Ọlọ́pàá gún bàbá àgbàlagbà lọ́bẹẹ nítorí obìnrin l'Ekiti, ẹbí rẹ̀ n ké tantan fún ìdájọ́ lórí ayélujára

 Priscillia Jerome

Oríṣun àwòrán, Priscillia Jerome/NPF

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti kede pe oun ti fi ṣikun ofin mu ọkan lara awọn oṣiṣẹ rẹ to gun araalu kan lọbẹ.

Igbesẹ naa lo wa waye lẹyin ti ọdọbinrin kan, Priscillia Jerome, ke gbajare lori ayelujara pe ọlọpaa ọhun, ti ko fi orukọ rẹ lede, gun baba oun lọbẹ latari ija kan to waye laarin ọrẹbinrin ọlọpaa naa ati aburo oun ọkunrin.

Ọdọbinrin naa ni "Ise Orun ni a wa yii, wọn ni ko si ohun ti yoo ṣẹlẹ nitori a jẹ alejo, amọ mi o ni dakẹ.

"O lọ fi ọbẹ gun baba mi lana nitori pe ọrẹbinrin rẹ ba aburo mi ja."

Ninu fidio to fi lede loju opo Tiktok rẹ, Priscillia ṣalaye pe aburo oun ọkunrin lo ni ija kekere kan pẹlu obinrin kan to jẹ ọrẹbinrin ọlọpaa naa, eyii to mu ki obinrin ọhun lọ fi ọrọ naa to ọlọpaa naa to jẹ ọrẹkunrin rẹ leti."

O ni ọlọpaa na wa si ile awọn lati fi panpẹ ofin gbe aburo oun ṣugbọn ẹgbọn rẹ ọkunrin mii ni wọn ba latari pe aburo oun ko si nile.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, wọn gbiyanju lati fi ofin gbe ẹgbọn oun naa ṣugbọn o kọ jalẹ, o si bẹrẹ si n ke pe baba wọn pe awọn kan n lu oun.

O ni bi baba wọn ṣe jade lati da si ọrọ naa lati mọ eredi ti wọn fi n na ọmọ oun ni ọkan ninu awọn alejo naa yọ ọbẹ, to si gun baba oun.

Priscillia sọ pe ọbẹ naa tun ge ọwọ baba oun lasiko to n gbiyaju lati daabo bo ara rẹ.

Ọdọbnrin naa ni "Bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, ọlọpaa ni ẹni to gun baba mi lọbẹ yii.

"Bi mo ṣe n sọrọ yii, ati awọn to na baba mi ati ọlọpaa to gun lọbẹ, wọn si n rin kiri lai si ibawi kankan fun wọn, wọn ni wọn ko le fi jofin nitori pe o jẹ ọlọpaa."

A ti mu afurasi naa, iwadii si ti bẹrẹ - Ọlọpaa Ekiti

Ẹwẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu sọ ninu atẹjade kan pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa nipinlẹ Ekiti ti ri fidio ẹsun ti Priscillia fi kan ọkan lara wọn, wọn si ti gbe igbesẹ lori rẹ.

Abutu sọ pe "Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Jospeh Eribo, ti paṣẹ ki wọn tare ẹjọ naa si ẹka CID, ki wọn si ri pe iwadii to peye waye lori rẹ.

"Ẹwẹ, ọlọpaa ti wọn fẹsun kan ti wa ni ahamọ fun iwadii kikun atawọn ohun mii to kan."

Lẹyin naa lo ke si gbogbo awọn ti ọrọ kan, paapaa mọlẹbi ẹni ti wọn gun lọbẹ ki wọn fi iye denu titi ti iwadii yoo fi pari lori ẹsun naa.