Ǹjẹ́ irun orí rẹ n rejẹ, tàbí o ti n pá lórí láì tíì di arúgbó? Wo ọ̀nà àbáyọ

Ọkunrin apari

Oríṣun àwòrán, Bandile

    • Author, Ameer Ahmed
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ki irun maa ja le ṣẹlẹ si ẹnikẹni, ko kan ọjọ ori, boya ọkunrin tabi obinrin ni eeyan, bẹẹ ni ko kan ẹya ti eeyan jẹ pẹlu.

Ọlọkan -o-jọkan idi lo wa ti eeyan le maa fi padanu irun rẹ, o le jẹ ajẹbi, ailera kan, agba ara tabi iru igbesi aye ti eeyan n gbe.

Lati mọ awọn ohun to n fa ki irun maa re lori, BBC ba onimọ nipa irun, Enitan Agidee, to fi orilẹede UK ṣebugbe, sọrọ.

Ọpọ irun ni Agidee ti yẹwo fawọn eeyan, paapaa julọ, awọn obinrin to ni ẹya irun ti a mọ si Afro.

"Ko ṣeni ti irun jija yọ silẹ, koda emi gan-an ti mo mọ pupọ nipa irun ti koju irun jija ri nigba kan."

Agidee lo sọ bẹẹ.

Iwe atigbadegba ti wọn n ṣe ni US nipa itọju irun, awọ ara ati eekanna, ṣalaye pe 16% ọkunrin ti ọjọ ori won wa laaarin mejidinlogun si mọkandinlọgbọn (18-29) ni wọn maa n ni iriri irun to n ja.

Wọn ni o maa n goke si ilọpo ọgbọn (30% ) laaarin awọn ti ọjọ ori wọn wa ni ọgbọn si mọkandinlogoji (30-39).

Ìdajì ọkunrin ti ọjọ ori wọn wa laaarin ogoji si mọkandinlaadọta ( 40-49) ni wọn ni wọn maa n padanu irun ori wọn.

ki irun maa re danu ni awọn dokita n pe ni Alopecia, wọn ni awọn ọkunrin lo maa n karamaasiki rẹ ju awọn obinrin ti ori i wọn n rẹ lọ..

Gẹgẹ bi ileewe iṣegun oyinbo, Harvard Medical School, ṣe wi, o fẹrẹ to ida mẹta obinrin to maa n koju irun jija ati rire danu lasiko kan layee wọn.

Ǹjẹ́ ó ṣée ṣe láti dá irun ori rẹ pada bí o bá tètè mọ̀ pé ó ń re

Obinrin to n ṣerun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ti o ba ṣakiyesi pe irun ori rẹ n rejẹ, ohun akọkọ lati ṣe ni pe ki o lọ sọdọ awọn onimọ nipa irun, ki wọn si sọ pato ohun to n fa a.

Dokita Aanchal Panth, onimọ nipa irun lo ṣalaye yii.

"Ounjẹ to ni eroja protein pupọ ninu, daa fun ki irun le maa hu daadaa. Bi eroja kan ba wa ti ko pe ninu ara latari ounjẹ ti a n jẹ, iyẹn lo yẹ ki eeyan kọkọ tọju na."

Ọpọ eeyan lo jẹ pe wọn maa n sare lọọ po awọn iparun onikẹmika oriṣiiriṣii pọ ti wọn ba ti ri i pe irun ori wọn n re danu. Awọn nnkan iparun onikẹmika bii Minoxidil abi awọn mi-in to ni caffeine ninu.

Bẹẹ eroja Minoxidil, wọn maa n lo o bii omi tabi ki wọn ṣe e ko dabii ọsẹ ni.

Iwadii fi han pe o maa n jẹ ki ẹjẹ to n lọ si isalẹ irun pọ ko le ba gun ko si pọ.

Ṣugbọn Dokita Panth kilọ, pe Minoxidil ko ni i jẹ ki irun ri herehere loootọ, ṣugbọn ko ni i jẹ ki irun tuntun hu lori pẹlu.

Eroja kan naa wa ti a mọ si ketoconazole, to wa fun awọn ọkunrin lati koju ori fifajẹ.

Awọn onimọ sọ pe o daa lati fi ṣetọju eṣiṣi, nitori bi eṣiṣi naa ba kari ori tan, o le mu ki irun rirejẹ buru si i.

Yatọ si Minoxidil, Ketoconazole ni tiẹ jẹ oogun apakokoro ti wọn maa n lo fun itọju kokoro fungai, eyi to maa n wa nisalẹ ori. Awọn iṣẹ iwadii kan tilẹ sọ pe ketoconazole le jẹ ki irun rire dinku.

"Ọpọ eeyan ro pe irun rirejẹ jẹ nnkan ti eeyan le gba itọju fun, ti irun naa yoo si hu pada lai jẹ pe eeyan tun ṣe nnkan kan si i mọ, ko ri bẹẹ.

