Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Ọlọpaa kan ti dero atimọle nipinlẹ Ekiti lẹyin to gun araalu lọbẹ nitori ọrọ obinrin

Eyii lo wa waye lẹyin ti omidan kan, Priscillia Jerome, ke gbajare lori ayelujara pe

Ọlọpaa naa gun baba oun lọbẹ latari ija kan to waye laarin ọrẹbinrin rẹ ati aburo oun ọkunrin

Ẹkunrẹrẹ wa loju opo BBC Yoruba

____________

Ajọ to n mojuto igbohunsafẹfẹ ni Naijiria, NBC, ti fofin de awọn ileeṣẹ redio ati tẹlifisan ni Naijiria

Pe wọn ko gbọdọ gbe orin "Tell Your Papa", ti ogbatarigi akọrin takasufe, Eedris Abdulkareem, gbe sita lori afẹfẹ

NBC sọ pe orin naa tako abala ofin to rọ mọ igbohunsafẹfẹ ni Naijiria

Ki lo wa ninu orin naa gan ti ijọba fi gbẹsẹ le?

Oun bi mi, ta ni ki n bi?

____________

Ijọba apapọ ti kede pe, ojo nlanla yoo rọ, omiyale yoo si ṣẹlẹ ni ipinlẹ ọgbọn, to fi mọ ilu Abuja, lọdun 2025 yii

Minisita fun nnkan alumọni inu omi ati imọtoto, Joseph Utsev, lo fi iroyin naa sita

O ni ọrọ naa yoo kan ipinlẹ Eko, Ogun, Ondo, Osun, Oyo

Awọn ipinlẹ to ku nkọ?