Aráàlú sọ ìrírí wọn nípa àwọn tó ń fi POS gbowó lórúkọ ìjọba Ogun, lẹ́yìn tí BBC tú àṣírí wọn

Ọrọ ẹnikan ṣoṣo ti ko ba ni ẹri to daju ni aye le maa pe nirọ, ṣugbọn ọrọ to ba ṣoju ilu ko farasin rara ni.
Kete ti BBC Yoruba gbe iroyin awọn kan ti wọn pe ara wọn ni oṣiṣẹ to n pawo wọle fun ijọba ipinlẹ Ogun jade lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2025, niṣe ni awọn eeyan to ti ni iriri owo ti ko lakọsilẹ tawọn eeyan naa n gba bẹrẹ si i sọ iriri wọn lori ayelujara.
Ṣaaju ni ikọ naa ti wọn ni ijọba ibilẹ Ifo, nipinlẹ Ogun lawọn n ṣiṣẹ fun, ti kọkọ gbedidina fawọn oṣiṣẹ BBC lọsẹ meji sẹyin, lasiko tawọn akọroyin n ba iṣẹ wọn lọ lagbegbe Berger/ Ojodu Abiodun.
Iwe kan ti wọn pe ni JTB, ni wọn beere lọwọ awọn oṣiṣẹ BBC Yoruba, a ṣe bi wọn ṣe n beere lọwọ awọn eeyan gbogbo niyẹn.
Ẹgbẹrun lọna aadọrin (70,000) ni wọn ni ka san, wọn si pada gba ẹgbẹrun marundinlogoji naira (45,000).
A tun ba kọmiṣanna igbokegbodo ọkọ l'Ogun, Gbenga Dairo, sọrọ pẹlu.
Lo ba dohun ti araalu bẹrẹ si i sọ iriri wọn lọwọ awọn agbegidina ti wọn lawọn yoo lu oṣiṣẹ BBC bi ko ba fun awọn lowo.
Diẹ ninu ohun toju araalu ti ri lọwọ awọn ayederu oṣiṣẹ ijọba Ogun naa ree:
- SF Importa Adefeso Ola: Ọdaran lawọn eeyan yii, wọn ti ṣe bẹẹ fun tirela wa ri l'Ojodu Abiodun ti wọn si ni ka mu ẹgbẹrun lọna igba ataabọ wa (250,000). Nigbẹyin, ọdọ oniPOS ni wọn mu dẹrẹba ati maneja wa lọ, nibi ti wọn ti san to ẹgbẹrun lọna ọgọfa (120,000). Ijọba gbọdọ wa wọn jade, ki wọn mu wọn ki wọn si fi oju wọn han fun gbogbo awujọ.
- Faseyi Kehinde Ebenezer: Wọn koju mi wọn si fi ofin mu mi ni 2012, nitori mo kan fẹẹ gbe ẹgbọn mi lasan. 'Wọn mu mi lọ si ọfiisi wọn l'Ojodu Abiodun, wọn si jo taya ọkọ mi. Wọn fipa mu mi san ẹgbẹrun mẹwaa naira.
- Daniel Aralomo: Ilu Ifo ati ijoba Ibile Ifo ki i se ibi to rorun lati gbe, nitori pe orileede ibo miran yatọ si Naijiria ni wọn. Ifipa gba owo pọ lọdọ wọn... Mo ti ko si wọn lọwọ ri, wakati mẹrin ni mo lo nibẹ nigba ti mi o ri owo san.
- Kol Gold: Ẹ ma tan ara yin jẹ, ibi gbogbo ni wọn ti n huwa yii ni Naijiria. Awọn ọmọ ita tẹ ẹ dẹ ri yii n ṣiṣẹ fun ẹgbẹ oṣelu ni, ere tiwọn lẹyin idibo niyẹn.
''Ohun ti wọn fi n tọju wọn niyẹn, wọn o le le wọn kuro loju ọna laye. Awọn ọmọ kọmiṣanna, aarẹ, gomina ati sẹnetọ ti wọn lo lati ṣe magomago ibo ni.
- Paul Akanbi: Iru ohun ti wọn ṣe fun emi naa niyẹn. Wọn fi iyanjẹ gbowo lọwọ mi wọn ko si fun mi ni risiiti kankan fun un.
