Mọ̀ nípa ìdí ti ìjọba ológun orílẹ̀èdè Niger ṣe sọ Hausa di èdè àjùmọ̀lò

Aworan awọn ologun ati awọn tọrọ kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ologun to n ṣakoso orilẹede Niger ti kede ede Hausa bii ajumọlo ede ti wọn yoo maa lo niluu naa.

Atẹjade kan ti wọn fi lede lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta ọdun 2025 lo ti kọkọ fidi ofin naa mulẹ.

O kede pe lara ilana tuntun to yatọ si ohun ti ijọba alagbada to wa nibẹ tẹlẹ n ba bọ ni igbesẹ yii.

Gẹgẹ bi wọn ti wi labẹ ofin Niger, "ede Hausa ni ede ajọlo orilẹede yii, awọn ti a o maa lo lagbo iṣẹ ni ede Gẹẹsi ati Faranse."

Awọn ede mi-in ti wọn tun ka silẹ ni Zarma-Songhay, Fula, Kanuri, Gourmanche ati ede Larubawa.

Igbesẹ ede yii n waye lẹyin ipada apapọ ti wọn ṣe loṣu Keji ọdun yii.

Nibi ipade naa ni wọn ti fẹnu ko, pe ki Abdourahamane Tchiani, ṣọja to lewaju iditẹ gbajọba Niger, maa ba iṣẹ rẹ lọ titi di 2030.

Ìdí tí wọ́n fi sọ Hausa di èdè àjùmọ̀lò

Aworan awọn to gun ẹṣin pẹlu lawani lori

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣaaju ki wọn too ṣe ikede yii ni Hausa ti jẹ ede ti ọpọ eeyan n sọ ni Niger, Paapaa lawọn agbegbe bii Zinder, Maradi ati Tahou.

"O ju ida aadọrun-un (90%) eeyan lọ to n sọ ede Hausa ni Niger, ninu eeyan miliọnu mẹrindinlọgbọn to wa nibẹ.

"Fun idi eyi, ẹ ko le fi we ede Faranse to jẹ pe miliọnu mẹta eeyan pere lo n sọ ọ."

Tahir Guimba, oṣiṣẹ ijọba kan ni Niger lo ṣalaye bẹẹ.

O fi kun un pe ede Hausa ti kuro lede ẹka kan, o ti di ti okoowo, karakata ati ẹsin.

Bakan naa ni Ọjọgbọn Abdou Majingini, onimọ nipa ede to n gbe ni olu ilu Niger, ṣalaye pe, "ikede yii tubọ fidi ẹ mulẹ, pe ede apapọ ni Hausa, ide iṣọkan si ni pẹlu, nitori o fẹrẹ jẹ pe gbogbo eeyan lo n sọ ọ. "

Ọjọgbọn Abdou to kọ iwe atumọ ede lati Faranse si Hausa (French-Hausa dictionary), sọ pe o yẹ ki ede Hausa wa lara awọn ede meji yooku ti wọn kede bii ede iṣẹ.

O lo yẹ ki wọn fi Hausa kun ede Gẹẹsi ati Faranse ni.

Àlàyé ìjọba ológun lórí i rẹ̀

Ijọba ologun ilẹ Niger ṣalaye pe awọn ṣe ipinnu lati fi ede Gẹẹsi ati Faranse ṣe ede ibi iṣẹ, ti Hausa si di ajọlo, kawọn le fi ya ara awọn sọtọ lọwọọ France.

Wọn ni awọn gbe igbesẹ naa lati yago fun France, lẹyin ti iditẹ gbajọba waye tawọn si le Mohamed Bazoum, aarẹ alagbada to n dari Niger tẹlẹ lọ.

Yatọ si afikun ede, orilẹede Niger tun gbe igbesẹ aabo to yatọ si ohun ti wọn n ba bọ tẹlẹ.

Wọn le awọn ọmọ ogun Faranse danu, wọn dẹkun ajọṣepọ to wa nilẹ, wọn si paarọ awọn orukọ adugbo to ti pẹ ti wọn fi n ṣeranti awọn Faranse tẹlẹ

Ṣaaju ni wọn ti kede pe awọn ko si lara orilẹede Francophone ti Faranse n dari mọ, gẹgẹ bii awọn ọrẹ awọn tuntun ti i ṣe Mali ati Burkina Faso.