Wo àwọn ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn ti pàdánù ẹ̀mí wọn jùlọ lọ́dún 2025 yìí ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, Facebook/Multiple
Ipaniyan ati jiji eeyan gbe pawo si n ṣẹlẹ lawọn ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria pẹlu eto abo to mẹhẹ.
Abọ ajọ kan ti wọn n pe ni Beacon Security Intelligence ti fidi rẹ mulẹ pe iṣẹlẹ ipaniyan pọ si loṣu mẹta akọkọ ninu ọdun 2025 yii ju oṣu mẹta to kẹyin ọdun 2024 to kọja lọ.
Iwadii naa fi han pe eeyan 3,610 lawọn janduku agbebọn pa laarin oṣu Kinni si oṣu Kẹta ọdun 2025 yii, eyi to ju iye awọn to ku ninu oṣu Kẹwaa si ikọkanla ọdun 2024 to kọja lọ.
Adari ajọ naa to ba BBC sọrọ ṣalaye pe awọn eeyan ti Boko Haram, Lakurawa ati ẹgbẹ agbesunmọmi ISWAP pa lẹkun ila oorun ariwa Naijiria ti pọ si.
Wọnyi lawọn ipinlẹ tawọn janduku agbebọn ti pa eeyan julọ ni 2025:
Ipinlẹ Niger: Wọn ṣeku pa eeyan 631, wọn ji 251 gbe lọ ninu ikọlu 178 to waye ni ipinlẹ naa.
Zamfara: Eeyan 585 lo ti ku ni Zamfara lọdun yii, wọn si ti ji eeyan 918 gbe lọ ninu ikọlu 250 to waye nibẹ.
Borno: Eeyan 514 ti padanu ẹmi wọn, wọn ti ji eeyan 357 gbe lọ ninu ikọlu 397 to waye nipinlẹ naa.
Katsina: Eeyan 341 ti dero ọrun, 495 bọ sọwọ awọn ajinigbe ninu ikọlu 247 to waye.
Kaduna: 106 lawọn eeyan ti wọn ti padanu ẹmi wọn lọdun yii nipinlẹ Kaduna, nigba ti awọn janduku agbebọn ti ṣe ikọlu nibẹ ni igba 128.
Eeyan mẹtalelaadọrun lo ti padanu ẹmi wọn bakan naa nipinlẹ Sokoto ninu ọdun yii, nigba ti mọkanlalelaadọrun ti ku ni Kebi.
Ipaniyan rẹpẹtẹ ninu oṣu Kẹta

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iwadii ajọ Beacon Security Intelligence ṣalaye pe ipinlẹ Niger ni iṣẹlẹ ipaniyan ti pọ julọ loṣu kẹta ọdun yii.
Abọ iwadii ajọ naa fidi rẹ mulẹ pe eeyan 368 lo padanu ẹmi won nipinlẹ Niger nikan loṣu Kẹta.
Eleyii ju eeyan 121 to ku ninu oṣu Keji to ṣaaju.
Ipinlẹ Zamfara ti eeyan 179 ti padanu ẹmi wọn lo ṣe ipo keji, nigba ti Borno w ani ipo kẹta nibi ti eeyan 151 ti dero ọrun.
Idi ti eto abo fi n mẹhẹ si i Naijiria
Ajọ naa sọ ninu abọ iwadii wọn pe ipadabọ awọn ẹgbẹ agbesunmọmi bii Boko Haram ati Lakurawa to ṣẹṣẹ bẹrẹ si ni ṣọṣẹ wa lara idi ti eto abo fi n buru si i.
Ajọ naa tun sọ pe awọn oloṣelu ti bẹrẹ imurasilẹ fun eto idibo gbogbogbo ọdun 2027 eyi to n fa hila-hilo kaakiri Naijiria bi nnkan to n ṣẹlẹ nipinlẹ Rivers lọwọ yii nibi ti Aarẹ Bola Tinubu ti kede ilu o fara rọ ti o si ni ki gomina ipinlẹ naa lọ rọkun nle.
Ija agbegbe si agbegbe naa wa lara nnkan to n jẹ ki eto abo maa mẹhẹ si i ni Naijiria gẹgẹ bi o ti n ṣẹlẹ nipinlẹ Osun.
Bakan naa ni ajọ Beacon Security Intelligence sọ pe ifẹhonuhan to n ṣẹlẹ kaakiri Naijiria naa n ṣakoba fun eto abo.
Idi ti Boko Haram fi n lagbara si i
Adari ajọ Beacon Security Intelligence sọ idi meji ti Boko Haram fi n lagbara si i ni Naijiria.
O ni akọkọ ni pe nigba kugba ti ISWAP ba kede ikọlu ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa maa n ri pe awọn ṣe ikọlu ọhun.
Adari ajọ naa tun sọ pe ileeṣẹ ologun Naijiria ko duro si ẹkun iwọ oorun ariwa Naijiria nikan mọ lati maa koju awọn agbesunmọmi.
O ni awọn ọmogun Naijiria ti n doju kọ awọn janduku agbebọn ni ẹkun ila oorun ariwa bakan naa bayii.















