Kílódé tí iye àwọn tó ń gba ìdájọ́ ikú fi ń pọ̀ ní àgbáyé?

- Author, Swaminathan Natarajan
- Role, BBC World Service
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ajọ Amnesty International ti sọ pe iye eeyan ti ijọba yẹ igi fun lọ soke lọdun 2024.
Ninu atẹjade kan to fi lede nipa yiyẹ igi fun ni, apapọ eeyan 1,518 ni wọn yẹ igi fun lọdun to koja, eyii to le si ni ida 32% ju ti ọdun 2023 lọ.
Eyii n waye bo tilẹ jẹ pe pupọ orilẹede lo n wọgile idajọ iku nilẹ wọn.
Gẹgẹ bii Amnesty International ṣe sọ, ọdun 2024 ni wọn yẹ igi fun eeyan julọ lagbaye lati ọdun 2015, bo tilẹ jẹ pe iye orilẹede to n yẹ igi fun eeyan dinku lati mẹrindinlogun si marundinlogun.
Igbagbọ wa pe orilẹede China ni wọn ti yẹ igi fun eeyan julọ amọ ko si akọsilẹ iye eeyan ti wọn yẹ igi fun nibẹ.
Vietnam ati North Korea tun jẹ orilẹede meji mii ti igbagbọ wa pe awọn naa n yẹ igi fun eeyan daadaa amọ wọn kọ lati kede iye awọn ti wọn yẹ igi fun.
Iyẹgi fun to gbajumọ julọ
Orilẹede Iran lo n lewaju ninu awọn idajọ iku to gbajumọ julọ lagbaye.
Akọwe ajọ Amnesty International, Agnès Callamard sọ pe "Iran, Iraq ati Saudi Arabia ni wọn ti yẹ igi fun eeyan julọ lọdun to kọja, ida 91% awọn ti wọn yẹ igi fun lọdun naa lo waye nibẹ ninu eyii ti wọn ti tẹ ẹtọ ọmọniyan loju mọlẹ latari bi wọn ṣe n yẹ igi fun awọn eeyan lori ẹsun gbigbe oogun oloro.
Ni 2024, o kere tan eeyan 972 – ti 30 ninu wọn jẹ obinrin – ni wọn yẹ igi fun ni Iran.
Ni 2023, eeyan 853 ni wọn yẹ igi fun.
Awọn ajafẹtọ ọmọniyan nibẹ sọ pe o ri bẹẹ latari ija oṣelu to n waye lorilẹede ọhun.
Roya Boroumand, adari ajọ Aborrahman Boroumand Center for Human Rights ni Iran sọ pe "A ri pe iye awọn ti wọn n yẹ igi fun pọ si lẹyin ifẹhonuhan nla to n waye."
Boroumand tọka si obinrin mejila ti wọn yẹ igi fun lọdun 2023 ati marundinlọgbọn mii ti wọn yẹ igi fun lọdun 2022.
O sọ fun BBC pe lootọ ni pe awọn kan ninu wọ lo jẹbi ẹsun gbigbe egboogi oloro, wọn mọọmọ dojukọ awọn mii latari pe wọn n gbogun ti ijọba.
Saudi Arabia to fẹgbẹkegbẹ pẹlu Iran yẹ igi fun eeyan 345, Iraq yẹ igi fun 63.
Iran ati Somalia yẹ igi fun eeyan mẹrin-mẹrin ti ọjọ ori wọn ko tii to mejidinlogun.
Iran ati Afghanistan jẹ orilẹede meji ti wọn yẹ igi fun awọn eeyan ni ojukaye lọdun 2024.
Ẹgbẹgbẹrun idajọ iku
Onimọ nipa idajọ iku ninu ajọ Amnesty, Chiara Sangiorgio, sọ pe atẹjade awọn ko mẹnuba ẹgbẹgbẹrun awọn ti wọn yẹ igi fun ni China.
O ni "Aṣiri ilu wọn ni fi iye eeyan ti wọn yẹ igi fun ni pato ṣe amọ iwadii wa fi han pe iye eeyan naa pọ jọjọ."
Amnesty gbagbọ pe China n dajọ iku fun awọn eeyan lori ẹsun lilu owo ilu ni ponpo ati gbigbe oogun oloro eyii to lodi si alakalẹ ajọ United Nations to sọ pe awọn ẹsun to buru jai nikan ni ijiya rẹ gbọdọ jẹ idajọ iku.
UN ni awọn ẹsun ti ko ba ni ṣekupa ẹlomiran taara bii ẹsun gbigbe egboogi oloro ati ẹsun ibanilopọ ko tọ si idajọ iku.
O ti pẹ ti China ti n lo idajọ iku fun eeyan. Ni 1983, o kede awọn idajọ kan to le koko fun awọn ọdaran.
Iroyin ni wọn yẹgi fun awọn eeyan lori awọn ẹsun bii jiji maalu ati alupupu.
Lootọ, awọn to n gbe oogun oloro ni wọn dojukọ julọ nibẹ.
Akoko kan tilẹ wa ti wọn yẹ igi fun eeyan 230 lọjọ kan ṣoṣo.
Ṣe idajọ iku ti n dinku?
Ọjọgbọn Michelle Miao lati fasiti ilu Hong Kong ṣalaye fun BBC pe o ṣoro lati sọ ni pato iye eeyan ti wọn ti yẹ igi fun ni China.
Miao sọ pe "Gẹgẹ bii awọn idajọ awọn orilẹede mii, China kii kede iye eeyan ti wọn yẹ igi fun."
Ninu iwadii rẹ, o fi ọrọ wa adajọ ogoji ni China lẹnu wo to fi mọ awọn agbẹjọro kan, o si fidi rẹ mulẹ pe awọn ti idajọ iku tọ si lo ri gba.
Agbẹjọro kan to n gbe nilẹ Amẹrika, Dui Hua sọ pe iye eeyan ti wọn yẹgi fun ni China ti dinku lati 12,000 lọdun 2002 si 2,000 lọdun 2018.
Lẹyin naa lo kọ lati sọrọ kankan nipa idajọ iku ni China fun BBC.
Lọwọ yii, iwa ọdara mẹrindinlaadọta lo le yọri si idajọ iku ni China.
Ọjọgbọn Miao ni "Ẹsun ipaniyan ati gbigbe oogun oloro ni ẹsun gboog meji to le mu ki eeyan ri idajọ iku gba."
O ni oun gbagbọ pe laipẹ lai jina awọn ofin tuntun yoo maa jade lorilẹede naa ti yoo mu ayipada otun waye.
Iye igba ti idajọ awọn ọdaran n waye

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹgbẹrun igbẹjọ lo n de siwaju awọn adajọ ni China, pupọ ninu awọn ẹjọ naa si ni wọn n pari.
Iwe iroyin nipa idajọ ni China, China Law Yearbook sọ pe ida 99.95% ẹjọ ti wọn gbe lọ sile ẹjọ lo n niyanju ti idajọ si n waye lori rẹ.
Atẹjade kan lati inu iwe International Journal of Law, Crime and Justice fidi rẹ mulẹ pe gbogbo ẹjọ to dele ẹjọ ni wọn ṣe idajọ rẹ laarin ọdun 1995 si 1999.
Yatọ si China, orilẹede Japan naa ko fi ọrọ idajọ ṣere rara latari bo ṣe n yanju ida 99% ẹjọ ti wọ n de iwaju rẹ.
Bo tilẹ jẹ awọn eeyan kan n sọrọ kobakungbe nipa awọn idajọ iku China, Ọjọgbọn Miao sọ pe pupọ ninu awọn ọmọ ilẹ naa lo faramọ.








