Njẹ́ ẹ ti gbọ́ nípa Owu-Kuta nípìnlẹ̀ Osun, níbi tó ti jẹ́ èèwọ̀ láti ta iyán àti ẹ̀pà

Àkọlé fídíò,
Njẹ́ ẹ ti gbọ́ nípa Owu-Kuta nípìnlẹ̀ Osun, níbi tó ti jẹ́ èèwọ̀ láti ta iyán àti ẹ̀pà

Idalu , niṣeluu, gẹgẹ bi Yoruba ṣe ma n sọ. Ba si ṣe n ṣe nilẹ kan, eewọ ni ni ilẹ ibomiran.

Eyi lo difa fun ilu kan ti wọn n pe ni Owu Kuta, nibi to ti jẹ eewọ ni lati gun iyán ta, tabi ta ẹpa.

Ijọba ibilẹ Aiyedire nipinlẹ Osun ni Owu-Kuta wa, ko si fi bẹẹ jina si ilu Iwo.

BBC Yoruba ṣe abẹwo si ilu naa, lati wadii ti wọn ko fi gbọdọ ta iyan, tabi ẹpa nibẹ.

Ninu iwadii naa, lo ti han pe wọn le gun iyan jẹ ninu ile wọn, ṣugbọn wọn ko gbọdọ ta a .

Ẹnikan lara awọn agba ilu Kuta to ba BBC sọrọ, Ọmọọba Segun Adeigbe, ṣalaye pe awọn to huwa tako eewọ naa nigba kan, "gbogbo idile naa lo parun".

"Nigba ti awọn ẹsin igbalode bẹrẹ, awọn kang be igbesẹ lati kọlu eewọ yii, nitori wọn gbagbọ pe ko si nnkan ti yoo ṣẹlẹ si wọn."

Amọ, ki gan-an lo pilẹ eewọ yii, nitori pe ounjẹ to gbajumọ nilẹ Yoruba ni iyan ati ẹpa, to si jẹ pe o wa lara awọn nnkan ti awọn kan fi n ṣe ọrọ aje wọn ni awọn ibi kan.

Iyan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kini idi ti wọn ko fi gbọdọ ta iyan ati ẹpa ni Owu-Kuta?

Ninu ọrọ rẹ, Ọmọọba Segun Adeigbe ṣalaye pe ọrọ naa bẹrẹ ni igba atijọ, nigba ti Ajibosin, to jẹ ọmọ Oduduwa nile Ifẹ, bẹrẹ si ni sunkun gba ade.

Ọmọ Oduduwa ni Ajibosin jẹ, "o si jẹ ọmọ ti baba rẹ fẹran lati ma a gbe mọra.

"Lọjọ kan ti baba rẹ gbe e mọra, lo bẹrẹ si ni fi Ade Aarr ti baba rẹ de sori ṣere. Lati ibẹ lo ti di pe ti wọn ko ba de ade naa fun, ẹkun ni yoo ma a sun."

Ọmọọba Adeigbe fi kun ọrọ rẹ pe, itan sọ pe ihuwasi ọmọ naa lo mu ki awọn obi rẹ o pinnu lati wo akọsẹjare rẹ.

Ninu iwadii wọn ni wọn ti mọ pe o wa ninu akọsẹjare Ajibosin lati di ọba.

"Ko ṣe e ṣe ki ọba meji o ma a de ade ninu ilu kan naa, eyi si lo mu ki wọn o tẹ ilu tuntun do fun Ajibosin."

Jagunjagun ni Akindele, to tun n jẹ Ajibosin, nigba aye rẹ, yatọ si pe o jẹ ọba.

Nigba ti Akindele dagba, o waja. Ṣugbọn ko to o di pe o waja, o sọ fun awọn ọmọ rẹ pe nigbakugba ti ilu Kuta b awa ninu iyọnu tabi ogun, ki wọn o pe ohun.

"O kọ wọn bi wọn o ṣe ma a pe e."

Ilu Kuta

Lẹyin asiko diẹ to wọ ilẹ, awọn ọmọ rẹ dẹjaa lọjọ kan, lati dan baba wọn wo boya loootọ ni oku rẹ yoo dide lati gbeja wọn.

"Bi wọn ṣe pe e, o jade pẹlu ẹṣin rẹ ati ida lọwọ.

"Bo ṣe jade lo n sare lọ si inu ilu, to si n fi ida ọwọ rẹ bẹ ori gbogbo awọn to ba ti pade loju ọna."

Itan lati ẹnu Ọmọọba Segun Adeigbe fidi rẹ mulẹ pe, bo ṣe de aarin ilu, ni ẹṣin rẹ deede yọ ṣubu.

"Bo ṣe n sare lọ, ko mọ pe iya kan to ma n ta iyan ninu ilu, ti da eepo iṣu to bẹ si aarin ọna. Eepo iṣu naa lo si yọ ọ ṣubu.

Akindele pada dide, amọ ko pẹ to sare siwaju diẹ, lo tun yọ ṣubu. Nigba ti yoo tun wo ilẹ, o ri i pe eepo ẹpa ti obinrin kan to n yan ẹpa ta lo da eepo naa si aarin ọna.

Awọn nnkan to ṣẹlẹ yii lo mu ko fura pe, o ṣe e ṣe ko jẹ ikilọ.

Eyi mu ko dẹsẹ duro diẹ, to si wa a ri pe, awọn ọmọ rẹ lo ti n bẹ lori lati igba to ti wọ inu ilu.

Iṣẹlẹ si lo mu ko kilọ fun awọn ọmọ rẹ pe, o ti di eewọ fun ẹnikẹni lati maa gun iyan ta, tabi ta ẹpa niluu Kuta.

Titi di oni, ko si ile ounjẹ ti ẹ le de niluu Owu-Kuta, ti ẹ ti le ri iyan ra.

Bakan naa ni wọn kii ta ẹpa nibẹ.

Eyi ko tumọ si pe wọn ko le jẹ awọn ounjẹ mejeeji. Wọn n gbin iṣu, amọ wọn kii gbin ẹpa.

Ọmọọba Adeigbe ti ẹ sọ fun BBC pe, bi igba ti eeyan gbe ọmọ sin ni fun ẹni to ba gbin ẹpa.

Awọn ọmọ ilu Kuta le ra ẹpa lati ibomiran, amọ ko si fun tita ninu ilu wọn.