ Aiku ni iroyin gba ori ayelujara kan wi pe awọn ọlọpaa mu Portable ni ilu Abeokuta, ni ipinlẹ Ogun.
Alẹ ọjọ aiku yii kan naa ni ileesẹ ọlọpaa Kwara fidi rẹ mulẹ pe awọn ti di panpẹ ofin mu were olorin naa.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa Kwara, Ejirẹ Adetoun Adeyemi, fi lede, o ni Osupa lo fi ẹsun kan Portable ni ọọfoso ọlọpaa Kwara ti awọn si bẹrẹ igbesẹ lori rẹ ni labẹ ofin.
Adetoun ni ẹsun naa da lori ibanilorukọjẹ, idunkoko mọni ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O fi kun pe, bi ẹsun naa se wuwo to lo faa tawọn fi gba asẹ ni ile ẹjọ Majisireeti Kwara ti awọn si tẹsiwaju lati mu afurasi ọhun.
Agbẹnusọ naa ni ilu Abeokuta ni ipinlẹ, Ogun ni awọn ti mu Portable lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun 2025 yii, ti awọn si wọ lọ si Ilorin fun iwadii.

Oríṣun àwòrán, Opeyemi
Ọlọpaa ni "A gba ọrọ rẹ silẹ niwaju awọn agbẹjọro igun mejeji, o si wa ni akata wa bayii, nigbati eto n lọ lọwọ lati wọ lọ ile ẹjọ lai fi akoko ṣofo".
O salaye pe ọlọpaa ipinlẹ Kwara wa fun gbigbe ofin ro lai ṣeke tabi ṣegbe lẹyin ẹnikẹni.
Agbẹnusọ ọlọpaa naa wa rọ araalu ki wọn wa ni alaafia ki wọn si ṣọra fun iroyin ẹlẹjẹ.
Ile itura fi ẹsun gbese kan Portbale
Ẹwẹ, ile igbafẹ kan ti a mọ si Starwood 02 Arena niluu Ilọrin, naa sọ pe, ọlọpaa Kwara mu Portable lori ẹsun ti awọn fi kan-an wi pe o jẹ awọn ni owo ti iye rẹ le ni milliọnu mẹfa naira.
Agbenusọ ile itura ọhun, arabinrin Seun, ninu ohun to fi lede to tẹ BBC Yoruba lọwọ sọ pe awọn ti wa lori ọrọ yii lati ọdun to kọja.
Arabinrin naa ni ọga oun pe Portable ko wa ṣere nile awọn naa, ti wọn si san owo ti iye rẹ jẹ N6.3m to bere fun.
Bo tilẹ jẹ pe o yọju lootọ ṣugbọn o kọ lati sere fun awọn.
Arabinrin naa ni gbogbo ohun ti ọga oun n bere fun ni koda owo naa pada ṣugbọn Portable kọ, o si n bere fun ki oun pada wa ṣere fun awọn.
Obinrin naa sọ pe ọga oun wa lorilẹede Germany bayii, ohun to si n fẹ ni ki Portable da owo to gba pada.
















