Ṣé lóòótọ́ ni ìgbéyàwó Barack àti Michelle Obama ti túká?

Barack ati Michelle Obama

Oríṣun àwòrán, Barack Obama

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lati bi ọjọ diẹ sẹyin, ni iroyin ti n lọ kaakiri ori ayelujara, paapaa nilẹ America, pe o ṣe e ṣe ki igbeyawo aarẹ orilẹede naa nigba kan, Barack Obama ati iyawo rẹ, Michelle, ti tuka.

Eyi ni ko ṣẹyin bi awọn kan ṣe kiyesi pe, wọn ko ri tọkọtaya naa papọ ni awọn ipejọpọ kan ti wọn jọ maa n lọ tẹlẹ.

Iyawo Aarẹ Amẹrika tẹlẹ, Michelle Obama, ti kede pe ko si ootọ ninu iroyin to ni ija wa laarin oun ati ọkọ oun ati pe igbeyawo wọn ti fẹ tuka.

Eredi iroyin naa ko ṣẹyin bi obinrin ọhun ko ṣe tẹle ọkọ rẹ, Barack Obama lọ si awọn ode kan ti wọn jọ maa n lọ tẹlẹ.

Lara awọn ode ti awọn eeyan ko ti ri wọn pọ mọ to fa iroyin nipa ituka igbeyawo wọn ni iburawọle Aarẹ Donald Trump ati eto isinku Aarẹ tẹlẹ, Jimmy Carter.

Nigba to n sọrọ lori eto ifọrọwanilẹnuwo Work in Progress, Michelle Obama sọ pe oun ti ni anfaani bayii lati yan ibi ti oun fẹ lọ ati awọn ibi ti ko ba wu oun lati lọ.

O ni awọn eeyan ko gbagbọ pe awọn igbesẹ ti oun n gbe jẹ eyii to wu oun lati inu ọkan, kaka bẹẹ, wọn gbagbọ pe ipinya ti n waye laarin oun ati ọkọ oun.

Iyawo Aarẹ tẹlẹ naa fi kun pe, ọkan oun da oun lẹbi pe oun ko yọju si awọn ayẹyẹ kan.

O ni "ninu ọdun yii, awọn eeyan ko le gbagbọ pe mo gbe awọn igbesẹ kan to wu mi lati gbe ki wọn to maa sọ pe emi ati ọkọ mi fẹ tuka.

"Ṣe eeyan ko le gbe igbeṣe to wu u gẹgẹ bii obinrin mọ ni? Ṣugbọn ohun ti awọn eeyan n fi oju wa ri niyẹn.

"Mo yan lati ṣe ohun ti ọkan mi n fẹ, kii ṣe ohun ti awọn eeyan n fẹ ki n ṣe."

Bo tilẹ jẹ pe Michelle ni oun ti pese aye fun ara oun lati maa ṣe awọn nnkan to wu oun bayii, o ṣi maa n lọ si awọn ode kan nibi to ti maa n sọrọ ni gbagede.

Michelle ti ṣalaye ṣaaju nipa awọn idojukọ rẹ gẹgẹ bii iyawo Barack Obama ninu iwe rẹ to pe ni "Becoming."

Oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 ni tọkọtaya naa ṣe ajọdun ọdun kejilelọgbọn gẹgẹ bii tọkọtaya.

Lati ọdunmọdun ni igbeyawo Barrack ati Michelle, ti jẹ apẹẹrẹ ati awokọṣe fun awọn eeyan kan kaakiri agbaye.

Ọpọ lo ti ẹ ma n fi igbeyawo wọn tọrọ, nitori awọn aṣeyọri wọn lagbo oṣelu ati awọn ọna mii.