Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Rogbodiyan to n waye ninu ẹgbẹ oṣelu Labour ma tun ti gbọna mii yọ
Emi lo de? Ṣebi ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiri ti dajọa pe igun Lamidi Apapa ni ojulowo adari ẹgbẹ naa
Ootọ ni, amọ alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ, Joe Ajaero ti ke si awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ lati ya bo ọọfisi ẹgbẹ oṣelu ọhun kaakiri Naijiria
Hmmmmm
Lọ soju opo BBC Yoruba to ba fẹ mọ ẹkunrẹrẹ
_______________________
Inu ibẹrubojo lawọn eeyan ilu Òdìgbó, nipinlẹ Ondo wa bayii lẹyin ti wọn ṣadede ri oku eeyan mẹta to lefo lori omi lagbegbe wọn
Iroyin ni ko si ori lọrun awọn oku naa mọ, wọn si ti n jẹra
Awọn olugbe agbegbe naa sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ awọn agbenipa lo gbẹmi awọn eeyan naa ki wọn to sọ oku sinu odo
Ileesẹ ọlọppaa ni iwadii ti bẹrẹ
___________________
Lorilẹede Dominican Republic
O le lọgọrun eeyan to ti jade, ti aadọjọ mii tun farapa lẹyin ti ile ijo kan da wo nibẹ
Asiko ti awọn eeyan n ṣe faaji lọwọ ni orule ile ijo naa ya, to si bo awọn to wa ninu rẹ mọlẹ