Bi eeyan yoo ba da irun to re pada, ohun ti eeyan gbọdọ kọju si gbere ni."

Dokita Panth lo ṣalaye bẹẹ.

Ó ṣe pàtàkì láti mọ irú irun tí o ní

Aworan obinrin ti obinrin mi-in n ṣerun fun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹkọ nipa iru irun ti eeyan ni lori ṣe pataki pupọ.

Onimọ nipa irun, Agidee to maa n ri si ẹya irun Afro, ṣalaye pe awọn irun to ba le, awọn irun to wuwo lori ati ti ooru ba n mu ori le jẹ ki irun ori maa re danu.

" O ṣe pataki lati nimọ nipa iru irun to o fẹẹ ṣe. Gbadun irun rẹ, ṣugbọn o gbọdọ mọ asiko to yẹ ko o ṣerun to wuwo sori, ati eyi to fuyẹ. Eyi nipa to maa ko lara ibi ti irun ti n hu gan-an"

Enitan Agidee lo ṣalaye bẹẹ.

O ni bi agbara ibi ti irun ti n hu ba ṣe pọ to ni irun yoo ṣe hu lori to, oun naa lo si tun n ṣiṣẹ fun egbo ori.

"Mo ti ri awọn onibaara ti irun wọn n reje nitori idi meji to ni i ṣe pẹlu alopecia ati eyi to jẹ iru irun ti wọn ṣe lo fa a ti irun wọn fi n rejẹ"

Awọn nnkan mi-in ti wọn lo tun n ṣakoba fun irun rirejẹ ni ọti mimu, wahala aṣeju ati aisun.

Dokita Panth sọ pe siga mimu maa n fa ailera kan ti a mọ si 'vasoconstriction', eyi to maa n din bi ẹjẹ ṣe n lọ sinu awọn ẹya ara ku, eyi si le ṣẹlẹ si awọ ori rẹ naa.

Ai ki i fọ isalẹ orii rẹ deede naa le fa ki irun rẹ maa ja, o le ṣakiesi eyi bi o ko ba ki n lo ọṣẹ 'shampoo' lati fọ irun rẹ, wa a ri i pe awọn irun ṣaa n ja nigba ti o ba n wẹ.

Dokita Panth gba awọn eeyan nimọran pe: "Tiwọ ba jẹ ẹnikan to ni awọ ori to maa n yọ bọlọ, ti ki i gbẹ, o lee maa fọ irun rẹ lojoojumọ abi ki o maa fi ọjọ diẹ silẹ lati fọ ọ."

To ba jẹ pe awọ ori to ṣe rẹgi lo ni, Dokita Panth sọ pe o yẹ ki o maa fọ irun rẹ, o kere tan, igba mẹta laaarin ọsẹ kan.

Ṣé iṣẹ́ abẹ irun nìkan ni ọ̀nà àbáyọ tó rọrùn jù ni?

Aworan ori ọkunrin kan lẹyin to ṣiṣẹ abẹ irun tan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ileeṣẹ to n ri si ilera awọn to n rin irin ajo afẹ ni Turkey, sọ pe o fẹrẹ to miliọnu kan eeyan to ṣabẹwo si orilẹede naa lati ṣiṣẹ abẹ irun

Iṣẹ abẹ irun jẹ ilana iṣaraloge kan to nilo ki wọn lo abẹ, awọn eeyan maa n ṣe e lati dun un wo, ki wọn si le nigboya lati wọ ibikibi lawujọ.

Yatọ si pe o wọn, iṣẹ abẹ irun tun gbajumọ nitori o le jẹ ki eeyan rẹwa si i gan-an, gẹgẹ bi Dokita Panth ṣe sọ.

Ṣugbọn, o ni ohun ti ko ye eeyan nibẹ ni pe ti eeyan ba fi itọju to yẹ ko maa fun irun rẹ silẹ lẹyin iṣẹ abẹ yii, o ṣee ṣe ki irun naa bẹrẹ si i ja pada leyin ọdun marun-un si mẹfa.

O ni o ṣee ṣe ki gbogbo irun ori ẹni naa re tan pata, ko jẹ eyi to fi owo ṣe ni yoo ṣeku fun un.

Onimọ nipa irun, Enitan Agidee, naa sọ pe iṣẹ abẹ irun ko gbọdọ jẹ ohun ti eeyan yoo ṣaa fẹẹ ṣe dandan.

O ni ti ko ba si ọna miran mọ lo ku, iyẹn si kọ ni yoo tan iṣoro irun fifajẹ kaluku, nitori ọtọọtọ ni idi ti irun wọn fi rejẹ lati ibẹrẹ.

"Bii ẹni ti otutu n mu to wọ ẹwu awọtẹlẹ to si n jade lọ ni iṣẹ abẹ irun, nigba ti ki i ṣe pe o fi nnkan mi tẹnu ju aṣọ otutu naa lọ, bo pẹ boya, otutu yoo pada mu un naa ni."

Enitan lo ṣalaye bẹẹ.