Ṣó o láyà? Ẹ wo bí àgbà òṣèré, Amina Eleha ṣe fakọyọ sí nínú ìmọ̀ Yorùbá

Àkọlé fídíò,
Ṣó o láyà? Ẹ wo bí àgbà òṣèré, Amina Eleha ṣe fakọyọ sí nínú ìmọ̀ Yorùbá

Gbajumọ oṣerebinrin, Adebukola Mosoba, ti ọpọ tun mọ si Amina Eleha, kopa ninu eto Ṣo o laye lori BBC.

Eto Ṣo o laya ni awọn oṣere ati olorin, ti ma n fi bi wọn ṣe ni imọ nipa ede Yoruba - owe, aṣa, gbolohun, itan, ati bẹẹbẹẹ lọ.

Arabinrin Amina Eleha dahun ọpọ ibeere ni abala yii, ẹ wo bo ṣe fakọyọ si.

Taa ni Amina Eleha?

Amina Eleha

Amina Eleha ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC lọdun 2024, sọ pe nigba ti wọn yẹ akọsẹjaye oun wo ni wọn sọ pe aburo baba oun lo gbọdọ tọ oun dagba.

Agba oṣere naa ṣalaye pe gẹgẹ bi ẹni ti wọn bi si ile ọba, o di dandan ki wọn yẹ akọsẹjaye gbogbo ọmọ ti wọn ba wo, kii ba jẹ musulumi tabi ẹlẹsin Kristẹni.

"Lati igba ti mo ti wa nile ẹkọ alakọbẹrẹ ni mo ti bẹrẹ iṣẹ tiata niluu Eko.

Koda, bi a ti n kọ iṣẹ tiata nigba naa ni a tun n kọ ẹṣẹ jija.

Awọn oṣere bii Madam Sajẹ ati Baba Suwe to ti dero ọrun lonii ni a jọ kọ ẹṣẹ jija.

Baba ko kọkọ gba ki n ṣiṣẹ tiata tori o ni ọmọ ọba ni mi, ati pe ọmọ ọba kii ṣẹru.

Baba mi sọ pe iṣẹ ẹru n'isẹ tiata."