Ohun tí a mọ̀ nípa obìnrin tí táǹkì omi wó pa ní Lekki lásìkò tó ń sùn lọ́wọ́ rèé

Oríṣun àwòrán, Cynthia Chizoba Oguzie/family
Gbogbo wa ni a fẹ isinmi lẹyin ti a ba pari iṣẹ, eyi si ni Cynthia Chizoba Ohuzie naa gbero lati ṣe ko to di pe o pade iku ojiji .
Iroyin to tẹ wa lọwọ ni tanka omi meji to wa ni ori aja ile ti Cynthia n gbe lo ṣadede dawo, to si wo sinu yara ọdọmọbinrin naa, eyi to si wo paa.
Iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Chevron Estate ni Lekki nipinlẹ Eko lọjọ Kejidinlogun ọdun 2025.
Ọmọ ọgbọn ọdun ni oloogbe naa, to si n ṣe isowo aṣọ tita.
Ọmọ meji ni oloogbe naa fi silẹ laye.
Ẹgbọn oloogbe, Ifeanyi Oguzie sọ fun BBC pe pe iku aburo oun jẹ ohun to buru jai, to si tun ba ni lọkan jẹ pupọ. O ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii ohun to ba mọlẹbi lọkan jẹ.
"Ohun to dun wa ju ni pe eeyan to ni ile naa ti iṣẹlẹ naa ti waye ko fi igba kankan kan si mọlẹbi lẹyin iṣẹlẹ naa.
"Lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye, onile ko fi igba kankan pe mọlẹbi lori ohun to sẹlẹ."
"Nigba ti a bere pe nibo onile naa, wọn ni o wa ni oke okun
"Onile naa ko mọ ipo ti ile naa wa ṣugbọn eeyan to n ba mojuto ile mọ ohun to n sẹlẹ
Ki ni iṣẹlẹ ọlọpaa sọ lori iṣẹlẹ yii?
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ni mọlẹbi oloogbe ko fi iṣẹlẹ to ileeṣẹ ọlọpaa leti.
Nigba ti BBC kan si Hundeyin, o ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ko mọ ohunkohun nipinlẹ iṣẹlẹ ti wọn ko si le gbe igbesẹ kankan.