''Mo ṣi ranti ọkunrin to fo ori mọto mi kọja, ọkunrin pupa kan ni mo ba ni ọfiisi wọn lọjọ yẹn. Mo ṣepe fun un ki n too kuro nibẹ, mo si mọ pe epe naa ko ni i lọ lai ṣẹ.
- Hammed Qudus: Won ya werey gan ni local government oooo... Nitosi Ojodu Berger.. Wọn maa mu ẹ lati Long bridge lọ si ijọba ibilẹ
- Alidu Adebayọ: Wọn gba #80,000 lọwọ mi lọdun to kọja nigba ti mo padanu ẹgbọn mi ti wọn bi mi le, wọn ni mo gba ọna ti ko yẹ ki n gba.
''Wọn ko gbe ami kankan sita to n tọka ibi ti eeyan ko gbọdọ gba, wọn ko fun mi ni risiiti kankan fun owo ti mo san. Wọn ni onipos ninu ọfiisi wọn.
''Yoo dun mọ wa bi ẹ ba le ba wa dia si i.
''Iṣẹlẹ yii maa n saba wa ye ti eeyan ba n bọ lati Mowe, to fẹẹ gbabẹ de Berger.''
This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Facebook post
Aráàlú bu ẹnu àtẹ́ lu ọ̀rọ̀ tí Kọmíṣánnà ìgbòkegbodò ọkọ̀ Ogun sọ
Lati fidi ẹ mulẹ boya ijọba ipinlẹ Ogun lo ran awọn olowoo kọbẹ naa niṣẹ, a kan si kọmiṣanna Igbokegbodo ọkọ ipinlẹ naa, Onimọ-erọ Gbenga Dairo.
Ninu alaye to ṣe fun BBC ni pe ijọba Ogun ko mọ awọn ayederu oṣiṣẹ to n fi POS gbowo naa ri.
O ni oun maa n sọ fawọn eeyan pe ki wọn ya fọto ẹni to ba n da wọn duro, ki wọn mu orukọ rẹ wa, awọn yoo gbe igbesẹ lori rẹ.
Bakan naa lo ni ofin ko faaye gba ẹnikẹni lati tu nọmba ara ọkọ, tabi bẹ siwaju ọkọ ọlọkọ.
Onimọ-ẹrọ Dairo ni oun maa n sọ fawọn eeyan pe ti wọn ba ri wọn, ki wọn waa fi ẹjọ sun.
Dairo ni bo tilẹ jẹ pe oun paapaa maa n ri wọn nigba mi-in ti wọn yoo bẹ sori ọkọ, o loun maa n bẹ wọn pe ki wọn ma pa ara wọn ni.
Ọrọ yii ni ko ṣe rẹgi pẹlu awọn eeyan, ti wọn fi bẹrẹ si i sọ pe kọmiṣanna naa ko mọ iṣẹ rẹ niṣẹ.
Awọn mi-in sọ pe ṣe ki wọn maa waa fẹjọ sun ni yoo yanju iṣoro yii, tabi kijọba mu wọn ki wọn si le wọn danu nibi iṣẹ ti ko ba ofin mu ti wọn n ṣe.
Ọpọ eeyan lo ni ijọba Ogun n ṣagbodegba fawọn eeyan naa, ni ko jẹ ki wọn ti le wọn lati ọdun gbọọrọ.
Bakan naa ni ijọba ibilẹ Ifo naa ti fi atẹjade sita, eyi to n ṣalaye pe awọn ko mọ awọn ayederu oṣiṣẹ naa ri.
Wọn ni wọn ko ṣiṣẹ funjọba Ogun.
To ba ri bẹẹ, ki wọn lọọ fi ofin le wọn kuro nibẹ lawọn eeyan n wi, yatọ si iwe ti ko yi nnkan pada ti wọn gbe jade.
Ọpọ eeyan lo ni awọn fẹẹ ri opin iṣẹlẹ yii, ki BBC jẹ kawọn mọ, ibi ti ọrọ awọn JTB abi jibiti ni ọhun, yoo pari si.














