Ipa tí owó eporọ̀bì tó já wálẹ̀ lọ́jà àgbáyé yóò ní lórí ọrọ̀ ajé Naijiria àti aráàlú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Busayo James-Olufade
- Role, BBC News Yoruba
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Iye ti wọn n ta epo rọbi lọja agbaye ti ja walẹ pẹlu ida12% eyi to jẹ ki wọn maa ta agba epo kan ni $65.50 bayii.
Eleyii waye lẹyin ti Aarẹ Donald Trump ti orilẹede Amẹrica ṣe afikun owo ori tariifu ọja to n wọle si Amẹrica lati awọn orilẹede ilẹ okeere.
$70 ni agba epo kan tẹlẹ ki Trump to kede afikun owo ori tariifu tuntun.
Ṣaaju ni Aarẹ Bola Tinubu buwọlu eto iṣuna ọdun 2025 Naijiria pẹlu afojusun pe $75 ni agba epo kan.
Eleyii tumọ si pe ijọba orilẹede Naijiria ni lati wa ọna ti yoo fi di $10 to jẹ iyatọ laarin iye to wa ninu eto iṣuna ati iye ti wọn n ta agba epo kan lọja agbaye bayii.
Ọpọ ọmọ Naijiria lo maa ronu lori ipa ti adinku iye ti wọn n ta epo lọja agbaye le ni lori ọrọ aje Naijiria ati lori wọn gẹgẹ bii araalu.
Ipa ti owo epo to walẹ lọja agbaye le ni lori ọrọ aje Naijiria ati araalu
BBC Pidgin ṣe ifọrọwanilẹnuwo lori ọrọ yii pẹlu Ọjogbọn Isa Dandago, to jẹ olukọ ati onimọ nipa iṣiro owo ni ile-ẹkọ giga fasiti BUK niluu Kano.
Ọjọgbọn Dandago sọ pe bi owo epo ti walẹ lọja agbaye le ṣakoba fun ọro aje Naijiria papaa julọ nitori bi ijọba ṣe fi $75 ṣe owo agba epo kan ninu eto iṣuna ọdun 2025.
O ni awọn ọmọ Naijiria ni yoo fara kaasa tori adinku yoo ba owo ti yoo maa wọle fun ijọba.
O ni ijọba ko ni le nawo lori gbogbo nkan ti wọn fẹẹ ṣe mọ ti adinku ba ti ba owo to n wọle sapo ijọba.
Ọjọgbọn Dandago fikun ọro rẹ pe ijọba le ya owo lati fi di aye ti yoo yọ silẹ ninu owo to n wọle ki o maa ba ṣakoba nla fun ọrọ aje.
Ọjọgbọn Dandago ni ''ọpọ akanṣe iṣẹ ti ijọba fẹẹ ṣe tẹlẹ ni wọn ko le ṣe mọ, eyi tumọ si pe Naijiria maa Iati ya owo fun eto iṣejọba.''
O fikun ọrọ rẹ pe awọn orilẹede ilẹ okeere ti Trump ti gbe owo ori tariifu to gara le lori ti n wa awọn onibaara mii ti yoo maa bawọn ra epo.
Olukọ fasiti naa sọ pe eleyii yoo jẹ ki epo rọbi lu ọja pa, eyi to tumọ si pe iye ti wọn n ta epo yoo maa lọọlẹ si i.
Ki ni ọna abayọ fun ọrọ aje Naijiria lori owo epo to ja walẹ?
Ọjọgbọn Dandago sọ pe o yẹ ki ijọba orilẹede Naijiria wa ọna mii tabi ibomiran to le maa ta epo rọbi si yatọ si orilẹede Amẹrika nikan.
O ni ọpọ orilẹede ilẹ okeere lo wa ti wọn nilo epo rọbi.
Ọjọgbọn onimọ nipa ẹkọ iṣiro owo tun sọ pe o yẹ ki ijọba wa ọna ti o le maa fi ta awọn alumọni mii silẹ okeere yatọ si epo rọbi nikan.
Olukọ fasiti naa ni ijọba tun le mojuto ẹka eto ọgbin ki o si ri pe o n ta ere oko jade silẹ okeere.
''Ti a ko ba ri owo to pọ lori epo rọbi, a le maa ta awọn nnkan alumọni mii, a tun le rowo lori nnkan ọgbin atawọn nnkan ti a n ṣe ni Naijiria,'' Ọjọgbọn Dandago lo sọ bẹẹ.
O ni ko yẹ ki orilẹede Naijiria gbẹkẹ le epo rọbi nikan fun eto ọrọ aje rẹ nigba ti Eledua fi awọn nnkan alumọni mii jinki orilẹede naa.
Owo epo le walẹ laipẹ lẹyin ti ijọba ni ki Dangote maa fi naira ra epo rọbi lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn alagbata epo bẹntiroolu ti sọ pe adinku le ba iye ti araalu n ra jala epo bẹntiroolu kan ni Naijiria, lẹyin ti igbimọ alaṣẹ ijọba apapọ kede l'Ọjọru wi pe ki ileeṣẹ ifọporọbi Dangote atawọn ileeṣẹ ifọpo mii to wa Naijiria maa fi naira ra epo rọbi lọ.
Awọn alagbata epo ni o yẹ ki ileeṣẹ Dangote kede adinku iye ti wọn n ta epo fawọn alagbata epo bẹntiroolu titi ipari ọsẹ ti a wa yii.
Wọn ni o yẹ ki eyi le mu adinku ba iye tawọn eeyan n ra epo laipẹ ni Naijiria.
Ọgbẹni Chinedu Ukadike to jẹ akọwe ipolongo fẹgbẹ awọn alagbata epo bẹntiroolu, IPMAN, sọ pe idaniloju wa pe owo epo yoo walẹ laipẹ.
Amọ, Ọgbẹni Ukadike ṣalaye pe oun ko le sọ ni pato iye ti adinku naa yoo jẹ.
Ẹwẹ, akọwe iroyin ẹgbẹ awọn to ni ileeṣẹ ifọporọbi ni Naijiria, Eche Idoko, ti kepe ijọba lati jẹ ki awọn ileeṣẹ ifọporọbi mii naa lanfaani lati maa fi owo naira ra epo rọbi lati ọwọ NNPCL.
O ni eyi yoo tun jẹ ki ọrọ aje orilẹede Naijiria gbooro ati fẹsẹ mulẹ si i.
Nibi ipade to waye lanaa Ọjọru ọjọ kẹsan an oṣu Kẹrin yii ni ijọba ti kede pe ileeṣẹ ifọporọbi Dangote atawọn mii yoo maa lanfaani lati maa fi naira ra epo rọbi lọ.
Ti ẹ o ba gbagbe, oṣu Kẹwaa ọdun 2024 ni ileeṣẹ Dangote tọwọ bọwe adehun pẹlu NNPCL lati maa ta epo pẹlu owo naira fun un.
Ṣugbọn ni ibẹrẹ oṣu Kẹta to lọ ni NNPCL sọ pe adehun tawọn ṣe pẹlu Dangote ko ju oṣu mẹfa lọ.
Amọ, ijọba ti yi igbesẹ naa pada bayii lẹyin to paṣẹ pe ki Dangote ma fi naira ra epo rọbi lọ.















